ORIKI IBEJI
Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún.
Ẹdúnjobí
Ọmọ ẹdun tíí ṣeré orí igi
Ọ́-bẹ́-kẹ́ṣé-bẹ́-kàṣà,
Ó fẹsẹ̀ méjèèjì bẹ sílé alákìísa;
Ó salákìísà donígba aṣọ.
.
Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọ́mọ.
Wínrinwínrin lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀.
Tani o bi ibeji ko n'owo?
.
Ẹ̀jìrẹ́ okin, edun a gb'origi reterete!
Ẹ̀jìrẹ́ ti mo bi, ti mo jo
Ẹ̀jìrẹ́ ti mo bi, ti mo yó
Ẹ̀jìrẹ́ ara isokun
Omó édun nsere lori igi
.
Ẹ̀jìrẹ́ wo ile olowo ko ló
O wo ile olola ko ló bé
Ile alakisá lo ló
Ẹ̀jìrẹ́ só alakisá di alasó
O só otosi di olowo
.
Bi Taiwo ti nló ni iwaju
Bééni, Kéhinde ntó lehin
Taiwo ni omode, Kehinde ni ebgon
Taiwo ni a ran ni sé
Pe ki o ló tó aiye wò
Bi aiye dara, bi ko dara
.
O tó aiye wò. Aiye dun bi oyin
Taiwo, Kehinde, ni mo ki
Eji woró ni oju iya ré
O de ile oba térin-térin
Jé ki nri jé, ki nri mu
No comments:
Post a Comment