GOMINA FAYOSE SORO
Looto opo awon eniyan ni oro oselu ko ye beeni die ni tun ni o ye ninu awon oloselu gan to si je pe ariwo to nlo ninu oselu ni opo nwo ti won ko wo ilana oselu.
Akoko lati se ilu ko rorun koda lati igba lailai ti awon Oba ndari ile Yoruba ni nitori ori tuntun ati ori gbigbe soro ko jo po, opo igba ni ote mo ndide ninu ilu kan ati orilede kan nigba atijo sugbon ti oro ba di ka da abo bo ile Yoruba won mo ngbe ote si egbe kan ki alafia ba le wa ati ilosiwaju.
Se a gbagbe ote Afonja Ilorin se osé pupo fun ile Odua ki awon Yoruba to ko ara jo si Ibadan ti won si tun ilu na te lati jagun ki awon Fulani Ilorin mo so Iran Yoruba di eru pelu yiyan Oluyole ni Basorun si Ibadan ti won si segun Fulani ni ogun Osogbo lehinna ni Ibadan di oluilu gbogbo omo Odua ti ilekun ilu na si si sile fun enikeni lati gbe ibe tabi lati joye nibe laifi ti eya kan se nile Odua.
Gegebi oselu oni òpè ni opo awon ara ilu ati awon to ntele oloselu to si je pe a ki wo iru adamo ti Aseda da mo eniyan kan ati ona to gba di osupa larin awon irawo.
Mo ti gbo itan Herbert Makoli ri pelu Adegoke Adelabu beeni itan Obafemi Awolowo kiise alo lodo mi ka to wa so Akintola baba logbomoso itan Ladimi Aribi Adedibu Ibadan si nho yaya nile pelu itu meje to pa lagbo oselu to si di araba nile Ibadan ati ile Yoruba koda kosi ibi ti won ko ti gbo oruko Adedibu loride Naijiria.
Diedie ni ipo nla kan Bola Hamed Tinubu to si di olokiki kari agbaye pelu nile Yoruba kosi Gomina egbe re kan to je tabi to fe je ti ko je pe o gba odo Tinubu koja ri yala o ba sise leko tabi ki won jo ni ajosepo to dan moran, ta ba wo lehin to kuro ni Gomina Eko ko du ipo kankan o duro lati da abo Ilu Eko lehin ti eyi bo si o pinu lati wa ja fun Ile Yoruba lehin ti Aseda fun setan o fi ogbon inu di afobaje leyi to gbe Are Buhari de ipo Are Tinubu kò ko joye oun lo si fa Osibajo kale fun igbakeji Are.
Sugbon Opeteke ndagba inu adámò nbaje ni oro Tinubu loju awon eniyan kan laikiyesi pe ibi ti opo ti se asise ni Tinubu tunse nitori opo o mo le ipo kiri laiwo ipo ti awon wa gan, sugbon lojiji lagbo pe awon kan nbu enu abuku ba Tinubu lati apa oke oya leyi to mu inu bi Gomina Fayose Ekiti soro pe "asiwaju Yoruba ni Tinubu eni ba fi abuku kan ti fi abuku kan Yoruba" oro yi je iyalenu si awon eniyan nitori won mo bi Fayose se mo ntako Are Buhari ati egbe APC sugbon ti opo eniyan ti gbagbe pe Fayose ko bu agba kan tabi Asiwaju kan nile Yoruba nitori omo eni o ni se idi bebere ka fi ileke sidi omo elomiran.
Awon oloselu mo ara won won si mo agbelewon ara won Gomina Fayose mo pe Asiwaju Yoruba ni Tinubu meji re kosi si ninu egbe APC to ndari orilede wa lati wa so di igba iwiyo je ona lati ko omo Yoruba more.
Oro oselu gba ogbon gidi bi ilosiwaju yio se ba ile wa lo se pataki sebi awa na ri awon ipo nla ti awon omo Yoruba dimo ninu ijoba, ariwo awon oloselu ori èro (phone) ni won ti npari e ati Gomina Fayose ni ati Bola Tinubu ka gba pe asoju Yoruba ni won ka fi owo sowopo fun ilosiwaju ile Yoruba lo je ohun pataki ka ba le ri itan rere kosile fun awon omo wa lehinwa ola ki awon Iran ti nbo si le ri itan gidi ka.
(Ilosiwaju ilè Yoruba dun ju òtè lo)
- Láti ẹgbẹ́ ÌTÀN YORÙBA lori facebook.com
Ẹ kàn sí wọn lóri WhatsApp: 08023687432
No comments:
Post a Comment