ÁLÍFÁÁBẸ̀TÌ ÌWÚRE
*A* - Alaafia ni fun ọ.
*B* - Buburu kan ki yio ṣsubú lu ọ.
*D* - Dugbẹdugbẹ ibanujẹ ko ni ja
le ọ l'ori.
*E* - Ebi ò ni pa ọ nibi ti ọdún
ku si yi.
*E* - Ẹkún, asun'da ko ni jẹ
tirẹ.
*F* - Funfun aye rẹ ko ni
d'ibajẹ.
*G* - Gunnugun ki ku l'ewe, wa
d'agba d'arugbo.
*GB* - Gbogbo idawole rẹ a yọrí
si rere.
*H* - Hausa, Yoruba, Ibo, gbogbo
ẹya ati eniyan kaakiri agbaye ni yio kọju si ọ ṣe ọ loore.
*I* - Iwaju, iwaju l'ọpa ẹbiti rẹ
yio ma re si.
*J* - Jijade rẹ, wiwole rẹ, ò ó
nik'agbako.
*K* - Kukuru abi giga - ìsorò ko
ni jẹ tìrẹ.
*L* - Loniloni wa r'aanu gba.
*M*- Mọnamọna ati àra Ọlọ́run yóò
tu àwọn ọta rẹ ka.
*N* - Naira, Euro, Dollar, Pound,
Yen, Yuan, gbogbo owo ati ọrọ kaakiri agbaye pẹlu ọmọ alalubarika ati alaafia
yóò mu ọ l'ọrẹ, wọn o si fi ile re ṣe ibugbe.
*O* - Ojurere ati aanu yio ma tọ
ọ lẹ́yìn ni ọjọ aye rẹ̀ gbogbo.
*Ọ* - Ọjọ́ ọ̀la rẹ a dara.
*P* - Panpẹ aye ò ni mu ọ
t'ọmọtọmọ.
*R* - Rere ni agogo aye rẹ yió ma
lu n'igba gbogbo.
*S* - Suuru pẹlu ìtẹ́lọ́rùn ninu
ọrọ at'alaafia yio ba ọ́ kalẹ.
*Ṣ* - Ṣsugbọ́n ati àbáwọn aye rẹ ti poora loni.
*T* - T'ọmọtọmọ, t'ẹbitẹbi,
t'iletile o ni d'ero ẹyin.
*U* A kii wátí U ti l'ede Ekiti
Ujẹ̀ṣà; a o ni fi ọ̀ ṣsàwátí laarin awọn ọniyan (eniyan). Ulọsiwaju (ilọsiwaju), ure (ire), ati ubukun
(ibunkun) yio jẹ́ tìrẹ.
*W* - Wa ri ba ti ṣe, wa r'ọna gbe gba.
*Y* - Yara ibukun, ire, ati ayo
ailopin loo ma ba ọ gbe titi ọjọ aye rẹ......
_*AMIN, L'AṢẸ EDUMARE.*_
_*IRE O!*
No comments:
Post a Comment