ORO ERE BOLU NFE AMOJUTO NILE YORUBA
Ipinle mefa ni won gba pe ohun ni Ipinle Yoruba sugbon awa mo pe omo Odua ni Ilorin ati apakan Ile Kogi nikan bi 70s si 80s omo Yoruba lo po ju ninu awon to mo ngba bolu fun orilede Naijiria pelu awon ni won si mo nse dada ju ninu bolu abele koda to fi mo ere Idaraya to ku.
Sugbon loni oro ko ri be mo nitori awon ota ilosiwaju lo po ninu eto ere idaraya nile Yoruba ti ko ba ri be kilode ti akude se ba ere idaraya nile wa abi e ti gbagbe pe agidi ni a fi ri omo Yoruba ninu iko egbe agbabolu ile wa.
Eyi to wa dun mi ju ni bi awon eniyan to wa lapa Ila-Orun se fi owo ola gba wa loju to se pe ojoro ni won mo nse fun awon egbe agbabolu ile Yoruba ti awon alase wa kosi wa nkankan se si opo igba ni ija ati ifiehunnuhan mo nwaye lori papa ti awon Gomina tabi awon agba ninu akoso ere bolu nile Yoruba ko ni gbe igbese ako si.
Egbe agbabolu Ifeayin Uba je okan lara awon agbabolu to wa lati ilaorun sugbon gbogbo bolu ti o ba lo gba yala nile ni o tabi oke itan ojoro lo ma ba de, eyi to wa buru ju nibe bolu marun ototo lo gba pelu egbe agbabolu ile Yoruba to je pe ojoro na lo se abi nigbati eniyan gba bolu lati ookan to si wole sugbon ti a dari ayo ni oun ko ka ti ijoba ati awon abenugan ile YORUBA ko si le soro ilu Eko ni oro yi ti sele.
Ni ijeta yi ni Ifeayin Uba yi tun gba bolu pelu egbe agbabolu Crown ti Ilu Ogbomoso Crown lo koko gba bolu wole ki Ifeayin Uba na to ri àwòn pada lehinna ni adari ayo wa fun Ifeayin Uba ni ayo Asolewomingba leyi ti awon eniyan gba pe ojoro ni ni ayo ba di meji si eyokan sugbon nigbati o se Crown na ba ri àwòn nipase bi won fi ori gbe wole si iyalenu gbogbo eniyan Amugbalegbe adari ayo ti sa lo arin gbungbun ila lati fi idi re mule pe ayo na wole dada sugbon adari ayo ni ko ri be.
Ilu Kaduna ni ayo yi ti waye ni ijeta bi inu se bi awon Hausa to wa wo ayo niyi ti won si ya wo ori papa lati lu adari ayo ti gbogbo e si fojupo ti ayo na ko si le pari ni ijeta.
Mo nwa pe gbogbo Gomina ile Yoruba ati gbogbo eyin ti e ni enu ni ilu e dide o nitori iyanje ti to ge bayi abi e ti gbagbe nigbati awon omo wa ngbe oruko wa ga ni, se ti gbagbe Balogun, Muda Lawal, Segun Odegbami, Owolabi, Aruna Ilerika, Ademola Adeshina, Mutiu Adepoju, Dimeji Lawal ka to wa so Rasheed Yekini.
Se a ti gbagbe pe akonimogba Tella ti je ka mo pe awon agbabolu ile Yoruba si da nigbati o je pupo ninu agbabolu to gba ife eye labe odun metadinlogun (under 17) Yoruba lo po nibe.
Nitorina aini aso lorun Paka o to apero omo erinwo.
(Nje iwo sakiyesi pe won nfi obo lo wa bi)
- Ìtàn Yorùbá
No comments:
Post a Comment