Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ẸBÍ WA
APÁ KẸTA
APÁ KẸTA
.
Wọn kò tilẹ̀ lé
àwa ọmọdé sí ẹ̀hìnkùlé. Wọ́n ní kí gbogbo ilé kúnlẹ̀ kí á
gbàdúrà. Nínú ọ̀rọ̀ àdúrà yìí ni mo fi ọgbọ́n gbe pé àbúrò bàbá
wa ti kú. Kí àlùfáà tó gbàdúrà tán, kí àlụ̀fáà kejì tó bẹ̀rẹ̀
Oore Ọ̀fẹ́, ni ẹkún àti ariwo ti gba ilé kan. N ò tilẹ̀ le sọ bí mo ti ṣe
kúrò ní pálọ̀ wa ní ọjọ́ náà. Mo lọ sí yàrá èmi àti ẹ̀gbọ́n mi. Mo
sọkún, inú mi sì bàjẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó ní láti jẹ́ pé ẹkún ni mo sun lọ
sùn.
.
Ní àárọ̀ ọjọ́
kejì, kòì tíì tó aago márǔn ni ẹkún ìyá wa kan jí mi. Ó ń ki àbúrò
bàá mi yìí ní oríkì ìran wọn ní mẹ́sǎn
mẹ́wǎ. Mo gbọ́ tí ó ń sọ pé, ‘Ọmọ Òrónnà, Ọmọ
Ìyáàlà, Ọmọ kí á fi ọ̀pá wá, k’á fi òjé, kí á fi ògèdègédé ọwọ
wa dé Sẹri mọ́lẹ̀… Hee Hee Hee.’ Tí ó bá yá, á tún kì í lọ bí ilẹ̀
bí ẹní, á tún bú sí ẹkún. Kò sí ẹni tí ó lè sùn mọ́. ‘Ikú wo ni
ó rí mi nílẹ̀, tí kò pamí, tí ó wá lọ pa ọmọ mi? Ọmọ mi tí kò ì ṣe
ǹkan láyé’. Jésù gbàmí. Mo kú lónì o.’ Ẹ̀gbọ́n ìyá bàbá
miobìnrin ni ó ń ké tí ó fa irun mọ́ ara rẹ̀ lórí, tí ó ń gbé ara rẹ̀
ṣánlẹ̀, tí ó ń sọkún kíkorò kíkorò bẹ́ẹ̀.
Ǹkan ṣe!
.
Títí ilẹ̀ ọjọ́ fi
ṣú, ariwo ẹkún ni ó gba ilé kan. Àti ìyá àti
bàbá wa kò fi ẹnu kan óńjẹ. Aládǔgbò
wa kan tí í ṣe ọ̀rẹ́ ìyá mi pàtàkì ni ó wá kó wa lọ sí
ilé rẹ̀, tí ó fún wa ní àmàlà àti ewédú jẹ. Nígbà tí ó di alẹ́
tí ó mú wa padà wá sí ilé wa, a bá àwọn àlejò mélǒ
kan tí wọ́n doríkodò. Ó dámi lójú pé wọ́n ti sọkún púpọ̀, agara sì
ti dá wọn.
.
Ọjọ́ kejì ni ọjọ́
ìsìnkú. Ilé wa sì ni wọ́n ní wọn yóò tẹ́ òkú sí nítorí bàbá mi
ni ó dúró bíi bàbá fún un, ilé onílé ni ó ń gbé. Ó kàn gba
ìyàrá méjì l’ágbàsanwó oṣoòṣù ni. Mo rí I pé wọ́n ń palẹ̀mọ́ níilé wa, wọ́n
kó gbogbo ǹkan ìtúnlé ṣe tí ó wà nínú pálọ̀ wa pamọ́ ní ilé wa pa mọ́.
Gbogbo àwòrán ẹbi tí ó wà ara ògiri ni wọ́n da ojú wọn kọ ògiri. Agogo
tí ó wà ní òkè tí gbogbo ènìyàn máa ń kọ́kọ́ rí nìkan ni wọn kò
da ojú rẹ̀ bo ògiri. Ṣùgbọ́n wọ́n dá a dúró sí àsìkò tí olóògbè
náà dákẹ́. Èyí jẹ́ agogo mẹ́rin ọ̀sán. Báyìí ni wọ́n sì fi agogo
náà sílẹ̀ sí agogo mẹ́rin ọ̀sán fún ọ̀sẹ̀ kan gbáko, kí àwọn ènìyàn
baà mọ àsìkò tí Bàbá Eréko fi ayé sílẹ̀ gan an.
.
- ÌYÁBỌ̀
No comments:
Post a Comment