4.11.16

ORIN

ESKEKẸNKẸ ÀYÌNDÉ(1)

- Odòlayé Àrẹ̀mú


AwúsùbìLáàyì
Mínàṣàìtọ́nì Rọ̀jíími
Bísímìláàyi Aramọ́ọ́ni Rọhíìmì
.

Àti wálé ayé ọjọ́
Ìbà lọ́wọ́ rẹ
Odòlayé ni ń wí ìbà yìí o
.

Àti wọ̀ oòrùn
Ìbà lọ́wọ́ rẹ
.

Àáfà tó yàn, tó yan jú
Tínú ẹ̀ mọ́, tó ya wòólì
Ìbà lọ́wọ́ ẹ̀yin o
.

Ẹ̀yin tẹ́ ẹ layé
Ìbà lọ́wọ́ ẹ̀yin o
.

Ẹ̀yin ọmọ kéèkèèké tẹ́ ẹ ṣẹ̀ lẹ́yìn wa
Ìbà lọ́wọ́ ẹ̀yin o
.

Kini ‘ǹfààní ẹni tóní ọwọ́ ayé ò le tẹ òun
Tí ń janu, tí ń ṣagbaja, tí ń tún minu
Àkámarà èé jẹ́bẹ̀
.

Ìgbà tí ayé bá ṣe èèyán tán
Wọn á sì dárò bọnu
Tí ayé bá ṣe èèyán tán, wọn a l’ódò rè é gbétí lé
.

Ṣé kí n máa lọ, ṣé kòsí nǹkan?

Ègbè: Wọ́n ní kòsí ǹkankan
.

Mo ríbà ‘i’ ríbá, mo ríbà dagbaro
Ẹbọra lágbó ẹgẹ, Ọ̀bá di méji; a gbẹwọ̀n gbẹ̀gẹ̀dẹ̀
.

Pẹ̀lẹ́ bí ẹ gbóhùn àríri, abínú fọhùn bí ènìyàn
Mo ríbà ‘i’ ríbá, mo ríbà ìyá mi oo
Ajíbọ́lá ẹdan
Ìyá mi ẹdọ̀ ọrọ oo
Ọ̀rọ̀ tí ń gbénú ilédì tí ń kùn yùnmùyùnmù
.

Ní alẹ́ yìí, ìbà lọ́wọ́ Ajíbọ́lá
Ará ìlú ète, ará ilú eédú
.

Ọlọ́ṣùn ún tẹ́rẹ́, abirù tínrín
Bóbá dú lójú, a dú lénu
Aájò lápá ìsàlẹ̀ woyìwoyì
Afínjú Àdàbà tí ń jẹ́ láàrín ín òrófo
Afinjú ẹyẹ tí ń jẹ ní gbangban ilé ọba
.

Àákú ayé ò bá o
Aa
Àákú ayé ò bá o, ilẹ̀ ló tún tẹ̀yin ṣe
Ọmọ aláya ọba, èyí tí ń ṣàǹfàni nínú ilédì, ọmọ àgbàgbà ìmùlẹ̀
Afínjú ońmùlẹ̀ tí ń so kùtúkùtú mọ́wọ́
.

Ẹ má wò ó óóó
Ẹ̀yin ọ̀dàlè ènìyàn
Ṣòkè ṣodò
Ẹlẹ́nu mẹ́rin-dín-lógún
Agbọ́ yìí sọ̀ yìí; Asọ̀lú kọ̀lú
Kẹ́ni mánǐ; Wèrè; Dìgbòlugi
.

Ẹ má debi a ò pèyín o
Ẹ ò gbọdọ̀ wo o, ojú ò gbọdọ̀ ri
.

Ẹ ò wá wo ọmọ inú ọgbà bí wọ́n ti ń ṣe
Àwọn ọmọ Àbẹ̀ní, ọmọ Oótù Ifẹ̀
.

Ní alẹ́ yìí, ìbà lọ́wọ́ Dángbọ́ngbọ́n baba kóko
Erù ọgbọ̀n gandàn, baba Ìlosùn
.

Aṣọ mẹ́rin-dín-lógún laṣọ Ṣọ̀npọ̀nná
Ọ̀kan lahún Ìlárá- Eskẹkẹnkẹ
Hájì kámaṣọ
Yínmíyínmí píṅkin
Ọgọgọlúmọlúmọ
Apẹran máwàkú, olókìkí òru
.

Ìbà lọ́wọ́ yín, atìdí mùjẹ̀ èèyàn
Ìyá mi, ọ̀rẹ́rẹ́ oo, ooooo, ooooo
Ati ojú j’orí oo
Ati ẹdọ̀ jọkàn
Ati òróǹró jẹ̀fun Ọ̀gàlàǹta
Ajẹran òró òó
Ajẹ ẹ̀dọ̀ èèyàn mabì
Ẹ̀yin lẹ kọ́mi lódù, tẹ sìnmí wálé ayé
Tẹ́ẹ sọ pé ilé ayé tí mo wá, orin ni kí n máa kọ, kí n máa fi jẹun
.

Èkó náà la wàyìí
Olú Nàíjíríà gan la wàyìí
Muṣin la wàyìí
Ọ̀dọ Ẹskẹkẹnkẹ la wàyìí
Ọ̀dọ ọmọ Ààmádù la wàyìí
Ọ̀dọ̀ Àyìndé la wàyìí
Ọ̀dọ Kìnìún Ojúwóyè la wàyìí
Ọ̀dọ Ìyàndá ọmọ Àdísátù la wàyìí
Ọ̀dọ Akódúdú la wàyìí
Ẹ dákun, ẹ má jẹ̀ kí tọwọ́ ó bọ́
-----


Ó ń tẹ̀ síwájú

1 comment:

  1. Orin tí Bàbá Odòlayé Àrẹ̀mú kọ láti fi ki Eskẹkẹnkẹ Àyìnde.

    Dadakúàdà ni èyí

    ReplyDelete