20.4.17

ÒWE

ÒWE: A kó bá ni l’Èkúté ilé, Ejò kìí j’àgbàdo
.

ÌTUMỌ̀: Ìṣẹlẹ̀ kìí dédé wáyé, ohun kan ló máa ń fà á wá
.

ÌTÀN: Ò tó ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn báyìí ní ìletò kan tí ń jẹ́ Sọkúlú lẹ bàá ìlú kan tí ń jẹ́ Fẹ̀yìntì. Ní gbogbo ìletò náà, kò sí alápatà kan (ẹlẹ́ran ní ń jẹ́ alápatà) ọkùnrin ẹlẹ́ran kan ní ń máa kiri wá sí ìletò náà. Ibi tóun pàápàá ń gbé jìnnà réré sí ìletò tó ń kiri wá. Ọjọ́ mẹ́tamẹ́ta ni ó máa ń kiri wá, torí èyí , gbogbo èèyàn ìletò náà ti mọ̀ ọ́n. Kódà, ní kété tó bá ti dé ni gbogbo èèyàn yóò ti mọ̀ torí gbogbo ọmọ kékeré inú ìletò náà ni yóò tẹ̀le e tí wọn yóò máa ba gbé ìpolówó ọjà rẹ̀. Tí bàbá ẹlẹ́ran bá ní “Yè-è-é, ó wọjú o, ẹ-ẹ̀rẹran, K-ẹ́-ẹ-sẹ́lẹ́ńkẹ́jọ̀”. Gbogbo àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tó tẹ̀ɔẹ yóò dáhùn . “Yè-è-é”, Igbe yìí ló ma ń polówo ọjà bàbá fún raa rẹ̀!
.

Ní gbogbo ìgbà tí bàbá bá gbé ẹran ka orí, ewé díẹ̀ , ni ó ma fi bò ó, yóò wá fi ọ̀bẹ ìgéran rẹ̀ lé e.
À ṣé àwọn ẹyẹàwodi kan wà̀ ní ìletò yìí tí wọ́n ti máa ń ṣọ́ bàbá ní ìgbà tí ó bá ń kiri ká inú ìletò náà. Àwọn ẹyẹ àwodì ti ṣe ìpàdé ní àìmoye ìgbà láti kó gbogbo ẹran orí bàbá alápatà yìí ní ìgbàkigbà tí àwọn bá péjú, torí ọ̀pọ̀ ìgbà ní bàbá sì ń kiri wọ inú ìletò tí àwọn àwodì yóò sì ti wá nǹkan jíjẹ, mímu wọn lọ.
.

À mọ́ lọ́jọ́ tí ìṣẹlẹ̀ yí máa wáyé, bàbá kiri ẹran wọ inú ìletò, àwọn ọmọdétẹ̀lé bàbá ẹlẹ́ran bí ìṣe wọn. Bàbá ń ta ẹran káàkiri, ó dé ọ̀dọ oníbáráà kan, ó sọ̀kalẹ̀, òun àti onítọ̀ún dúǹá dúrà ẹran dáadáa. Ìná sì wọ̀, bàbá gé ẹran fún onítọ̀ún ló bá tún gbé ẹrù rẹ̀ lórí ló ń kiri lọ. À ṣé àwòdì méjì ti rí bàbá láti ìgbà tó ti wọ inú ìletò.
.

Ǹ jẹ́ bí bàbá ṣe gbé ẹran nílẹ̀ tó gbé e lérí ní àwọn àwòdì méjì fò bàràbàrà tí wọ́n ya lu inú ọpọ́n ẹran bàbá. Yé è! Ni bàbá fi igbe ta, àwọn àwòdì kò rí ẹran gbe, ọ̀bẹ bàbá ni wọ́n kì mọ́lẹ̀.
.

Bi

No comments:

Post a Comment