19.10.16

IBI

ABÚLÉ ỌJÀ


ÀṢAMỌ̀
Ilú pọ̀ jàǹtirẹrẹ ní ìpínlẹ̀ Èkó bí o ti pọ̀ ní ìpínlẹ̀ mẹ́fà mìíràn tí ó parapọ̀ di Orílẹ̀ Ọmọlúàbí. Bẹ́ẹ̀ ìlú kìí wà kí ó mà ní olórí tàbí ibi tí ó ti ṣẹ̀ wa nígbà ìwáṣẹ̀, odò á ní orísun dandan. Ìlú tí a ó gbé yẹ̀wò lọ́sẹ̀ yìí ni Abúlé Ọjà. Ẹni bá ń lọ si Bàrígà, tí ó bá gba Yáàbá wọlé, yóò gba Abúlé Ọjà kọjá . Ẹni bá sì ń lọ si ilé Ẹ̀kọ́ fáfitì Èkó ti ìjọba àpapọ̀ kò lè yẹ Abúlé Ọjà sílẹ̀ láì má gbà á kọjá. Ìlú tí a ó gbé yẹ̀wò lọ́sẹ̀ yìí ni Abúlé Ọja.
Ìlú Abúlé Ọjà kìí ṣe ìlú kékére rárá, gbogbo ohun tí ó ń tọ́ka sí ìlú ńlá lówà ní Abúlé Ọjà bí óti lẹ̀ jẹ́ pé Abúle tí ó wà nínu orúkọ yìí lè ṣi èèyàn lọ́nà láti rò pé Abúlé ni ìlú náà yóò jẹ́. Kò rí bẹ̀ rárá. Ṣùgbọ́n ẹni tí kò ì dé ibẹ̀ yóò rò pe Ìgbèríko ni. Abúlé Ọjà fẹ̀ dáadáa. Kò dín ní ọ̀dúnrún kìlómítà ló rọ kiriká ìlú yìí tí ẹsẹ̀ bá rìn ín ká. Fáfitì Èkó àti apákan Bàrígà ló rọ̀ ká a ní ìhà gúsu, Bájùláyé àti Abúlé Ìjẹṣà ló gbè é ní ìwọ̀ òrùn nígbà tí Yábàá yíì ká ni ìhà àríwá. Abúlé Ọjà wà ní Ìjọba ìdàgbàsókè Yaba (Yaba LCDA) ní Ìpínlẹ̀ Èkó.

ÌṢẸ̀WÁ
À ti Ìlú Biní ni baba ńlá bàbá àwọn ọmọ àti Oònilẹ̀ Abúlé Ọjà ti ṣẹ̀wá bí ó ti ṣe rí fún púpọ̀ àwọn ìlú tí ó wà ní Èkó. Àbádárìgì, Ẹ̀pẹ́, Ìsàlẹ̀ Èkó jẹ́ pàtàkì lárá àwọn ìlú pàtàkì tí wọ́n jọ tẹ̀dó tí wọ́n sì jẹ iyèkan.

BÁÁLẸ̀ JÍJẸ

Báálẹ̀ ni oyè tí ó tó bi jù lọ ni Abúlé Ọjà, ọdún 1944 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oyè báálẹ̀ ni ìlú yìí. Ìdílé Elétù Òdìbò ni ó ń jẹ Báálẹ̀, àwọn sì ni wọ́n ń ṣe àkoso gbogbo ilẹ̀ Abúlé Ọjà àti ìdá kan nínú mẹ́ta ilẹ̀ Abúlé Ìjẹṣà. Báálẹ máa ń ṣe ìjọba pẹ̀lú àwọn àwòrò ǹṣàṣà tí wọ́n jẹ́ àgbà láàrín ìlú. Elétù Òdìbò Èkó ni ó máa ń fi Báálẹ̀ jẹ. Nínú ètò àti ìlàna tí wọ́n fi yan báálẹ̀ tí ó wà lórí àlééfà ni wọ́n tí ṣé lófin pé ẹni tí kò bá ì tíì tó ọmọ àádọ́ta ọdún kò lè jẹ Báálẹ Abúlé Ọjà, èyí tí ó lè ṣe àkóba ńláǹlà fún ètò ìlú náà.

