16.10.16

ÀRÒKỌ

DÁÚDÀ JÁLÉ AGBỌ́N

oroyoruba.blogspot.com.ng
.
Àbúrò Sàká ni Dáúdà jẹ́ ṣùgbọ́n, Kúnlé ni ó jẹ àgbà wọn. Bí Dáúdà ṣe jẹ́ ọmọdé tó yìí, ata ni, kò ṣeé fi sí ojú. Gbogbo eré géle tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kò lè ṣe ni ó máa ń ṣe. Dáúdà ní ìkà nínú púpọ̀. Bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe ń kìlọ̀ fún un tó, ṣe ni ó máa ń wa ọrùn kì, tí ó ń kọ etí ikún sí ohun tí wọ́n ń sọ fún un.
.
Dáúdà ní rọ́bà tí ó máa ń fi pa ẹmọ́ kiri ní ẹ̀yìnkùlé. Bí kò bárí ẹmọ́, ó máa ń ta rọ́bà rẹ̀ lu aláǹgbá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹbọ tó fẹ́ fi í rú.
.
Ó jẹ́ àṣà àwọn ọmọdé wọ̀nyí- Dáúdà, Sàká àti Kúnlé, láti máa lọ ran bàbá wọn lọ́wọ́ nínú oko lẹ́hìn tí wọ́n bá ti ilé ẹ̀kọ́ dé. Dáúdà á tilẹ̀ máa fi rọ́bà rẹ̀ tú ìtẹ́ ẹyẹ tí yóò sì pa ẹyẹkẹ́yẹ tí ó bá rí níbẹ̀. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kò fẹ́ràn ohun tí ó ń ṣe yìí, wọ́n sì máa ń fi ẹjọ́ rẹ̀ sun bàbá wọn. Bàbá wọn náà kò ṣàì máa bá a wí. Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ni wọ́n ń yín àgbàdo sí lọ́dọ̀ Dáúdà.
.
Ní ọjọ́ tí Dáúdà ta rọ́bà fọ́ agbè ẹmu bàbá Sídí ní ọ̀nà oko wọn, bàbá rẹ̀ nà án funfun gbẹ́ru gbẹ́ru. Wọ́n gba rọ́bà rẹ̀, wọ́n fi ọ̀bẹ rẹ́ ẹ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Dáúdà tún bọ́ sọ́jà láti ra rọ́bà mìíràn.
.
Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ó ti ra rọ́bà tuntun, àmọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀mọ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ti sú wọn. Ìyẹn ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ fún bàbá wọn mọ́.
.
Lọ́jọ́ tí ọwọ́ pálábá Dáúdà ségi, ẹnu rẹ̀ kọ ìroyìn. Ní ọ̀sán ọjọ́ yìí, wọ́n ń lọ sí oko, Dáúdà ta ojú kán, ó rí nǹkan náà, ó ń mì dìlọ̀d̀lọ̀, àdán ni ó pè é, ó sún mọ́ ọn dáadáa. Bí ó ṣe ta rọ́bà rẹ̀ pàrà, ilé agbọ́n ló lọ bà. Ilé agbọ́n já lé e lórí; agbọ́n ta á lójú àti nímú. Kò sí ibìkan tí wọ́n dásí ní gbogbo orí rẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ kejì, gbogbo iwájú orí rẹ̀ ti wú kọ́ńdú kọ́ńdú, orí rẹ̀ tóbi tó odì ẹyìn, ọmọ ojú rẹ̀ wọnú. Kòsí ẹni tí yóò rí Dáúdà ní àsìkò yìí tí ìrísí rẹ̀ kò ní pa á lẹ́rìn- ín. Yẹ̀yẹ́ ni àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi i ṣe. Kò kúkú lè lọ sí ilé- ẹ̀kó, ńṣe ni àwọn ẹgbẹ rẹ̀ tí wọ́n gbọ́, wá ń kí I nílé. Kòjọ àwàdà, kò jọ yẹ̀yẹ́ ni wọ́n ń fi í ṣe.
.
Yẹ̀yẹ́ tí wọ́n ń fi Dáúdà ṣe yìí dùn ún púpọ̀. Ó jẹ ìrora oró agbọ́n náà fún ọjọ́ mẹ́ta kí ara rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀sí wálẹ̀. Ọgbọ́n tí bàbá kọ́ Dáúdà tí kò gbọ́n ni agbọ́n wá kọ́ ọ yìí. Ojú rẹ̀ sì já a pé àìgbọràn kì í bímọ rere.
.
- Yorùbá Òde Òní

No comments:

Post a Comment