Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ẸBÍ WA
APÁ KẸRIN
.
Nǹkan púpọ̀ ni mó fẹ́ bèèrè lọ́jọ́ náà lọ́hǔn, ṣùgbọ́n n kò rí ẹni bi. Gbogbo èèyàn ló bara jẹ́ tí wọ́n ṣe bí ẹni pé wọn kò tilẹ̀ rí àwa ọmọdé- ilé. Títí kan àwọn tí wọ́n máa ń yọ̀ kí wa, lásán ni wọ́n kí wa. Obìnrin kan tilẹ̀ sọkún tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí kò tilẹ̀ mọ̀ pé èmi ni mo jókǒ ní kọ̀rọ̀ kan ní ẹ̀yìnkùlé.
.
Wọ́n ti gbé ìbùsùn bàbá mi sí pálọ̀. Mo rí gbogbo àwọn nǹkan tí wọ́n ti rà láti fi sin òkú náà kí wọ́n tó sin ín. Ńṣe ni mo fi gbogbo rẹ̀ ṣe ìran wò. Wọ́n ní kí gbogbo ènìyàn yẹra o, wọ́n ń gbé òkú bọ̀. Mo gbọ́, mo sì fẹ́ wò ó, ṣùgbọ́n ìyá wa àgbà kan lé mi sẹ́hìn. Ó ní, ‘Àwọn ọmọ ayé ìdayìí mà láyà o. Wọ́n ní wọ́n ń gbé òkú bọ̀, ìwọ Ìyábọ̀ ń yọjú. O fẹ́ wo òkú ni?’ Bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ kí n rí òkú náà wò bí wọ́n ṣe ń gbé e bọ̀. Yàrá bàbá mi ni wọ́n gbé e lọ. Mo sì mọ̀ pé wíwẹ̀ ni wọ́n lọ wẹ̀ ẹ́ nítorí mo ri àwọn ènìyàn wa tí wọ́n ń gbé kàn-ìn-kàn-ìn, igbá omi, aṣọ ìnura, wọ ilé. Ó pẹ́ kí wọ́n tó jáde, wọ́n ní wọ́n ti wẹ òkú tán, wọ́n sì ti wọ ‘ṣọ fún un tán. Wọ́n ní wọ́n ma gbé e lọ sí pálọ̀. Wọ́n wá tẹ́ ẹ sí orí ìbùsùn bàbá mi tí wọ́n ti tẹ́ aṣọ funfun lé.
.
Ó tó agogo méjìlá ọ̀sán báyìí. Tí kò bá sí ọ̀fọ̀ tí ó ṣẹ̀ wá ni, irú àsìkò báyìí , ilé- ìwé ni èmi, ẹ̀gbọ́n àtí àbúrò mi ìbá wà ṣùgbọ́n wọn kò jẹ́ kí á lọ sí ilé- ìwé. Nǹkan púpọ̀ ni ó jẹ́ nǹkan ìyàlẹnu fún mi l’ọ́jọ́ ìsìnkú yìí. Wọ́n ní kí emi àti ẹ̀gbọ́n mi wọ aṣọ funfun kan tí a máa ń wọ̀ lọ sí ilé- ìsìn. Ìyá mi sì fún wa ní gèlè dúdú láti wé. N ò wé gèlè dúdú rí ṣùgbọ́n a ṣe bí wọn ṣe wí. A jókǒ sí ẹ̀hìnkùlé, a n gbọ́ ìkini òkú àti ìdánilóhùn oríṣiríṣi. Ẹlòmíràn á sọkún kíkorò, á sì kí àwọn ènìyàn wa báyìí pé:
Ẹ pẹ̀lẹ́ o.
Ẹ kú àjálù.
Ẹ kú ọ̀fọ̀.
Ọlọ́run yóò ṣe é mọ bẹ́ẹ̀.
Ọlọ́run kò ní í jẹ́ k’a r’írú rẹ̀ mọ́.
.
Ẹlòmíràn á tún dé, a ní ṣe irú rẹ̀ ní tiyín mọ́.
Ọlọ́run yóò fi mọ bẹ́ẹ̀.
Ọlọ́run á tìkùn ìbànújẹ́.
.
Síbẹ̀ ẹlòmíràn tún lè kí wa pé:
Ẹ pẹ̀lẹ́ o.
Ẹ kú ẹjọ́ tí Ọlọ́run dá yín.
Ọlọ́run kò ní í fi irú bẹ́ẹ̀ sí sàkání yín mọ́.
Ọlọ́run kò ní í jẹ́ kí ẹ kú àkúrun mọ́ o.
.
Ìdáhùn àwọn òbí wa sí kíkí ọ̀kan-ò- jọ̀kan wọ̀nyí ni:
Ẹ ṣeun, ṣeun.
Ẹ ṣeun, a dúpẹ́ o.
Ọlọ́run kò ní í ṣe é ní àáró o.
Ọlọ́run kò ní í jẹ́ kí ẹ fi irú rẹ̀ gbà á o.
Bí a ti rí náà nìyẹn o.
.
- ÌYÁBỌ̀
Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ẸBÍ WA
ReplyDeleteAPÁ KẸTA
https://oroyoruba.blogspot.com/2016/10/aroko_23.html