7.10.16

ÀRÒKỌ

MO DI OBÌNRIN
oroyoruba.blogspot.com.ng



Oṣù kẹta lẹ́hìn tí ìyá mi kú ni mo di obinrin. Mo bẹ̀rẹ̀ síi rí ǹkan oṣù mi. Ẹ̀gbọ́n mi ti rí ti ẹ̀ síwájú; ìyá mi sì ti ṣe àlàyé díẹ̀ fún mi nípa rẹ̀. Ẹ̀rù kò bà mí púpọ̀, ṣùgbọ́n ó sì jẹ́ ohun ìyàlẹnu fún mi, ó sì ṣe àjèjì lára mi fún ìwọ̀n ọdún mélǒ kan.
.
Ìyá mi pèmí sí ìyàrá rẹ̀, ó ní, Ìyábọ̀, o di obìnrin lónǐ o. Ọjọ́ pàtàkì ni ọjọ́ yìí jẹ́ fún ọ, ọjọ́ ayọ̀ sì ni o. Òní ni o mọ̀ pé obìnrin ni ọ́; tí o lè di abiyamọ. O ní láti tọ́jú arà rẹ, kí o má jẹ̌ kí eṣù tán ọ̀ jẹ kí o lọ bá ọkùnrin ṣe eré ìṣekúṣe. Ẹni tí ó bá ti ń rí ǹkan oṣù rẹ̀, tí ó bá bá ọkùnrin ṣ’erékéré, oyún ni yóò ní. Ọmọ ni a gbàdúrà kí a fi oyún bí.
.
Ǹkan pàtàkì ni oyún, ayọ̀ púpọ̀ sì ni ó ń fún ni tí ènìyàn bá ní oyún ní àsìkò tí ò tọ́, àti àsìkò tí ó yẹ, èyí sí ni lẹ́hìn ìgbéyàwó. Ẹni tí ó bá lọ lóyún, tí ó lọ bímọ, kí ó tó gbé ìyàwó, ó sọ epo di àbàwọ́n nìyẹn.
.
‘Ṣé o mọ̀ pé, óúnjẹ ni epo pupa, òhun ni a fi ń se ọbẹ̀, tí a fi ń se óúnjẹ gbogbo. Kò sí ẹni tí kò fẹ́ epo nínú ọbẹ̀, tí kì í rà á ní ọjà, ṣùgbọ́n tí epo bá lọ dà sí aṣọ mímọ́ pàtàkì olúwarẹ̀, kíákíá ni olúwa rẹ̀ yóò lọ fọ̀ ọ́ dànù’. Orí aṣọ wíwọ̀ wa pàtàkì kò ní ilé epo, níto rí náà, fífọ̀ dànù ni a ó fọ̀ ọ́ dànù. Bẹ́ẹ̀ náà ni oyún; tí ènìyàn bá lọ ní in ní àsìkò tí kò dára, ó di epo tí ó dà síni láṣọ nìyẹn, kàkà kí a jẹ óúnjẹ pàtàkì tí a fẹ́, tí ó sì máa ṣe wá ní oore, á di ohun ìbànújẹ́ fún wa. Fi ojú sí ìwé rẹ títí di àkókò tí ìwọ yóò fi rí ọkùnrin tí ó wù ọ́, tí ẹ ó sì ṣe ètò àti gbéyàwó l’ọ́jọ́ iwájú. Bí o bá lọ ní oyún ní àkókò tí o wà ní ilé- ìwé, ìwọ ni yóò pòfo.
.
‘Ọkùnrin yóò máa bá iṣẹ́ tàbí ìwé rẹ lọ, ṣùgbọ́n obìnrin parí tirẹ̀ síbẹ̀ nìyẹn o. Èrò burúkú àti ba oyún jẹ́ ni í máa ń wà l’ọ́kàn obìnrin tí ó ní oyún àìròtẹ́lẹ̀. Nítorí náà, Ìyábọ̀, ṣọ́ra rẹ o. O ti di ẹni ẹlẹgẹ́ láti òní lọ. O ti di ẹyìn tí a gbọ́dọ̀ dìmú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ nítorí tí a bá jẹ́ kí o bọ́, tí o sì fọ́, kò ní ṣé kójọ mọ. Jọ̀wọ́ o, Ìyábọ̀, ṣe ọmọ dáadáa o. Ààbọ̀ ọ̀rọ̀ ni à ń sọ fún ọmọlúwàbí, tí ó bá dé inú rẹ̀ á di odidi.
.
Mo ti dàgbà t́o láti mọ ǹkan tí ìyá mi ń sọ, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ sì dàrú mọ́ mi lórí. Nígbà tí ìyá mi ṣàdúrà fún mi, tí ó sọ gbogbo èyí tí ó níi sọ tán, ṣe ni mo wọ ìyàrá lọ, tí mo lọ sọkún bí ẹni pé ọ̀fọ̀ ṣe mí.
.
Ìyàlẹnu ni ó jẹ́ fún mi ní ọjọ́ kejì tí bàbá mi pè mí tí ó kí mi, tí ó sì fún mi ní owó fún orííre pé mo di obìnrin, tí ó sì ní kí n mú owó náà fún ìyá mi, kí ó sì fi se óúnjẹ fún mi. N kò tilẹ̀ rántí bí wọ́n se óúnjẹ nígbà ti ẹ̀gbọ́n mi, ṣùgbọ́n ti emi yìí jẹ́ ǹkan tí n kò le gbàgbé.
.
Ìyá mi ní kí n pe àwọn ọ̀rẹ́ mi wá láti ilé-ìwé wa. Mo ní kín ni n ó sọ fún wọn pé mò ń ṣe. Ìyá mi ní kí n kàn ní ìyá àti bàbá mi fẹ́ ṣe sàráà fún mi. Irọ́ ọjọ́ ìbí kò ṣé e pa nítorí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ni wọ́n mọ ọjọ́ ìbí mi.
.
Mo sọ fún ọ̀rẹ́ mi kan pé ìyá àti bàbá mi fẹ́ ṣe sàráà fún mi ní ọjọ́ àbámẹ́ta, tí à ń pè ní Sátidé, mò sì fẹ́ kí o wá. Kí n tó sọ̀rọ̀ tán ni ó ní, ‘ Tàbí ìwọ náà ti di obìnrin?’ Mo ní láti jẹ́wọ́ fún un. Ó ní ní oṣù tí ó kọjá ni òun náà rí ti òun tí bàbá àti ìyá òun náà ṣe sàráà fún òun. Èyí jẹ́ kí ara mi fúyẹ́ díẹ̀. Díẹ̀ nínú àwọn tí mo pè mọ ohun tí ó fa sàráà yìí. Àjọ wa ní ọjọ́ Satídé náà si dùn ju bí mo ti ní èrò lọ.
.
Adìẹ mẹ́ta ni ìyá mi pa, ó sì se ìrẹsì. Ó sì tún ra ọsàn, ìrèké àti ọ̀gẹ̀dẹ̀. ‘Wà á ṣe obìnrin kalẹ́ o. Wà á bí ọkùnrin, bí obìnrin, tí ọjọ́ bá yá o. O kò ní ṣi ilé wọ̀,’ ni ìyá wa àgbà kan kí mi. Èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé ìyá mi ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi fún- un.
.

- Ìyábọ̀

oroyoruba.blogspot.com.ng

No comments:

Post a Comment