5.11.16

ORÚKỌ

ORÚKỌ TÍ Ó JẸ MỌ ÀSÌKÒ

1. Ọ̀tẹ́gbẹ̀yẹ: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ ìlú. Ọ̀tẹ̀ náà sì ti gba ẹ̀yẹ ìdílé

2. Ogúnpọlá: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn tàbí lásìkò ogun. Ogun ti pa ọlá ìdílé

3. Abíóyè: Ọmọ tí a bí lásìkò tí bàbá rẹ̀ wà lórí oyè

4. Abíọ́lá: Ọmọ tí a bí sínú ọlá tàbí lásìkò tí àwọn òbí rẹ̀ ní ọlá púpọ̀

5. Abíọ́nà: Ọmọ tí a bí lásìkò tí ìyá rẹ̀ wà lójú ọ̀nà sí ibì kan yálà ọ̀nà oko, ọ̀nà odò, ọ̀nà ọjà, ìrìn- àjò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

6. Abíọ́sẹ̀/ Abọ́sẹ̀dé/Ajọ́ṣẹ̀/ Jọ́ọ̀ṣẹ̀ (Ọjọ́- ọ̀sẹ̀): Ọmọ tí a bí lọ́jọ́ ọ̀sẹ̀ Òrìṣà-ńlá; tàbí lọ́jọ́ ọ̀sẹ̀ òyìnbó lóde òní.

8. Bọ́sẹ̀dé: Orúkọ obìnrin ni èyí

9. Abíọ́dún/ Abọ́dúnrín/ Abọ́dúndé: Ọmọ tí a bí lásìkò ọdún pàtàkì kan- Ó le ṣe ọdún ẹ̀sìn tàbí ọdún ìlú

10. Ọdúnjọ/ Ọdún- Ifá/ Ọdúnayọ̀: Ọmọkùnrin tí a bí lásìkò ọdún Ifá tàbí ọdún mìíràn

11. Babájídé/ Babátúndé/ Babárìndé/ Babáwándé: Ọmọkùnrin tí a bí ní kété tí bàbá rẹ̀ kú. Orúkọ yìí fi ìgbàgbọ́ Yorùbá nínú àjínde múlẹ̀

12. Yéwándé/ Yéjídé/ Yétúndé/ Ìyábọ̀dé/ Yésìdé: Ọmọbìnrin tí a bí ní kété tí ìyá bàbá rẹ̀ kú

13. Babárínsá/ Babárímisá/ Òkúgbésàbí: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, bí ọmọ bẹ́ẹ̀ bá jẹ́ ọkùnrin

14. Jọ́họ̀jọ́/ Yérímisá: Ọmọbìnrin tí a bí tí ìyá rẹ̀ sì kú lọ́jọ́ náà tàbí kí á tó sọ ọ́ lórúkọ

15. Adéọjọ: Ọmọkùnrin tí a bí tí ìyá rẹ̀ sì kú lọ́jọ́ náà tàbí kí a tó sọ ọ́ lórúkọ

16. Àbíìbá: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, pàápàá bí ó bá pẹ́ díẹ̀ tí baba rẹ̀ ti kú kí a tó bi i

17. Ábíára: Ọmọ tí oyún rẹ̀ kò tí i hàn dáadá tí baba rẹ fi kú. Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ ju oṣù mẹ́sàn- án lọ tí baba rẹ̀ ki á tó bí i

18. Babáyẹjú: Ọmọbìnrin tí a bí lẹ́yìn ikú baba rẹ

No comments:

Post a Comment