22.10.16

ÌTÀN

OYÈ ÌBÀDÀN

(Inu osu keta odun yi mo koko ko itan yi jade sori Facebook, atunka niyi, oni ni eyin eniyan mi a gba fonran mp3 re lori WhatsApp)
Lehin iku Olubadan ti ilè Ibadan Oba Odugade Samuel Odulana gbogbo aye gba pe Balogun Saliu Adetunji ni Olubadan kan nitori igun Otun ni Oba Odulana to gbese, igun meji pere lo nje Oba Ibadan iyen igun Balogun ati igun Bale (Otun).
.

Ohun ti awon alaimotan nwi nipe, Seriki kan ko je Oba Ibadan ri nitori lasiko Ogun tabi aye atijo ara igun Balogun na ni Seriki wa, Ona meji la le gba tunmo Oye Seriki si ikini Olori odo tabi Olori Èsó iyen eni ti ko dagba sugbon to je akoni ti awon odo si po lehin re.
Eni akoko to koko je Seriki ni Toki Onibudo to nse oga Ibikunle Oloke oju ogun ni Seriki Toki Onibudo ku si lehin iku re ni Ibikunle Olori eso re je Seriki Ibadan keji to si ba oye na de ori Balogun Ibadan ko to ku koda ko ba je Are Ona Kakanfo nitori Balogun Ibikunle lo ko Ijaiye Kurunmi amo o ku lehin ojo mokanla pere to pada wo Ibadan lehin Ogun Ijaiye ati Ègbá to ja fun odun mefa iku Balogun Ibikunle lo fun Ogunmola to nse otun Balogun ni anfani ati je Basorun dipo Kakanfo to ye ko je.
.



Awon oye miran wa ni Ibadan bi Sarumi to je Olori agesin jagun to si je pe ohun lo gbodo mo seto bi awon to ngun esin logun yio se ja ajase, Ogunrenu sini Sarumi akoko pelu Areagoro na je oye pataki ni Ibadan to powole le Agbakin ati Seriki, Delesolu Oje sini Areagoro akoko.
Awon eto yi bere nigba aye Iba Oluyole ti a le pe ni Bale Ibadan keta nitori kosi eto oye nigba aye Bale Moye to nse Bale Ibadan akoko lehin ti won fi ogun gba Ibadan lasiko Oluyedun omo Are Afonja to nse Bale Ibadan keji oye Kakanfo baba re lo je eto oye Kakanfo ni won to.
Ipo kerin ni Seriki Toki Onibudo wa ninu eto, ki o ba le yanju nto si isale fun yin nitori emi ki sègbè.
.

Iba Oluyole (alato ilana oye ti Ibadan nlo)
1. Balogun - Oderinlo
2. Otun Balogun - Lajumoke
3. Osi Balogun - Opeagbe
4. Seriki - Toki Onibudo
5. Asipa - Babalola
6. Abese - Oyesile
7. Sarumi - Ogunrenu
8. Agbakin - Yerombi
9. Areagoro - Delesolu.
.

Ti a ba wo eto oye yi dada ao ri pe oye ogun ni gbogbo Oloye mesan yi to fi mo Oluyole to je olori ilu gan nitori Iba ti a tun npe ni Basorun ni olori ogun Oyo Alafin, Oluyole nikan sini o je oye yi si ehin odi Oyo (ti Basorun Ogunmola ni sugbon ninu nitori Basorun Gbenla si wa ni Oyo nigbati o je) pelu ilana yi ipo kerin ni Seriki wa to tunmosi pe oun ni Osi Balogun kan lehin Opeagbe ti Asipa yio si di Seriki.
Bi mo se so Ibikunle ni Seriki Ibadan keji a ko si ri akosile pe o je oye meta ni Ibadan koja oye Seriki ati Balogun leyi to je pe lehin ti Iba Oluyole ku ti Olugbode ti oye re ga ju je Bale Ibikunle di Balogun Ibadan ti Ogunmola ti ko je oye pataki kan ri si di Otun Balogun, Lasiko Bale Olugbode Ajayi Jegede ni Seriki Ibadan.
A o ri pe ara eto oye kan ni Balogun ati Seriki wa to mo awon Oloye to ku nitori awon ipo oye igbana a sun de ori Balogun ni kiise ilana oye meji bi ti oni.
.

