A dá búlọ́ọ̀gù yii sílẹ̀ látara ìpè níja tí a rí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì bí kò ṣe si ẹyọ̀kan tí ó bójú tó èdè Yorùbá. Bẹ́ẹ̀ gbogbo ọmọ Kóòtû- ò-jíire ló mọ̀ pé ọrọ Yorùbá duǹ mọ̀rànyìn- mọranyin. Ní orí búlọ́ọ̀gù yìí, a o màa fi ìròyìn lẹ́kùn rẹ́rẹ́ tọ́ yín létí, òwe lọ́kan ò jọ̀kan ò ní gbẹ́yìn, àlọ́ àpamọ̀ àti àpagbè la ó máa fi dá ara wa lárará. Ẹ máa mìlíkì
17.10.16
ÌWÚRE
ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀
Bí igi kò bá léṣo lórí, ayé kì í ju òkò fún un!!.
Bẹ́ẹ̀ bí òsùpá kò bá tàn kárí ayé láti alède ọ̀run
Ọmọ aráyé kò ní pókìkí ẹ̀!!.
Ìwọ́ ọ̀rẹ́ mi, bí o bá ń bẹ̀rù ọ̀tá;
Dàkun máse gba àdúrà ìgbéga nítorí ẹ̀dá kan kò ní gòkè ọlà;
Káyé ó máse má a lé ipa rẹ̀!!
Àdúrà wa ni wí pé kí a máse subú fún ọ̀tá yọ̀!!!
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment