23.10.16

ÒWE

ÌTAN D’ÒWE


Kò sí bọ́mọdé ṣe lè tètè jí kúrò nílé, oko ló má a bá kùkùté.
.

ÌTUNMỌ̀:

Kò sí èèyàn ṣe lè ní òun gbọ́n tinú tẹ̀yìn tí kò níí bá ẹnìkan tó gbọ́n jù ú lọ níwájú.
.

ÌTÀN:
.

Àwọn bàbá wa bọ̀, wọ́n ní, ṣàṣà èèyàn ló ń fẹ́ni dékùn tá ò bá sí ńlé, àmọ́ tẹrú tọmọ ní ń fẹ́ni lójú ẹni. Ọ̀rẹ́ méjì kan wà láyé àtíjọ́; kòríkòsùn gbáá ni wọ́n. Iṣẹ́ òkòwò ni wọ́n jọ ń ṣe. Ọ̀rẹ́ kìn- ín- ní jẹ́ olóòótọ́ gidi, èkejì sì ń fi àṣírí rẹ̀ pamọ́ síkùn, kìí nà tán fọ́rẹ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀rẹ́ yìí kò mọ̀. Ó wá gbàgbé pé ọba lókè Arínúríta, Olùmọ̀ràn ọkàn kọ ìwà mànáfìkí. Pẹ̀lú èyí ni àwọn ọ̀rẹ́ méjéèjì jọ ń ṣòwò, tí wọ́n ń bóde pàdé tí wọ́n sì ń kó èrè wọn pọ̀ sójú kan náà.
.

Ní ayé àtíjọ́, kò sí báńkì bíi tayé òde òni, bẹ́ẹ̀ ni àjọ tàbí èsúsú dídá kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́ pọ̀ rárá. Ihò ni àwọn èèyàn ń gbẹ́ tí wọn ma ń kówó pamọ́ sí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi ohun èlò tó nípọn bo ẹnu ihò náà, àwọn tó ní owó nìkan ló sì ń mọ́ èyí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ wí pé ìyàwó pẹ̀lú ọmọ kì í mọ ibi tí owó yìí fara sin sí. Ní bò míràn ẹ̀wẹ̀, wọ́n má á ń lo inú akèǹgbè láti kówó pamọ́ sí.
.

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe lọ, àìsàn nawọ́ gán ọ̀kan nìnú àwọn ọ̀rẹ́ méjéèjí yìí, ikú foní kà sílẹ̀, ó mú onínúure lọ; ó wá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ tí inú rẹ̀ mọ́ sí ọ̀rẹ́ kejì ni àìsàn kì mọ́lẹ̀, inú àìsaṅ náà ló kú sí. Ní wàrànṣesà tí ọ̀rẹ́ yìí ṣán kú ni àwọn ará ilérẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ òpò ṣíṣe. Ẹni tí yóò gbẹ́ ilẹ̀, àwọn tí yóò wẹ òkú àti bàbá- ń- sìnkú.
.

(Bàbá-ń- sìnkúni ẹni tí ń darí gbogbo òpò àti wàhálà ìsìnkú ní ilẹ̀ Yorùbá.)
.

Ìròyìn dé sí etí ìgbọ́ ọ̀rẹ́ kejì pé ọlọ́jọ́ ti dé bá ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ ń ṣòwò. Lẹ́sẹ̀ kan ló dìde, tó gba ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ṣaláìsí lọ. Ó bá àwọn èèyàn lẹ́nu wàhálà ìpalèmọ́ òkú, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí sá síwá, sá sẹ́yìn; lẹ́yìn iṣẹ́ díẹ̀, ó tọrọ ààyè pé kí wọ́n jẹ́ kòun fẹsẹ̀ kan dé ọ̀dọ̀ oníbàráà wọn tó jẹ wọ́n lọ́wó, kí díẹ̀ ó tún lè gun orí owó tí wọn yóò ná ní bi ìsìnkú ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ẹ̀yin òǹkàwé, jagunlabí kò gba ibì kan lọ ju ibi tí òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó dolóògbé fi owó pamọ́ sí.
.

