Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ẸBÍ WA
APÁ KEJÌ
....
.
Ẹ̀gbọ́n mi sọ pé òun tì wá àwọn méjéèjì lọ sí ilé àbúrò rẹ̀, ṣùgbọ́n òun kò bá ẹnìkan ní ilé. Bàbá mi kàn dáhùn pé, ‘Bẹ́ẹ̀ni ara àbúrò òun ni kò dá. Ìyá mi ti fi àkísà nu ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n omijé kò í tì í bọ́ ní ojú rẹ̀. Ojú rẹ̀ wá pọ́n wẹ̀ẹ̀ bí ẹrẹ iná. Wọ́n ní kí a lọ sí ẹ̀hìnkùlé, ó rẹ àwọn púpọ̀, àwọn sì fẹ́ lọ sinmi. ‘Ṣé kò sí nkan’ ni èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ḿ bèèrè, ‘Kò sí nkan, ‘ ni wọ́n dáhùn. Ọ̀dẹ̀ ènìyàn pàápàá á ti mọ̀ pé ǹkan ḿ bẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ nkan náà.
.
Àbúrò mi ń yí kẹ̀kẹ́, ó fi ń pariwo. Ń ṣe ni mo pariwo mọ́ ọn, tí mo ní kó mọ̀ pé òníni ọjọ́ ìsinmi ni àti wí pé àti bàbá àti ìyá wa ni inú wọn kò dùn. Bàbá mi kọjá sí ilé ìwẹ̀, mo ní èrò pé ó lọ tọ̀ ni, ṣùgbọ́n ó pẹ́ kí ó tó jáde, ó ní kí n bu omi fún òun kí òun mú, ṣùgbọ́n kàkà kí ó mu omi náà, ojú ni ó fi bọ́, ó sì dámi lójú pé ó ti sọkún.
.
Mo bèèrè, mo ni, ‘Bàbá, ṣé kò sí nkan?’ Ó wò mí, ó mú mi lọ́wọ́ d́ní bí ẹni pé kò le dá dúró mọ́. Ó ní, Ìyábọ̀, àbúrò mi tí ẹ̀ ń pè ní Bùrọ̀dá Eréko ni ó ń ṣàìsàn púpọ̀; àwọn oníṣègùn òyìnbó tí ó yẹ̀ ẹ́ wò sọ pé kò dájú pé ó lè yè, nítorí àìsàn ikú ni àìsàn náà. ‘Ṣé kò ì kú,’ ni mo bèèrè, ó sì dámi lóhùn pé, ‘Ko ̀ ì kú.’ Mo ní n ó lọ gbàdúrà kí ó má kǔ. Bàbá mi mi’rí, ó jù mí lọ́wọ́ sílẹ̀, ó sì wọ yàrá rẹ̀ lọ.’
.
Mo lọ pe ẹ̀gbọ́n mi, mo sì sọ fún un ohun tí bàbá mi sọ fún mi. Àwa méjèèjì lọ sí yàrá wa, a lọ kúnlẹ̀, a sì gbàdúrà wí pé kí Ọlọ́run dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, kí ó má kǔ. Ó jọ l’ójú mi l’ọ́jọ́ náà pé bí a ṣegbàdúrà tán, ẹ̀gbọ́n wa àgbà kò ní í kú mọ́. Ni mo bá bá eré tèmi lọ, mo sì ti fi ọkàn sí I pé tí ó bá ṣe díẹ̀, ara rẹ̀ yóò yǎ, a ó sì tuńn rí I ní Sátidé tí ó ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀.
.
Gbogbo ènìyàn ń wá kí wa ní ilé wa, àwọn ẹbí bàbá mi ń pòòyì, wọ́n á sọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ayọ̀ ní ojú wọn, ojú wọn kan gógó, kò sì sí ẹni tí ó pariwo sọ̀rọ̀ tàbí tí ó bèèrè óńjẹ lọ́wọ́ ìyá mi gẹ́gẹ́ bí àṣà ènìyàn kan tí ó fi ara mọ́ wa púpọ̀. Bí àlejò èyí bá dé, á ní ‘Ẹ kú aájò o, Olúwa á mú ẹsẹ̀ rẹ̀ padà sí ilé o’. Òmíràn á ní, ‘ Ẹsẹ̀ rẹ̀ ni o máa fi rin padà wálé o, Olúwa kò ní jẹ́ kí á gbọ́ o. A kò ní í sáré wá pè wá o.’ Bẹ́ẹ̀ ni kíkí ń pe kíkí, tí àdúrà ń pe àdúrà níjà.
.
Bí wọn ti gbìyánjú tó pé kí àwa ọmọdé- ilé mọ nkan kan, ń ṣe ni a mọ̀ pé ayọ̀ sí nínú ilé wa ní ọ̀sẹ̀ náà. Èyí kò sì ṣẹlẹ̀ rí. Ní ọjọ́ tí wọ́n dá ońjẹ tí ìyá mi gbé lọ sí ilé- ìwòsàn padà láìjẹ́ pé ènìyàn fọwọ́kàn àn ni ẹrù ti bà mí, ṣùgbọ́n mo sọ́ ọ́ sí ọkàn mi pe mo sá ti gbàdúrà ná. Bàbá Eréko kò le tí ì kú! Bàbá mi sá ju ú lọ púpọ̀, kò ṣàì tì bí ọmọ! Kò ì tìí tó àsìkò tí yóò kǔ.
.
Èrò mi ni pé kí ènìyàn tó kú ó ní láti ti gbéyàwó, kí ó sì ti bímọ! Èrò ọmọdé gbáà ni èyí, à ṣé ikú kò mọ ọmọdé, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ àgbà, ẹni ikú bá rí ni ikú ú mú lọ.
.
O ́tó agogo mẹ́jọ tí wọ́n dá ońjẹ padà yìí ni, a rí alùfáà ìjọ wa, àti alùfáà àdúgbọ̀ wa tí kì í ṣe ti ìjọ wa. Àwọn bíi mẹ́rin mǐran tẹ̀lẹ́ wọn. Wọ́n rí mi lójú ọ̀nà, wọ́n ní kí n lọ pe bàbá àti ìyá mi wá. Mo fi ìjókǒ lọ̀ wọ́n. Nígbà tí ìyá mi ti rí àwọn àlúfáà wọ̀nyí, ń ṣe ni ó bú sẹ́kún, tí ó ń pariwo, tí ó ń jára mọ́lẹ̀. Erù ti lẹ̀ bà mí. Mo lérò pé wọ́n wá gbàdúrà kí ara bàbá wa kékeré yìí yá kíákíá ni, à ṣé wọ́n wá tú ọ̀fọ̀ ikú rẹ̀ ni.
.
- ÌYÁBỌ̀
http://oroyoruba.blogspot.com/2016/10/itan-dowe_23.html
ReplyDelete