A dá búlọ́ọ̀gù yii sílẹ̀ látara ìpè níja tí a rí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì bí kò ṣe si ẹyọ̀kan tí ó bójú tó èdè Yorùbá. Bẹ́ẹ̀ gbogbo ọmọ Kóòtû- ò-jíire ló mọ̀ pé ọrọ Yorùbá duǹ mọ̀rànyìn- mọranyin. Ní orí búlọ́ọ̀gù yìí, a o màa fi ìròyìn lẹ́kùn rẹ́rẹ́ tọ́ yín létí, òwe lọ́kan ò jọ̀kan ò ní gbẹ́yìn, àlọ́ àpamọ̀ àti àpagbè la ó máa fi dá ara wa lárará. Ẹ máa mìlíkì
12.10.16
ÒWE
Ẹni tí ọ̀ṣọ́ bá wù k’ó ṣòwò, ẹni ajé ya ilé rẹ̀ l’ó gbọ́n
Translation: One who wants beautiful things should trade (or work ) for them; it is the man to whose works profit comes that can claim to be far- seeing.
Lílò: Èdè pé ní tòótọ́ ẹni tí ó bá fẹ́ ohun kan, ọ̀ranyàn ni kí ó ṣiṣẹ́, kí ó ṣaápọn fún ohun nâ; ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo ẹni tí ó ṣiṣẹ́ ni ohun rẹ̀ ń dára, àfi kìkì ẹni tí ó ṣorííre, wọn á sì ka ara wọn sí ọlọgbọ́n
Use: Although, you may be working hard because you want certain things, this does not mean that you are sure to suceed; he who works hard and suceeds has the reputation of being far- seeing.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment