21.10.16

ÀṢÀ

ÌSỌMỌLÓRUKỌ

APÁ KÌNNÍ ÍN: ÌGBÀGBỌ́ ÀWỌN YORÙBÁ NÍPA ORÚKỌ


Àwọn Yorùba kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ètò ìsọmọlórúkọ nítorí pé a ka orúkọ sí ǹnkan pàtàkì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe àti àṣayàn ọ̀rọ̀ tí a máa ń lò ni ó fi bí orúkọ ti ṣe pàtàkì sí hàn. Fún àpẹẹrẹ bí a bá ní: ‘àpọ́nlé ni ìyá káà, kò sí ìyá kan ní káà tí kò ní orúkọ’, ohun tí a ń sọ ni pé kò sí ẹni tí kò ní orúkọ. Ẹni tí a bá fẹ́ pọ́nlé nìkan la lè dàpè tí a kò ní pẹ̀ é lórúkọ rẹ̀ pàtó. Ìṣòro púpọ̀ ni yóó wá bí ènìyàn kò bá ní orúkọ. A kò lè mọ bí máa pe ara ẹni tàbí bí a ó ti máa tọ́kasí ènìyàn kọ̀ọ̀kan bí ó bá jẹ́ pé a kò ní orúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, orúkọ wa la fi máa dá ara ẹni mọ̀. Bí ènìyàn bá jẹ́ méjì ni wọ́n le lo ‘ìwọ’ fún ara wọn tí ẹni a lò ó fún yóò fi mọ̀ pé òun ni à ń bá wí. Bí a bá lo ‘ìwọ’ láti tọ́ka sí ẹnìkan nínú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ẹni tí à ń báwí kò lè mọ ara rẹ̀ nítorí pé ‘ìwọ’ tọ́ka sí ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ni.
.

Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn Júù, Ẹlẹ́dàá tì kárarẹ̀ ló fún ẹ̀dá alààyè kìn-ín- ní ní orúkọ. Ẹ̀dá alàyè náà lósì fún ẹni tí a dá tẹ̀le e ní orúkọ. Òun náà ni Ẹlẹ́dàá fún láṣẹ láti fún àwọn ẹ̀dá mìíràn gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ, ewéko, ẹranko, igi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní orúkọ tí wọn yóò máa jẹ. Orúkọ tó fún wọn ni wọ́n sì ń jẹ́ di òní. Àṣẹ kan náà ni Ọlọ́run fún gbogbo ẹ̀dá láti fún àwọn ǹnkan wọ̀nyìí ní orúkọ ní èdè tí wọ́n ń sọ. Nítorí náà, orúkọ ṣe pàtàkì ni Ọlọ́run ṣe fún ẹ̀dá alààyè kìn- ín- ní ní orúkọ tí Ó sì fú un láṣẹ láti fún àwọn ẹ̀dá ìyókù ní orúkọ tí wọn yóò máa jẹ́.
Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé o orúkọ á máa ro ènìyàn. Bí orúkọ ọmọ bá ti rí ni yóò ṣe máa huwà; nítorí náà ni wọ́ ṣe máa ń fara balẹ wo orúkọ tí wọn yóò sọ ọmọ. Yorùbá á tún máa pa òwe kan pé, ‘orúkọ ọmọ ni ìjánu ọmọ’. Ìgbàgbọ́ wa tí ó tún hàn nínú òwe yìí ni pé irú orúkọ tí á bá fún ọmọ kó ipa pàtàkì nítorí a kì í fẹ́ ba orúkọ ara ẹni tàbí ẹbí ẹni jẹ́ àfi àwọn ènìyàn lásán ni kì í bìkítà fún orúkọ rere wọn tàbí orúkọ ẹbí wọn. Nítorí ìfẹ́ àti fi orúkọ ẹni sí ipò iyì àti ẹ̀yẹ ni àwọn Yorùbá fi fi orúkọ wé ìjanu. Ọmọlúàbì yóò máa rántí àwọn ènìyàn rere tó ti jẹ́ orúkọ rẹ̀ síwájú, yóò sì máa gbìyànjú láti máa hùwà rere kí ó má baà ba orúkọ náà jẹ́.
.

Bí a bá ṣe àkíyèsí ìtàn ilẹ̀ Yorùbá lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, a ó rí i pé àwọn kan ti ba orúkọ wọn jẹ́ nípa ìwà búburú tí wọ́n ti hù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló yí orúkọ wọn po nígbà tí orúkọ bẹ́ẹ̀ bá orúkọ àwọn ọlọ́ṣà, adigun- jalẹ̀ mu. Wọ́n yí orúkọ wọn po kí àwọn ènìyàn má baà máa rò pé ìbátan àwọn ọlọ́ṣà náà ni wọ́n. Nítorí náà, àwọn Yorùbá a máa dáàbò bo orúkọ rere wọn gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣọ́ra láti máa hùwà rere. Bí a bá rí ọmọ tó ń hùwà ìpáǹle nínú ẹbí, àwọn mọ̀lẹ́bí á máa kìlọ̀ fún un kí ó má ba orúkọ ẹbí wọn jẹ́. Ìwà rere, orúkọ rere ṣe pàtàkì fún àwọn Yorùbá nítorí náà ni wọ́n ṣe máa ń sọ pé orúkọ rere sàn ju wúrà àti fàdákà lọ. Dájúdájú wúrà àti fàdákà dára púpọ̀, wọ́n sì níye lórí gan- an. Ṣùgbọ́n bí orúkọ rere bá sàn jù wọ́n lọ, dájúdájú àwọn Yorùbá ka orúkọ rere sí nǹkan iyebíye tí a kò lè fi owó rà rárá. Ìgbàgbọ́ yìí ni ó ń mú wọn kó ara wọn níjàánu láti hùwà tí kò dára. Kíkó ara ẹni níjàánu láti tún orúkọ ẹni ṣe ló ń mú wọn máa pa á lówe pé ‘orúkọ ọmọ ni ìjánu ọmọ’. Bí a bá tún yẹ àwọn òwe àti àṣàyàn ọ̀rọ̀ mìíràn wò, a ó rí irú ìgbàgbọ́ yìí kan náà.

- Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá Titun

No comments:

Post a Comment