7.10.16

ORÍKÌ

IGÚN


Igún, ọmọ ajẹbọ,
Lábàlúyẹ̀gẹ̀, ọmọ a-jẹ̀’ gbin-kàsì- má-bì;
Igúnnugún tiiri ẹnu gọ́gọ́.
Àbàlúyẹ̀gẹ̀, lásán kí ‘Gún ò n’írun lórí.
Igún ń’írun lórí, ẹbọ l’ó m’órí Igún
Pá kánrin- kése.
.


K’á rúbọ àgùtàn, k’á tún m’ádìẹ ọ̀ṣọ́rí,
K’á fi rúbọ s’óríta;
Gbogbo a-jí-mú-t’ẹbọ-gbọ́
T’igún ni wọ́n ń ṣe.
Igúnnugún tí í jẹun ẹbọ gbé
.
Òjò gbogbo l’órí akítì ní í dáá lé..
Aró pẹ̀ l’ómi, ó d’òkúṣú,
Lábàlúyẹ̀gẹ̀ pẹ́ l’ẹ́bọ, ó d’alákǐsà aṣọ.
Iṣẹ́ nṣẹ́ ‘Gún, Àwòdì ò bá ‘Gún ra.
Ojú n pọ́n ‘Gún, ẹyẹ- oko ò bá ‘Gún ṣe.
.
Igún t’orí ẹbọ, ó f’oríta ṣe ‘lé.
Lábàlúyẹ̀gẹ̀ t’orí ẹ̀gbin, ó fàkìtàn ṣe yẹ̀wù.
Igún l’ẹ́bọ jíjẹ ò ṣe ǹkan,
K’ó yí ni lárá nìkan lèèwọ̀.
Afínjú ẹyẹ tí I f’àkísà ṣè ‘rọ̀rí!

No comments:

Post a Comment