Báyìí ni orúkọ àwọn tí wọ́n ti jẹ Báálẹ̀ ṣe lọ, àti àwọn Elétù Òdìbo tí wọ́n fi wọ́n jẹ:

Ọdún 1944 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oyè Báálẹ̀ ní Abúlé Ọja, Olóyè Sèídù Bánkọ́lé ló kọ́kọ́ jẹ ẹ́, Elétǔ Òdìbò (Olóyè) AbduLlahi Bámgbọ́pàá ni ó sì fi wọ́n jẹ. Báàlẹ́ yìí lo sáà wọn títí ọdún 1952 nígbà tí ẹlẹ́mìí gbà á. Fún ọdún márùn ún ni kò fi sí Baálẹ̀ lórí àtẹ́ ní ilú Abúlé Ọjà. Ìgbà tì ó ma fi di ọdún 1957 lẹ́yìn ìgbà tí ẹlòmíì ti jẹ oyè Elétǔ Òdìbò (Olóyè) Ámúsà Gbádéṣeré ti jẹ oyè Elétǔ, wọ́n fi Olóyè Sulaiman Balógun Elétǔ Òdìbò jẹ báálẹ. Báálẹ Sulaiman wà lórí òyè di ọdún 1974 tí ó fi wèwàlẹ̀ àsà, bí ẹ ti mọ̀ pé nílẹ̀ Yorùbá pé ikú nìkan ló lè yẹ Ọba tàbi Báálẹ̀ kúrò lórí oyè.

Ó tó ọdún mẹ́wàá dáadáa kí báálẹ míì tún tó jẹ, ọdun 1984 sì ni. Iṣẹ́ ìwádìí fi yé wa pé fún gbogbo ọdun tí kò fi sí Báálẹ̀ lórí ìtẹ́, igbimọ fìdí hẹ́ ni ó ń tukọ̀ ìlú. Olóyè Andrew Ayọ̀délé ló jẹ Báálẹ̀ tí Elétǔ Òdìbò (Olóyè) Ìṣọ̀lá Bájùláyé Gbádéṣeré si fi oyè Báálẹ jẹ. Ọdún 1989 ni
Olóyè Andrew ṣípò padà. Ó lé ní ogún ọdún dáadáa kí báálẹ tó wà lórí àlééfa lọ́wọ́lọ́wọ́ tó jẹ, èyíkò ṣàì rí bẹ̀ bí óti jẹ́ pe, ogun ọtẹ ló kó ìlú ní pápá mọ́ra. Ọdún 2013 ni Olóyè M.K.I. Adédèjì Balógun- Eletǔ jẹ Báálẹ̀, Bábá (Olóyè) Tajudeen Agboọlá Elétù Òdìbò ti ilú Èkó ló sì fi wọ́n jẹ.



ÌYÀTỌ̀ TÍ Ó WÀ LÁÀRÍN ÍN ELÉTÙ ÒDÌBÒ ÀTI BÁÁLẸ̀


Ìyàtọ̀ kékeré kọ́ ló wà láàárín oyè Elétù Òdìbò àti Báálẹ̀. Bí sánmọ̀ ṣe jìnà si ilẹ̀ tó ni Elétù Òdìbò ṣe jìnà sí Báálẹ̀. Ẹbí tàbi Ìdílé kan náà ni àwọn méjéèjì ti wá ṣùgbọ́n baba ni Elétùú Òdìbò jẹ́ sí Báálẹ̀, Elétùú Òdìbo ní í máa ń yan Báálẹ gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ ní àárín ìlú. Nínú gbogbo àwọn olóyè abìlà funfun t’Èkó, Elétùú Òdìbò ni olórí wọn. Elétùú Òdìbò ló sì máa ń fi Ọba Èkó jẹ, èyí ò ya ni lẹ́nu tìtórí orúkọ ìdílé (Gbádéṣeré) yìí fi hàn bẹ́ẹ̀. Olóyè Tajudeen Agboọlá ni ó wa lóri alèéfà Elétu Òdìbò nígbà tí Olóyè M.K.I. Adédèjì Balógun- Eletu jẹ Báálẹ̀ Abúlé Ọjà.


OLÓYÈ M.K.I. ADÉDÈJÌ BALÓGUN- ELETU

A bí Báálẹ̀ Abúlé Ọjà ní ǹnkan bi ọdú márùn ún dín lọ́gọ́ta sẹ́yìn sí Ẹbí Elétùù Òdìbò. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ jáde ni ilé ìwé alákọ̀bẹ́rẹ̀ẹ́ ti ‘7th Day Primary School’ tí ó wà ní Abúlé Ọjà, wọ́n tẹ̀ síwájú sí ilé ìwé girama ní Jíbówú High School tí ó ń jẹ́ Premier College, Jíbówú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí. À ì sí owó já wọn ní tàn mọ́ọ̀ láti tẹ̀ síwájú síi. Lẹ́yìn ìwé yìí ni wọ́n lọ kọ́ṣẹ́ ìwé títẹ̀, èyí ni wọ́n ń ṣe títí tí wọ́n fi joye Báálẹ̀ ní ọdún 2013. Ìnágijẹ oyè wọn ni Ìlúfẹ́milóyè I.

