A dá búlọ́ọ̀gù yii sílẹ̀ látara ìpè níja tí a rí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì bí kò ṣe si ẹyọ̀kan tí ó bójú tó èdè Yorùbá. Bẹ́ẹ̀ gbogbo ọmọ Kóòtû- ò-jíire ló mọ̀ pé ọrọ Yorùbá duǹ mọ̀rànyìn- mọranyin. Ní orí búlọ́ọ̀gù yìí, a o màa fi ìròyìn lẹ́kùn rẹ́rẹ́ tọ́ yín létí, òwe lọ́kan ò jọ̀kan ò ní gbẹ́yìn, àlọ́ àpamọ̀ àti àpagbè la ó máa fi dá ara wa lárará. Ẹ máa mìlíkì
10.10.16
ÌTÀN D'ÒWE
ENI TÓ LERÚ LÓ LERÙ
Ní ìgbà àtijó, Oba olórò kan wà, ó ní oko beere, ó ní ilé nlá púpò, ó ní orò jántirere bákannáà ni erú rè kò mo níwòn. Bí ó ti wá ní dúkìá àti orò tó yìí omo obìnrin kan soso ló bí.
Nígbà tí Ojó Oba yìí dalé gbèrégbèré tí ó kíyèsi pé àwon asáájú gàpère rè ti n séwó sí i, ni ó bá pe àwon jèpé eégún tirè (tí wón kángun sí i), ó sàlàyé wí pé láti pínnísín ni Àyìnlá olórí erú òun ti n sin òun tèmítèmí láì rojú tàbí puró Nítorí náà, kí won ó jé kí omobìnrin òun ó mú òkan péré nínú dúkìá òun kí gbogbo ìyókù pátá ó sì jé ti olórí erú òun. Ah! ni gbogbo àwon tí wón gbó òrò òhún se pé; "ènìyàn ti seé féràn erú ju omo bíbí inú rè lo?". Àmó oba fi èpè lé e pé yàjóyàjó nikú eni tí ó bá yí òrò òun padà yóòjé. Lòrò bá di wòmí n wò ó fún gbogbo won.
Ojó keta òrò yìí ni oba wàjà. Léyìn gbogbo ètò tí ó ye léyìn ìgbésè oba, wón mú ojó láti pín ogún oba ni ìbámu pèlú àsosílè oba.
Nígbà tí ojó ìpíngún pé,Basòrun sàlàyé ohun tí Oba so sílè kí elémìí ó tó gbàá, ó sì ro Adéláyò Omo Oba láti tóka òkan péré nínú dúkìá bàbá rè tí yóò jogún kí àwon ó tó fa gbogbo dúkìá yóòkú fún Àyìnlá olórí erú Oba. Ìrònú dorí Adéláyò kodò lórí ohun tí ó lè tókasí, nígbà tí ó se ó ro àwon àgbà àti olóyè tí ó wà níkàlè láti fún òun láàyè láti ronú lórí ohun tí òun yóò mú. Wón gbà fun béè, wón sì fun ní ojó méje péré. Adéláyò dúpé, ó sì fi ìbànújé kúrò lódò àwon àgbà náà, nígbà tí Àyìnlá n béyin kee nítirè fún ayò pé òun ni òun yóò ni gbogbo dúkìá Oba nígbà tí Adéláyò bá ti mú òkan péré. Òrò wá di;" Omo olórò n sunkún, erú olórò n yò.
Adéláyò ò fojú boorun páàpáà lórí ìrònú ohun kan soso tí ó le yàn nínú ògòòrò dúkìá tí baba rè fi sílè. Níkeyín, orí rè gbé e ko àgbà dáadáa kan tí ó làá lóye pé erú tí baba rè fún lógún n gan ni kí ó mú, nípa báyìí gbogbo dúkìá bàbá rè yóò padà di tirè nítorí pé eni tí ó ni erú ni ó ni gbogbo ohun ìní erú; eni tó lerú ló lerù.
Láàrin kádijúkálàá, ojó ìpíngún pé, esè gbogbo àwon àgbà sì kò. Àyìnlá n yán apá ká pèlú èrò pé òun yóò di olórò lójó náà, àmó àgbà tí ó kó Adéláyò ti so fún un láti máa fi òye kíyèsí ohun gbogbo. Nígbà tí àsìkò tó fún Adéláyò láti mú òkan péré nínú ògòòrò dúkìá tí baba rè fi sílè, ó kúnlè kí gbogbo àgbà tí wón wà níkàlè ó sì tóka sí olórí erú baba rè gégé bí dúkìá baba òun tí òun mú. Ah! Ko gbogbo àwon àgbà pé níbo ni Adéláyò ti kó irú ogbón tí ó lò. Àyìnlá banújé, ó sì toro ààyè láti kó àwon dúkìá Oba pamó kí ó tó wá máa sin Adéláyò, àmó Basòrun sàlàyé pé kò sí dúkìá kankan tí ó lè fowó kàn mó àyàfi èyí tí olúwa rè tuntun (Omo Oba Adéláyò) bá fún un, Nítorí pé eni tí ó lerú ló ni erù.
Láti ìgbà yìí ni ó ti di òwe ìpàsamò fún àwon erú pé; ENI TÓ LERÚ LÓ LERÙ.
Àbò mi rèé oooo.
E kú ìfé Èdè àti Àsà Yorùbá lára mi o.
© Olùkó Èdè Àti Àsà Yorùbá Arb (2016)
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment