5.10.16

EWÌ ỌMỌDÉ

MO BÚ MỌ̀-Ọ́N
oroyoruba.blogspot.com.ng


Mo bú ‘Mọ̀-ọ́n’

Kín ní í jẹ́ ‘Mọ̀-ọ́n’?

Mọ̀-ọ́n lóógun;

Kín ní í jóógun?

Ògún l’Adé;

Kin ní í j’Ádé?

Adéṣípọ̀;

Kin ní í jẹ́ Pò?

Pòǹṣẹ́rẹ́;

Kin ní í jẹ́ Ṣẹ́rẹ́?

Ìṣẹ́rẹ́ Ọmọ́yọ;

Kin ní í j’Ọ́mọ́yọ?

Ọmọ́yọ Àkókó

Kin ní í j’ Àkókó?

Àkókó Òrìṣà

Kin ní í j’ Òrìṣà?

Òrìṣà Alayé;

Kin ní í j’ Alayé?

Alayé Alọ̀run

Alọ̀run Ìgbálá;

Kin ní í jẹ Gbàlà?

Ìgbálá ìgbásẹ́;

Kin ní í jẹ Gbásẹ́?

Ìgbásẹ́ Arẹrẹ;

Kin ní í j’ Árẹrẹ?

Arẹrẹ ń Mògún;

Kin ní í jẹ́ Mògún?

Mògún Onírè;

Kin ní í j’Onírè?

Onírè Apàtẹ;

Kin ní í j’Apàtẹ?

Apàtẹ Ìlẹ̀kẹ̀;

Kin ní í jẹ́ lẹ̀kẹ̀?

Ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn ẹ sígógó

Sín-ín-ìn!

oroyoruba.blogspot.com.ng

No comments:

Post a Comment