IKÚ TÍ YÓÒ PAMÍ
- Ayọ̀ọlá ọmọ Fádèyí
Ikú tí yóò pamí,kìí ṣe ti Ẹ̀bólà
Ikú tí yóò pamí, kìí ṣe tòṣì
Ikú tí yóò pamí, kìí ṣe ti ‘HIV’
Ikú tí yóò pamí, kìí ṣe t’ọfà
Ìgbà tí mi ò kọhùn Ọlọ́run
.
Ikú tí yóò pa ọmọ Ádámọ̀
Ń bẹ lára rẹ
Ń bẹ ní gbègbèri rẹ
Èmi ò ní báwọn kú pipìpi bí adìyẹ
Ikú akọni ni n ó kùú
.
Bí wọ́n pé ọgbọ̀n kú, n ò ní sí nínú wọn
Bí wọ́n pé ẹgbẹ̀rún kú, n ò ní sí láàrín- ín wọn
Ẹ̀ẹ̀kan n l’ọ́kan ni n ó kú
Ikú kan, ọkùnrin kan
Ọ̀nà ọ̀fun, kọ́ ni ọ̀nà ọ̀run t’èmi
.
K’ákú sí ogun ṣàgbà kí wọ́n múni l’ẹ́rú
Ọba yóò kú, ẹrú rẹ̀ yóò r’ọ̀run
Ọ̀nà ikú yóò gbà l’óṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Ẹrú tí ò kú, á sin olówó rẹ̀ kú
Ìwọ̀fà tí ò rọ̀run, á sin olówó rẹ̀ kú
.
Ikú tí yóò pamí, ìṣòdodo
Ikú tí yóò pamí,
Ẹ̀sìn Ọlọ́run
Ikú tí yóò pamí, ikú ire
Ikú tí yóò pamí,
Ẹ̀sìn Àláfíà
Àìkú s’ógun mi, iná laa lẹ́yìn ọ̀tá
.
------------------------------------------------
Gbogbo àṣẹ lórí àtẹ̀ jáde yii jẹ́ ti oroyoruba.blogspot.com
#AyF™
©2016
No comments:
Post a Comment