Báálẹ̀ fẹ́ ìyàwó méjì, Olorì Táwàkálítù Adédèjì Balógun- Elétǔ àti Olorì Ọmọlará Adédèjì Balógun- Elétǔ pẹ̀lụ́ àwọn ọmọ alálùbáríka

ORÍKÌ

Ọmọ Ẹrin ò béjì
Tí ó bá béjì, ọ̀kan á dìso

Àwa ló lọwá
Àwa ló lọba
Elétǔ Òdìbò la fọba jẹ

ÀWỌN IBI PÀTÀKÌ NÍ ÌLÚ

1. African Church Bethel



2. Mọ́ṣàláṣị Gbogbo gbo(Central Mosque)

3. Igi Àgbálùmọ́: Igi yìi ti lé ni ọgọ́rùn ún ọdún

4. Ilé Ìwé Girama Agba( Elétǔ Senior High School)



5. Ilé Ìwé Girama Kékeré ( Elétǔ Senior Junior School)

6. Ilé Ìwé Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, 7th Day Adventist Primary School


ÀWỌN JÀNKÀN JÀNKÀN NÍNÚ ÌLÚ

1. Bàbá Ọba: Àwọn ni bàbá Bàbá báálẹ tí ó wà lórí ìtẹ́, àwọn sì ni ààrẹ ìjókǒ àgbà ti Ìlú Abúlé Ọjà. Wọ́n bí bàbá ní Oṣù Agẹmọ, ọjọ kẹta dín lọ́gbọ̀, ọdún 1937.  Orúkọ wọn sì ni Alàgbà Ganiu ọmọ Sùbérù Bánkọ́le.


ÀWỌN ÌGBÌMỌ̀ BÁÁLẸ̀

1. Báálẹ Abúlé Ọjà: Olóyè M.K.I. Adédèjì Balógun Elétǔ

2. Akọ̀wé: Olóyè Babátúndé Shóyẹmí

3. Bàbá Ọba: Olóyè Sèídù Bánkọ́lé

4. Ìyá Ọba: Olóyè Áfúsátù S. Balógun

5. Olóyè Babátúndé Kareem

6. Ìyálóde: Olóyè Táwàkálítù Àṣàbí Ọláwálé

7. Olóyè AbdulGaniu Kareem

8. Olóyè Labi Davies

8. Aṣòfin James Adéoyè

9. Olóyè  Lateef Balogun

10. Olóyè Bashiru Àtàndá

11. Olóyè Ìsíákà Balógun

12. Agbẹjọ́rò Alhaji Jabar Ameen

13. Olorì Tèmiyémi

14. Baàlà Nurudeen Ìyàndá

15. Alhaji Ràsákì Ọsho**

** Àwọn ni Olóyè T. A. Gbádéṣeré fi jẹ Aṣíwájú Ìlú Abúlé Ọjà ní ọjọ́ tí wọ́n ṣi 'Health Centre, Àkọkà. Aṣòfin J. J. Jimoh ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà.

ÀWỌN ALÁBǍṢIṢẸ́PỌ̀ FÚN ÌTẸ̀SÍWÁJÚ ÌLÚ ABÚLÉ  ỌJÀ

1.  Alàgbà Saliu Kareem

2. Alàgbà Wasiu Kareem

3. Alàgbà Taofiki Mustapha

4. Alàgbà Ibrahim Bánkọ́lé

5. Aṣòfin Lukmon Owólabí

*Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ìlú Abúlé Ọjà ló ń fẹ́ ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbà sókè Ìlú Abúlé Ọjà tí Ọlọ́run fi ta ẹbí Elétǔ Òdìbò àti ìlú Èkó lọ́rẹ.

ÌPÁRÍ

Àwọn ìlú kéréje kéréje tí wọ́n ṣìdí wọn kúrò ni ọgbà fáfitì Eko, ilé ẹ̀kọ́ àgbà olùkọ́ni wá faramọ́ àwọn tí wọ́n tẹ ìlú Abúlé Ọjà do. Ìlú Abúlé jẹ́ ìlú ìfọkàn balẹ̀ tí kòsí ìyọnu àti ìdààmú. Kòsí ẹ̀yà tí kò ṣà sí níbẹ, Hausa, Tápà, Nùpẹ̀, Ìgbìrà, Ìgbó ló ń gbé ní bẹ̀ là ì kèéta. 

Báálẹ̀ ń kí wa.

No comments:

Post a Comment