11.11.16

ÌTÀN

LAAYE IGBA-N-NNI, LOJO-OJO'UN ANA!


BAYI NI BI ORIN JUJU SE BERE ATI AWON TODA SILE
( Apa Keji)

Moki gbogbo eyin ayanfe wa kaabo sori akotun eto wa eto yin LAAYE IGBA-N-NNI
LOJO-OJO'UN ANA, eku amojuba wa fun itesiwaju itan orin juju ta nbaabo lati
ijeejo a o ni deena penu lojo toni, bee si ni ko ni si atunwi asan o, eje ki a bere ni
paapapa o

ORIN IBILE NI IYA F'ORIN JUJU
Bee ni bi opolopo eeyan o se mo pe orin ibile wa loje iya fun orin juju gege bi o
se je fun awon orin yooku, lara orin ibile yi ni won ti yo orin bi apala, senwele waka,
ati beebelo, orin ti a n pe ni orin juju lojo toni, bi awon orin yooku se bere lo'un
naa se bere o, kin ni kan nipe idi emu, idi oguro nibi gbogbo tawon eeyan ti n se
faaji won leyin ise oojo won ni, lagbo faaji nile elemu ni won ti koko awon orin yi, gbogbo
nkan ti mo n so yi o ko i ti i ju odun 1920 lo ti orin naa gbile nilu Eko lo, kin ni kan ti
o daju saka nipe lati odo awon eeyan wa ti won ti rin irn ajo lo sawon ilu okere ni won mu
asa naa bo wa ti won si yi pada sede ti ibile wa.

EYI I NI AWON EEYAN TO SE PATAKI NINU ORIN JUJU


Ni ibere pepe ti ko ti i si orin juju iwonba awon eeyan meta si merin lo saba ma
n korin yii ni ibere pepe, bi won se ma n to ara won nipe eeyan kan yoo maa korin ti
yoo si gbe irinse pataki kan ti o mu orin naa yato si tawon yooku ti won n pe ni Banjo yi
lowo ti yoo si maa ta kinni ti won n pe ni Banjo yi bi jita atijo, ni odo awon oyinbo ni won ti
gbe wa tori eyii ko jo oun eelo orin kankan nile wa, enikeji yi ni yoo maa ta tamborin, tamborin
yi dabi ilu kan ti won n pe ni samba, sugbon won so saworo tabi ide wewe mo
leti ti yoo si ma dun jinwin jinwin bi won ba ti n luu, lodo eni to n lu tamborin yi gan-an ni oruko
ti won n pe orin juju yi ti wa saye, oni tamborin yi gan lo so orin juju loruko o, E je kin
farabale salaye re fun yin lekunrere o, bi oro naa se je nipe bi oni tamborin ba ti
n lu tamborin re yi oo, bi ere na bati wa n wo lara tan, ti inu re bere si ni dun ti o si
ti wo ni akinyemi ara bi o ba ti n lu tamborin yi bee naa ni yoo ma ju soke ti kinni naa yoo si tun
maa dun pelu ara oto, bee ni inu awon ero to n woran yoo ma dun ti awon naa
yoo si tun maa pariwo pe juu daadaa juu ki o tun juu, nibi ti won ti n pariwo juu daadaa
juu daadaa yi ni won ti yo oruko orin juju jade gege bi a ti n pe lojo toni o, ti awon
oluworan yoo ma sope mo fe lo woran awon olorin to n ju tamborin bi won ba ti n korin, bee ni won pe kuru
titi tofi di bi a se n pe lojo toni, eeyan keta ti o ma n tele won ni oni sekere bi
enikan ba n korin ti o mtun n ta Banjo, ti oni tamborin naa n lu tamborin to si fi n dasa
lorisirisi bee ni oni sekere naa yoo ma a ta sekere lati ma fi gbe orin won lese ti oun naa yooma gbe orin, eni kerin won gan ni ojulowo agberin leyi tim o tumo si pe koni ise meji ju ki o gbe orin lo.


Tooo, eje ki a danu duro loni lori itan orin juju ta n baabo fun ti toni ki ale loo
mu eto tuntun min-in wa fun yin, mo dupe lowo gbogbo eyin ayanfe wa ti e n fadura
gbewa ro pelu oro iyanju ti e n fi tuwa lokan, e seun oo, ajosepo wa o ni baje lase
Edumare o, Tooo, Agbe mi se tan, Agbe n rele, Aluko mi se tan, O n rode ikosun, Lekenleke
mi se tan, O n rode ikefun nini-n-nini, Olalekan Olaonipekun Akanji iko Ademeto, omo Baba ni Ijeru
Ogbomoso loni bi e ba jeun, ata o ni sa pa yin lori, bi e ba mu omi, koni gbodi lago Ara yin,
bi iku ba wa n sa egbe yin pa, ti Arun si n gbe awon egbe yin de, Oto ni iku ati Arun yoo ma
fi ti yin si o, bi a ba wa ri enikeni ti o n pe Ori yin lai da, Obaraka ki o ma ka gbogbo won da
si Orun. Oodua yoo gbe yin oo, yoo gbe iran mi oo, IRE OOO

- Oojiirebii Osf

No comments:

Post a Comment