13.5.17

ÌRÍRÍ

OKÀN AKIN NI A NÍLÒ

Àseyorí kìí se ohun tí ó rorùn pàápàá fún eni tí kò bá réni bálà,sé e mò pé bí a ò bá réni bálà olà kìí yá. Gbogbo èdá ní ó fé láti là, àmó èta hóró ènìyàn ni ó lè fi ara da ìsòro tí ó rò mó gígun òkè Àseyorí.
Ìrírí mi ní òkè Láńgbòdó nínú igbó Olódùmarè ní odún 2016 jé kí ó túbò yé mi síi wí pé, níní ìfé láti se àseyorí nìkan kó ló lè mú ni se àseyorí bíkòse níní okàn akin láti fi àyà ró ìsòro tí ó bá yojú lójúnà àtilà. Gbogbo àwa tí a dé òkè Láńgbòdó ni inú wa dùn láti rí òkè náà,sùgbón ògédé olókàn akin nínú wa ni ó lè gun òkè dé téńté nítorí pé bí a se ń to mó on ni ó ń yò wá padà, béè ni àwa náà sì ń tún un gùn títí tí a fi dókè.

OHUN TÍ MO FÉ KÍ Á MÒ


Àwon àgbà a máa so pé; "Ohun tí ó dára kìí fé kí á se òhun, okàn akin làá fií làlùyo". A nílò láti pèsè okàn wa silè de ìsòro saájú kí ìsòro gan ó tó yojú kí ó má baà báwa lójijì, Kí á sì máa fi okàn tótó pe Olórun. E máse fi ààyè gba ìsòro tàbí ìjákulè láti díi yín lówó lójúnà láti se àseyorí. Bí e bá lè ní okàn akin, e ó dèé òkè àseyorí láìpé jojo.
Olódùmarè yóò gbé wa lékè gbogbo ìdojúko wa. Àse.
©Olùkó Édè Àti Àsà Yorùbá Arb(2017)

No comments:

Post a Comment