ÀGBÀ BÍ ỌMỌDÉ
- Ayọ̀ọlá ọmọ Fádèyí
Àgbà bí ọmọdé
Bí ẹ rí ẹni tó fi ọ̀pá tẹlẹ̀
Tó sọ̀rọ̀ òmùgọ̀
Ọmọdé ni
Àgbà kìí sọ̀rọ̀ òmùgọ̀
Bí ẹwá rí abirun funfun lórí
T’ó ń fi ewú orí ṣe bí ajunilọ
T’ó ń fi ẹsẹ janlẹ̀ kiri l’àdúgbò
Òmọdé ni
Pẹ̀lẹ́ sùúrù l’àgbà fì ń lò
.
Omọdé bí àgbà
Bí ẹrí ènìyaǹ tó sọ̀rọ̀ àtàtà lẹ́nu
Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n, oní làákàyè
Bóṣe ọmọdé lójú yín
Àgbà ni
Bí ẹ rí abirun dúdú lórí
Tó sọ̀rọ̀ àtàtà
Àgbà ni
.
Òótọ́ ni
Ohun àgbà rí ní ìkàlẹ̀
B’ọ́mọdé ga ọrùn oní- pẹ̀tẹ́ẹ̀sì
Kò tó bẹ́ẹ̀, kí ó ri i
Àgbà ọjọ́ orí wà
Àgbà oní làákàyè ń bẹ
.
Ṣ’ẹ ri àwọn àgbà ọlọ́jọ́ orí
Àwọn ni wọ́n ń mu ẹmu tàkìtì kiri ìlú
Àwọn ni kò lè to ilé wọn gún régé
Àgbèrè ò fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kan
Gbogbo iṣẹ́ ibi, ọwọ́ wọn ló kun mọ
Bí a bá dà’gbà, à á yé ogun jà
Kọ́ ni ti wọn
Wọ́n á so àgbàdo mọ́ ìdí, adìẹ á sì máa lé wọn kiri
.
‘Wán tú tírí kọ́ lafi ń mọ àgbà
Ó lè ṣe pàtàkì níhà ibìkan
Kìí ṣe gbogbo ibi
Bí ọmọdé ọlọ́jọ́ orí bá fẹ́ dàgbà onílàákàyè
Ó tọ́, kí ó bọ̀wọ̀ fún àgbà ọlọ́jọ́ orí
Ó tọ́, kí ó bọ̀wọ̀ fún àgbà onílàákàyè
.
Wọ́n á pé àádọ́rin ọdún
Wọ́n á tún máa lé ọmọọmọ wọn kiri ní àdúgbò
Fún fífẹ́ kọ, àgbèrè pọ́nbélé ni
Wọ́n á ní ọmo àti aya nílé
Ìyà á jẹ ìyàwó àti ọmọ
Owó kọ́ ló tán nílé
Tàbí iṣẹ́ ló ṣàfẹ́kù
Ọtí àti burańdí ló ń dárà
Ọtí ti pọ̀jù ọ̀kà wọn lọ
Ohun ni aṣọ fi ń pọ́n mọ́ wọn lára
.
Ẹ̀yin àgbà, ẹ ṣe bí àgbà
Ẹ hùwà àgbà
Kí ẹ lè ba kó àwọn ọmọ yín jẹ̀ pẹ́pẹ́pẹ́
Ẹnu àgbà ni obì ń gbó sí
Kí àwọn ọmọdé, má ba tètè mọ iyì yín
.
Tani kò fẹ́ d’àgbà tòótó?
Tani kò fẹ́ d’àgbà oní làákàyè?
Àgbà tí ó mọ ojúṣẹ
Kí n má dàgbà ìranù, àgbà ìyà
Kí n má dàgbà òṣì, àgbà bí ọmọdé
Mo ṣe ìbà àgbà
Mo júbà àgbà
.
-------------------------------------------------
No comments:
Post a Comment