Dípò kí ó wu ìwà òòtọ́, kò ṣojú ṣẹ̀yìn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣe ni ó kó gbogbo owó tó wà níbi tí wọ́n ra sí(èyí ni ibi tí wọ́n kówó pamọ́ sí) tó sì dà á sápò, ló bá gbérà ló darí sí ilé ọ̀rẹ́ re tó dolóògbé níbi tó gbé dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tó ń ṣòwò lọ́wọ́. Kò pẹ́, kò jinnà, wọ́n parí gbogbo òpò òkú, wọ́n sì wé e láṣọ, ó di ibojì. Wọ́n dé ibojì, wọ́n ṣe gbogbo ètò tó jẹ́ ti ìsìnkú, àwọn ọmọ olóògbé kò gbàgbé ètò ìṣẹ̀mbáyé, wọ́n da yẹ̀pè sí ara òkú, bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí náà ni gbogbo èrò àti àwọn ìbátan òkú ń bá wọn da yẹ̀pẹ bo pósí. Ǹ jẹ́ bí ọ̀rẹ́ ẹni tó kú yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ pé kí òun náà ó bá wọn da yẹ̀pẹ̀ sínú ibojì pẹ̀lú ẹkún èké lójú ni gbogbo owó tí òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ dà sínú ibojì òkú. Ó wá jẹ́ pé gbogbo owó tí òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó dolóògbé jọ ní nípàmọ́ kó tó kú tó lọ jí kó sápò ní ìrètí àti nìkan ná, ló dà sínú ibojì láì ku eépìnnì.
.

Ọ̀rẹ́ ọ̀dàlẹ̀ yìí kò mọ ohun tí yóò ṣe, inú ibojì ò ṣeé kó sí, kò sí ọgbọ́n tí owó le fì di ṣíṣà kúrò nínú ibojì, ọ̀rọ̀ wá dàbí ti akúwárápá tó gbé nǹkan adẹ́tẹ̀ sọnù ni, àìlọ́wọ́ kò jẹ́ kí wọn ó lè lura wọn pa! Pẹ̀lú ìbànújẹ́ àti oríṣiríṣi èrò ni ọ̀rẹ́ fi padà sí ilé. Ódá jókòó sínú ibojì ọ̀rẹ́ rẹ. Ọkàn rẹ̀ ń dá méjì, ó ń rò bóyá òkú ló mọ̀ọ́mọ̀ gba owó lọ́wọ́ òun, èrò m̀íràn sọ sí I lọ́kàn pé, kó lọ, ṣebí àṣìṣe lásán ni owó fi dà sínú kòtò.
Ní gbẹ̀yìn, ọ̀ré gbé ìtìjú tà, ló bá sùn pé tí ó bá di kùtù hàì, òun yóò jí lọ́ sí ibi tí wọn sin ọ̀rẹ́ òun sí, pẹ̀lú èrò pé, òun nìkan yóò lè gbọ́n yẹ̀pẹ̀ inú ibojì jáde, owo àná yóò si di kíkó jáde.
.

Ní tòótọ́, ó jí dé ibi tí wọ́n sin ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí ó gbọ́n gbogbo yẹ̀pẹ̀ inú ibojì jáde, ó sì ṣa owó kúrò nínú ibojì. Ibi tí ó ti ń ṣa owó yìí ni ó ti gbọ́ gìrìgìrì ẹ̀sẹ̀, ó sá kúrò ní sàkàní ibojì ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó ṣáà ti ṣa owó dání tán, ṣùgbọ́n kò tíì gbọ́n yẹ̀pẹ̀ ibojì pàdà! Bí ọ̀dàlẹ̀ ṣe ki eré mọ́lẹ̀ tí ó ń sálọ, ǹ jẹ́ kí ó tó gbé ẹsẹ̀ kẹta ni, kùkùté(àgékù igi) kan bá kọ ní aṣọ, igi yìí kọ́ aṣọ ọ̀rẹ́ yìí dé bi pé tí èèyàn bá ríi, yóò rò pé ṣe ni wọ́n mọ̀ọ́ mọ̀ wé aṣọ náà mọ́ ara igi.
.

Ṣé bí èèyàn bá ṣe rere, ara kì yóò ti onítọ̀ún ní ìgbésẹ̀ kí gbésè yòó wù kó gbé láyé. Bí kùkùté igi ṣe lọ́ mọ́ ọ̀rẹ́, ló bu igbe ta pé “yéè, ẹ gbà-mí- o, òkú ti dì mí láṣọ mú o, ará igbó, èrò ọ̀nà, ẹ wá yọ mí nínú ọ̀fìn yí o”. Ipò yìí ni ọ̀rẹ́ ọ̀dàlẹ̀ yí wà títí tí ilẹ̀ fi mọ́ bá a tí àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe háà, háà, háà, à ṣé bí ayé ṣe rí rè é!
.

Ìtìjú ojọ́ náà pọ̀ jù fun ọ̀rẹ́ búburú yìí kí ó tó mọ̀ pé kùkùté igi lásán ló lọ́ mó òun láṣọ, Ìtìjú yìí ló sì mú u kúrò ní ìlú náà.


No comments:

Post a Comment