5.10.16

ÀRÒKỌ

ÌGBẸ̀YÌN OLÈ

oroyoruba.blogspot.com.ng


.
Bádérù jẹ́ ògbójú ọlọ́ṣà. Ó máa ń jí ọkọ̀ gbẹ, ó sì máa ń fọ́ báńkì pẹ̀lú. Ó ti sọ òlè jíjà di iṣẹ́ àṣejẹ. Kò sí ẹni tó mọ bàbá rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ìyá rẹ̀. ‘Èkó gba olè, ó gba ọ̀lẹ’, bí ọ̀rọ̀ Yorùba. Kòkú sẹ́ni tó lè bèère ibi tí ẹnikẹ́ni ti ṣàn wá ní ìlú Èkó. Bádérù ti dé Èkó, ilẹ̀ ta sí i. Kò sì sí iṣẹ́kan tí àwọn ará àdúgbò mọ̀ ọ́n mọ́. Olè ló ń jà kiri. Gbogbo àwọn ará àdúgbò ni wọ́n ti fura pe olé ni.
.
Bádérù kò kúkú mọ̀ pé ẹnikẹ́ni ń wo òun. Ẹni tí à ń wò ní áwòsọkun tí ń wo ara rẹ̀ ní àwò- rẹ́riǹ-ín ni Bádérù. Gbogbo àwọn ará àdúgbò ni kìí fẹ́ kí ọmọ àwọn dé sàkání rẹ̀. Won kò fẹ́ kí ó kọ́ àwọn ọmọ wọn ni iṣẹ́ olè jíjà, ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ ti sú wọn. Wọ́n ń retí ọjọ́ tí ọlọ́pàá yóò tẹ̀ ẹ́.
.
Ìwà àwọn ará àdúgbò yìí kò dènà kí Bádérù ní àwọn ọ̀rẹ́. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ a sì maá bá a ṣeré. Ṣùgbọ́n àtòun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn fi ojú sí lára gẹ́gẹ́ bí ọlọ́ṣà.
.
Bí ènìyàn bá pàdé Bádérù ní ibi fàájì, yóò rò pé ọlọ́lá kan ni. Ńṣe ni ó máa ń náwó bí ẹlẹ́dà. Àwọn obìrin àsìkò kì í wọ́n lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó lọ́yàyà, ó sì gbajúmọ̀. Bí Bádérù kìí bá ṣe olè, ó yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní “ẹni ayé yẹ”.
.
Ní ọjọ́ kan ni a gbọ́ pé ọwọ́ tẹ ọlọ́ṣà kan tí ó lọ jí ọkọ̀ àlùfáà ìjọ Ọlọ́run kan gbé. Bádérù ni. Àwọn ọlọ́pàá mú un. Wọ́n gbé e lọ ilé- ẹjọ́. Wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé ó pa aṣọ́gbà tí ń ṣọ́ ilé àlùfáà yìí. Ẹni bá sì pa ènìyàn, pípa ni à á pa á. Adájọ́ dájọ́ ikú fún Bádérù. Báyìị́ ni Bádérù ṣe gbọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀.
.
Àwọn ènìyàn pariwo yèèè. Inú wọn dùn nítorí Bádérù ti ṣọṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láàrin ìlú. Ní ọjọ́ tí wọ́n fi ẹ̀yìn Bádérù ti àgbá, ńṣe ni ìlú ń rọ́ kẹ̀kẹ̀. Gbogbo ayé ló fẹ́ wo ikú ẹ̀sín ti Bádérù máa kú. Èrò pọ̀ tí wọ́n wá wòran rẹ̀. Wọn kò ṣàánú rẹ̀ rárá. Ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ ló ń kéèésú rẹ̀. Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀. Olè jíjà kò yẹ ọmọlúwàbí
.
-Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá Òde Òní
.
oroyoruba.blogspot.com.ng

No comments:

Post a Comment