11.11.16

ORIN

Ẹskẹkẹnkẹ Àyìndé(2)

Òdòlayé Àrẹ̀mú

...
Yásàlámọ̀ Yásàlámọ̀ alaekum
Ìgbòwó ló n mọ́lẹ̀, ọmọ Kòsọ́kọ́

Ẹ dákun, e má jẹ́ ki tẹ sẹ̀ ó gbọ̀n dànù
Ẹ dákun, e má jẹ́ ki tilẹ̀ ó pọ̀jù ti tẹnu lọ

Mi ò màmà ríhun tó pọ̀ tí ò ní tán
Ìrí tí morí, ṣé mo rí atare, Ẹskẹkẹnkẹ

À ní ọmọ Àmọ́dù, ọmọ Ẹjalónibú
Apá ọ̀tún tí mo wò, mo tún rí kábá

Báǹkí onímuṣin, ọ̀bùn muṣin
Onímuṣin, ọ̀bùn muṣin

Ọgbọngbọn bí ọjọ́ kanrí, agùntáṣọ́ọlò
Orí mọ́námọ́ná ṣiyàn ládé

Kò sí ìyà oró n Muṣin mọ́ páà
Ẹnu igbà tó joyè yìí náà ni, ọba Muṣin

Ìrí tí mo rí, ṣe mo rí atare?
Apá ọ̀tún tí mo wò, mo tún rí kábá
Ẹ̀yìn tí mo wò, mo rí àgádágodo
Ẹskẹkẹnkẹ, Ẹskẹkẹnkẹ

Ọ̀rọ yìí e débi à ń yọ orùka
Ṣébi min ò lóògùn, kédì ewé jíjá
Àyìndé bí mo bá dejò, ó sá di igi oko

Èyí tí wọ́n ṣe tó kọ̀ tí kòjẹ́ oo; yéèèèè
Àtèyí wọn máwọ̀ wèrè ṣe

Ní Muṣin
Olówó kan ò lè dún kowéè lé ọ lérí mọ́
Àyìndé ọwọ́ ti tẹ àgádágodo wọn

Elégbodo kan ò lè dún kowéè lé ọ lérí mọ́
Àyìndé ọwọ́ ti tẹ àgádágodo wọn

Akéwejẹ! Akéwejẹ!!
Akéwejẹ gbogbo Èkó

Kìnìún Ìdímù tíí ṣẹ́mọ à á ṣẹ́ mọ kọ́lá ó dígbọ́n
N ò rí ohun tí kòlè fi tọrọ
Íí ràlẹ̀ í fún èèyàn
Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ mí oo
Bí ebi bá ń pamí oo
B’órun bá ń kùn mí oo
Ó dilé Ẹskẹkẹnkẹ
Kìí pé àlejò pé ibo lóti wá

Ọmọ Ẹjalónibú
Bí Géḿbérí bá wọlé ẹ, á jẹun
Bí ó bá jẹun mumi tán, á ní kó máa lọ
Ẹskẹkẹnkẹ

Àjọsọ Kìnìún ọmọ Àdísátù
Bí Géḿbérí bá wọlé ẹ, á jẹun
Bí ó bá jẹun mumi tán, á ní kó máa lọ
Ọ̀ríjínà Yoòbá
Bí ó bá jẹun mumi tán, á ní kó máa lọ
Ẹskẹkẹnkẹ

Kìí pe wọ̀bìà, Bí ó pajá ẹ̀ kó wá jẹun
Ṣùrù lọlá tí ń bọ́ báálé tẹrú tọmọ
Baba toní o ó dà lo dàyìí
Àjọsọ Séríkí

Àgbà toní o ó dà lo dàyìí
Bo ṣe bí o ṣe ń ṣe ni, ni o máa ṣe
Àyìndé, Baba Akeem

Bí o bá ti rí ọmọ kékeré o máa fọmọ kékeré mọ́ra
Baba Enjiníà, baba lọ́yà, bàbá adájọ́
Àyìndé bí o rágbà o f’àgbà mọ́dọ ọọọọ
Ẹskẹkẹnkẹ
Baba dókítà
Àgbà ló ń báni ṣèlú, ọmọ kékeré ni ń báni tún ilé ẹni ṣe
Ẹskẹkẹnkẹ

Àyìndé má j’obì lọ́gànjọ́ mọ́ ọọọ
Ẹni bá rí ni tán ló ń ṣekú pani
Kòrí kòsùn ló pa Jimoh, ọmọ Àgbókí l’ádífá
Àpọ́nlé òògùn, là ń so ońdè mọ́wọ́
Ẹskẹkẹnkẹ Àyìndé

Tani ikú ò bá faragbá tí kò mú lọ?
Ìdájí ìdájí lo l’ógùn ń kú, ọmọ Àgbókí l’ádífá
Ọ̀ré rẹ ńkọ́, ṣé ó ń bẹ lá làáfíà ara?
Bùṣìrá, ọmọ Agúnbíadé
Ikú gberí kangí ọmọ Agúnbíadé


...

No comments:

Post a Comment