ETO OYE LAYE BASORUN OGUNMOLA
Ogunmola ti ori Otun Balogun di Olori Ibadan o si je Basorun si Ìbàdàn, Akere si je Balogun ti Tunbosun si ti ori oye Osi Bale di Otun Balogun, Ajobo ni Seriki nigbana ti oye Akoko Latoosa si je Otun Seriki, Tahajo si lo je Sarumi.
Kosi iyemeji pe igun meji ko le je Bale Ibadan nigba na lo je ki Tunbosun Osi Bale je Otun Balogun.
O saba mo nje pe ti Bale kan yio ba fi je ni Ibadan lasiko na opo awon Oloye igba Bale isaju a ti ku tan tabi ka ti fi Oloye miran je sugbon to ba je pe lasiko ti ogun nlo ni tabi ki Oloye ku si oju ogun o di igba ti won ba pada de Ibadan leyi ti si mo nje ki alafo bi meta si merin si sile nikehin ti agbega nla a si ba elomiran iru eyi to ba Ogunmola to koko je Oye Otun Balogun laije oye ri tele to si papa wa je Basorun eyi tumosi pe oye meji pere lo je nigba aye re.
.

ETO OYE LAYE BALE OROWUSI
Lehin ti Basorun Ogunmola gbese (ku) Orowusi di Bale Ìbàdàn, Seriki Ajobo di Balogun lati ori oye Seriki leyi to tumosi pe oye marun lo fo ti Latoosa otun Seriki si di Otun Balogun besini Ajayi Ogboriefon ti ko je oye pataki ri si di Osi Balogun, Lawoyin ni Seriki Ibadan igbana.
Se awa na ri bi Seriki Ibadan se ri nigba awon baba nla wa leyi to je pe opo awon Balogun lo ti je Seriki tabi otun Seriki ri nitori oye ogun ni ipo kerin ni Seriki wa lasiko Iba Oluyole ti won bere eto ati ilana oye Ibadan.
.

AARE ONA KAKANFO LATOOSA
Oye akoko Latoosa ni Otun Seriki ti Ajobo si je Seriki nigbati Ajobo di Balogun Otun Seriki Latoosa na gba igbega di Otun Balogun lati ori oye Otun Balogun lo si ti je Are Ona Kakanfo ile Yoruba, awon Bale lo mo nje Kakanfo sugbon lehin ti won ba je won ki pe won ni Bale mo bikose Are Ona Kakanfo.
.

LEHIN IKU KAKANFO LATOOSA
Ni ago ogun Ibadan ni Kiriji ni Are Latoosa ku si Oloye to powole le nigbana ni Seriki Ajayi Osungbekun laisi alatako o gba akoso ogun Ibadan ati olori pelu ti gbogbo awon akoni to ku si ngbo oro si lenu amo niwon igba to je pe oju ogun ni won wa ni Ikirun ko le je Bale a fi ti won ba pada si Ibadan, amo iwadi je ka mo pe o le je Bale ko si pada si Ibadan sugbon won ko lati sebe nitori lasiko ti Are Latoosa yio ku Seriki Ayayi Osungbekun nikan ni Oloye nitori gbogbo awon Oloye ti ku tan ti Are Latoosa kosi fi elomiran je.
Won si panupo fi Seriki Osungbekun je Balogun ko ba le mu oju to ogun pelu adehun pe to ba pada de ile ni yio wa je Bale ti Akintola omo Balogun Ibikunle yio si je Balogun.
.

Idi Oro niyi nigbati otun Seriki Oyediji to ye ko je Seriki gbe enu Gomina Ajimobi sohun, loju opo awon eniyan won ri Otun Seriki bi eni to fe da eto oye Oba Ibadan ru sugbon pelu awon iranti ati Itan yi ipile yio ye gbogbo wa, pelu idajo ti wa si aye ri nigbati Seriki Adisa ti Aliwo ni Agodi Gate gbe oro lo ile ejo ti ile ejo si gbe idajo kale lehin opo iwadi ati Itan to ro mo, Seriki Adisa ko ja fun ara re nikan nigbana bikose gbogbo Seriki ti won fi eto won dun won.
Nitori idi eyi Seriki Ibadan leto a ti di Balogun lehin ti Balogun, Otun Balogun, Osi Balogun ko ba si laye mo gegebi ilana ipile ati Idajo besini Otun Seriki le di Balogun tabi Otun Balogun.
O je ohun ti ko dara lati mo fi Otun Seriki Oyediji je Seriki lehin ti Seriki ti ku, ti awon Oloye igun Balogun ati Otun Bale si sun ara won soke.
.

Iru ohun ti won se fun Otun Seriki yi ti sele ri ti won ngbe opo oye fo Ayejenku koda ati Basorun Ogunmola ati Are Latoosa ba ni ilu Ìbàdàn ni.
Ka mo ri Otun Seriki Ibadan bi eni fe da ilu ru ara arun Ibadan ni "A ki waye ka mo ni arun kan lara, Ijagboro larun Ìbàdàn" Itan ni Gomina Ajimobi i ba lo bere saaju ko to soro nitori eyin lohun, sibe mo ro Otun Seriki pe pele lako pele labo, ilu Ibadan ko ni baje o.
(Nje o ti gbo eyi ri bi)

- Ìtàn Yorùba: Whatsapp - 08023687432

No comments:

Post a Comment