10.10.16

ÌWÚRE

Bí ewé bá jábọ́ lára igi,

Tí kò rí gbòn̄gbò tilẹ̀,

Tó ṣe kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ bẹ́ẹ̀ dójú omi,

A padà di Ìràwé!!.

Bẹ́ẹ̀ Ìràwe kan kò ní fojú kan odò láì sègbé!!.

Èdùmàrè jọ̀wọ́, gbogbo ohun tí a fòwúrọ̀ àti ọ̀sán ayé tiwa ṣe,

Máse jẹ́kí ó dàsálẹ́ parẹ́ lójú ayé àti lẹ́hìn wa!!

Ó dàsẹ ni tÈdùmàrè!!.

No comments:

Post a Comment