9.10.16

ÀRÒKỌ

Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ẸBÍ

oroyoruba.blogspot.com.ng

Mo mọ àbúrò bàbá mi tí mo fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí dáradára. Ó jẹ́ onínúrere, ó sì máa ń bá àwa ọmọdé ṣeré púpọ̀. Bí ó bá wa tí à ń ta òkòtó, yóò bá wa ta á; bí à ń ṣe bojúbojú, á bá wa ṣe é; à ní bí ó ṣe taní-wà- nínú ọgbà náa ni à ń ṣe, yóò bọ́ sínú ọgbs̀ bí ẹni wí pé ẹgbẹ́ ni wá. Bẹ́ẹ̀ sìni sánmọ̀ jìnnà sílẹ̀. Bí à ń sọ itàn, yóò sọ ìtàn òmìrán tí ó dùn ju tiwa lọ. Ẹnu rẹ̀ dùn púpọ̀. Tí ó bá sọ ìtàn ìjàpá, tí ó fi oyin sí i, tí olúwa rẹ̀ bá ti gbọ́ ìtàn náà ní ogún ìgbà, ń ṣe ni ó màa dàbí ẹni pé ìtàn titun ni! Ó jẹ́ eléré àwàdà tí ó mọ ohun tí ó máa ń wu ọmọdé, tí ó sì máa ń mú inú ọmọdé dùn.
.

Kí n tilẹ̀ sọ òtítọ́, inu wa máa ń dùn nígbà kigbà tí ó bá wá lọ. Bàbá wa pàápàá kị̀ í bá wa ṣeré tó ti àbúrò rẹ̀ yìí. Nígbà kan, mo gbọ́ tí ba[ɓ ́ mi ń bá a wí pé eré, àwàdà àti yẹ̀yé ni ó máa fi gbogbo ọjọ́-ayé rẹ̀ ṣe, àti pé ní ọjọ wo ni ó máa huwà àgbàlagbà. Ṣé bí a bá dàgbà tán, à yéé ṣorò bí èwe!
Ní ti àwà ọmọdé- ilé, ènìyàn pàtàkì ni ó jẹ́ fún wa, a sì ní ìfẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. À ń retí rẹ̀ kí ó wá báwa ṣeré ọjọ́ Sátidé tí ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹlẹ̀ yìí títí di alẹ́. A bi ìyá wa pé a kò tíì rí bàbá wa kékeré l’ọ́jọ́ náà, àti pé a kò mọ kín ni ó ṣe é. Bẹ́ẹ̀ kì í ṣe aláì- má- wǎ ní ọjọ́ Satídé.
.

Nígbà tí ó di ọjọ́ Ọ̀sẹ̀ ni ìyá wa ní tí a bá ń bọ̀ láti ilé- ìsìn, kí a yà ní ilè rẹ̀, kí a wádĩ kín ni ó ṣe é tí a kò fi rí ní àná, tí a kò sì tún fi rí i ní ilé- ìsìn. Kí a sá ní òun ni mo fi gbogbo àsìkò ṣọ́ láti wò ó bí ó bá wá sí ilé-ìsìn l’ọ́jọ́ náà lọ́hǔ. N kò rí i títí ìsìn fi dé òpin.
.

Nígbà tí a yà ní ilé rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ àná ni inú kan tí ń dà á láàmú, tí kò gbádùn. Nígbà tí ó di òru tí kò í tíì rí àlàáfíà ni wọ́n ṣe ìpínnu láti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì. Kí a má fa ọ̀rọ̀ gùn, òun ìyàwó sì ti yà ní ilé wa láti sọ fún bàbá mi pé ó fẹ́ si àbúrò rẹ̀, ó sì ti lọ sí ilé- oníwòsàn, ṣùgbọ́n òun kò bá wọn nílé.
.

Àwa pàápàá délé, ṣùgbọ́n ìyá mi àti bàbá mi kò sí ní ilé; wọ́n ti lọ sí ilé- ìsìn mǐràn tí wọ́n pè wọ́n sí. Wọ́n tó dé, wọn kò dé, a retí, retí, wọn kò dé. Óńjẹ ọ̀sán tó jẹ, a ò mà rí wọn o. A wá óńjẹ jẹ, ṣùgbọ́n t’ìjayà t’ìjayà ni. Ẹ̀gbọ́n mi ní kí èmi máa tọ́jú àwọn àbúrò wa, kí òun tún padà lọ sí ilé àbúrò baba mi yìí láti lọ wo àwọn òbí wa. Kò pẹ́ púpọ̀, ó padà dé, ó ní kò sí ẹnìyàn kankan ní ilé títí kan ọmọ- ọ̀dọ̀ wọn. Èyí yà wá lẹ́nu ṣùgbọ́n kínni ọmọ ọdún mẹ́sǎn àti mọ́kànlá lè ṣe ju èyí tí a ti ṣe lọ! A dúró à ń wò, à ń retí, ṣùgbọ́n ọ̀sán tún pọ́n, ó fẹ́rẹ di ìrọ̀lẹ́ kí bàbá àti ìyá wa tó wọlé. N ò rí kí ojú bàbá mi pọ́n, kí ó sì rẹ̀wẹ̀sí báyìí rí. Agbára kákáni ó fi kí wa pé a kú ile.
.

-Ìyábọ̀


oroyoruba.blogspot.com.ng

No comments:

Post a Comment