7.10.16

ÌṢINI L'ÉTÍ

OLÉ JÍJÀ ÀTI ÌDIGUNJALÈ.

Àkíyèsí mi sí àwùjo fi hàn wí pé púpò nínú àwa ènìyàn àwùjo ni a máa n fún jíja olè àti ìdigunjalè ní Ìtumò kannáà ní èyí tí wón sì yàtò gédégbé sí ara won.

IRÚ ÈNÌYÀN WO NI À N PÈ NÍ OLÈ?
Olè ni eni tí ó mú/gbé/yo nnkan tí kìí se tirè láìgbàse lówó Olóhun(eni tí ó ni nnkan). Òkan ò jòkan àdàpè ni àwon àgbà máa n fún olè wéwéèwé pèlú ìfojúsun òsunwon ohun tí eni náà gbé àti ònà tí ó gbà gbé e.
ÀFOWÓRÁ; èyí ni kí á beni nísé, kí onítòun wá yo sílè nínú owó ohun tí ó ye kí ó rà. Bí àpeere, eni ti wón rán ní ojà egbèfa náírà àmó tí ó ra elégbèrún náìrà fi owó rá igba náírà ni.

ÌFÉWÓ; èyí ni kí ènì kí ènìyàn ó rí nnkan tí ó pò nílè, kí ó sì yo níbè. Bí wón bá ní ènìyàn n féwó ohun tí ó túmò sí ni wí pé; bí irú onítòun bá gba ègbé odidi nnkan kojá, nnkan náà yóò di ààbò/ìlàjì. JÀGÙDÀ; Èyí ni eni tí o máa n gbé ohun tí ó bá rí tán làìnáání bí yóò ti dún olóhun sí. Àgbétán ni jàgùdà n gbé erù tí owó rè bá bà.

ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ
Àwon ìsòrí olè métèèta wònyí kìí lo ohun ìjà kankan, àwon gan ni òwe "Ìjànbá solè oníléjí" bámu nítorí pé ó rorún fún Olóhun tí ó bá gbóyà láti mú èyíkéyìí nínú àwon olè wònyí.

IRÚ ÈNÌYÀN WO NI ADIGUNJALÈ?
Adigunjalè gégé bí orúko rè ni eni tí ó di ìhámóra Ogun lo sí oko olè. Àwon wònyí a máa mú onírúurú ohunèlò Ogun bí ìbon,òkò, àdá, idà, òbe abbl dání lo sí oko olè láti dáàbòbo ara won nítorí ìdágirì bí onílé bá jí àti láti le wón ìlèkùn. Onílé tí ó bá fé se wón ní ìjànbá ni won máa n dojúko àwon yàtò sí àwon agbanipa, kí ipá onílé ó má baà ká won ni wón fi n di ìhámóra Ogun.

NÍTORÍ NÁÀ,
Gbogbo eni tí ó bá mú,gbé, tàbí yo ohun tí kìí se tirè láìgbàase ni olè nígbàtí adigunjale jé eni tí ó fi ipá gba,mú tàbí gbé ohun tí kìí se tirè.
Àbò mi rèé lórí èyí, kÓlódùmarè ó fún mi lókun láti se àwon isé tí ó tún wà níwájú mi. Àmín.

E kú ìfé Àsà àti Èdè Yorùbá lára mi o.

©Olùkó Èdè Yorùbá Arb(2016)

No comments:

Post a Comment