22.2.19

Nípa Ọ̀rọ̀ Yorùbá

Ọ̀rọ̀ Yorùbá

A dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ láti polongo èdè Yorùbá ní gbogbo ọ̀nà tí a lè gbà mú u wuyì fún tolórí- tẹlẹ́mù. Ipa tí a fẹ́ kó nínú ẹgbẹ́ yìí rọ̀ mọ́ gbígbé èdè Yorùbá lárugẹ, kí ó ma bàà di èdè tí kò ní ní alábòójútó ní ọjọ́ iwájú. Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé wón ti ka èdè Yorùbá sí èdè tí kò ní sí lórílẹ̀ ayé mọ́ bí àwọn elédè gan-an ò ṣe káràmáásìkìí èdè wọn. Ìpèníjà ni èyí jẹ́ fún awa ògidì ọmọ Odùduwà tí èdè yìí jẹ lógún jùlọ. Èrèdí ọ̀rọ̀ rè é tí a fi jẹ ọmọ ẹgbẹ́ yìí.

Nínú ẹgbẹ́ yìí, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n, ọ̀mọ̀wé, àwọn olùkọ́ àgbà àti olólùfẹ́ Yorùbá ní ó wà níbí. A sì tún fi àǹfààní sílẹ̀ láti mọ ara wa ju báyìí lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ohun kan tí yóò ṣàǹfààní fún ẹgbẹ́ tí yòò sì mú ìmọ̀ kún ìmọ̀, kí ó má ṣe jáfara láti fi tó wa l'étí. Ire lójú owó ń rí, ire la ó máa rí o. Àṣẹ
.

https://chat.whatsapp.com/HWihx792vGEC5fQoEyhhiB

1 comment:

  1. Casino City Near Fort Mecklenburg - Mapyro
    Find 안성 출장샵 Casinos Near Fort Mecklenburg, PA near Fort Mecklenburg, Pennsylvania and other 밀양 출장안마 nearby Real Estate Casinos 여주 출장샵 in 여주 출장안마 the 경산 출장샵 area.

    ReplyDelete