5.11.16

ÀṢÀ

ÌSỌMỌLÓRUKỌ

APÁ KEJÌ: ÈTÒ ÌSỌMỌLÓRÚKỌ

Kí ó tó di ọjọ́ ìsọmọlórúkọ, oríṣiríṣi orúkọ ni a máa ń pe ọmọ titun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Àwọn mìíràn a máa pè é ní àlejò nítorí pé wọ́n kà á sí àlejò tó wá bá ni; ṣùgbọ́n wọn kò kà á sí àlejò tí yóò tún padà, bí kò ṣe èyí tí yóò máa bá ni gbé lọ títí. Àwọn mìíràn a máa pè é ní ìkókó, túnfúlù tàbí aròbó. Àwọn ẹ̀yàYorùba mìíràn ní orúkọ tí wọ́n ń pe ọmọ titun tí kò tíì ní orúkọ ní ẹ̀ka- èdè ti wọn.
.

Ní ìbẹrẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ọjọ́ mẹ́fà ni à ń sọ ọmọ lórúkọ ìbáà jẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin. Ṣùgbọ́n àwọn ìran tàbí ìdílé pàtàkì pàtàkì pàápàá ní ààrin ẹ̀yà Yorùbá Ọ̀yọ́ ní ètò ìsọmọlórúkọ tó yàtọ̀ sí ọjọ́ mẹ́fà. Ní ìdílé Olú- òjé, Onígbẹ̀ẹ́tì, Olókùn- Ẹṣin, Arẹ̀sà, Oníkòyí àti Olúgbọ́n, ọjọ́ keje ni à ń sọ ọmọbìnrin lórúkọ. Ọjọ́ kẹsàn án ni ti ọkùnrin. Bí a bá bí ìbejì ní ìdílé wọ̀nyìí, tí àwọn méjéèjì sì jẹ́ obìnrin, ọjọ́ keje la ó sọ wọ́n lórúkọ. Ṣùgbọ́n tí àwọn méjéèjì bá jẹ́ ọkùnrin, ọjọ́ mẹ́sàn án ni a ó sọ wọ́n lórúkọ. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjéèjì bá jẹ́ ọkùnrin tí èkejì sì jẹ́ obìnrin, ọjọ́ kẹjọ ni a ó sọ wọ́n lórúkọ ní ìdílé náà.
.

Ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ní ìdílé Ọlọ́fà tún yàtọ̀. Ní ìdílé Ọlọ́fà, ọjọ́ méje ni à ń sọ ọmọkùnrin lọ́rúkọ. Ọjọ́ karùn ún ni ti obìnrin. Ọjọ́ kẹfà ni ti àwọn ìbejì tí ọ̀kan jẹ́ ọkùnrin tí èkejì jẹ́ obìnrin. Ṣùgbọ́n tí àwọn ìbejì náà bá jẹ́ ọkùnrin, ọjọ́ keje la ó sọ wọ́n lórúkọ. Bí wọ́n bá jẹ́ obìnrin, ọjọ́ karùn ún ni. Ní ìdílé Aláàfin, ọjọ́ kẹfà ni à ń sọ ọmọ lórúkọ.
.

Láyé òde òní, ìyípadà ti dé bá ọjọ́ ìsọmọlórúkọ. Kí gbogbo rẹ̀ lè dọ́gba, ọjọ́ kẹjọ ni à ń sọ ọmọ lórúkọ ní ibi púpọ̀ ilẹ̀ Yorùbá. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ló ní orò- ilé tí obìnrin tó bí ọmọ gbọ́dọ̀ ṣe láti ọjọ́ tí ó bá ti bímọ títí di ọjọ́ ìsọmọlórúkọ. Orò kan wọ́pọ̀ ní ibi púpọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá. Èyí ni ‘kíkó- ọmọ- jáde’ ní ọjọ́ ìsọmọlórúkọ.
.

Inú ìyàrá ni ìyá ìkókó gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú ìkókó náà láti ọjọ́ tí ó bá ti bímọ títí di ọjọ́ ìkomọjáde.Ibẹ̀ ni wọn yóò maá dàná fún un yá. Ìgbà tó bá fẹ́ yàgbẹ́, ìgbà tó bá fẹ́ tọ̀ tàbí ìgbà tí ó bá fẹ́ mọ́ra ni yóò maá jáde sí gbangba. Ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ni a ó tó gbé ọmọ náà jáde láti inu ìyàrá bí ó bá jẹ́ ọ̀kan. Bí ó bá jẹ́ ìbejì, ọjọ́ náà la ó tó kó wọn sí gbangba òde. Ìdí nìyǐ tí a fi ń pe ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ní ọjọ́ ìkómọjáde.
.

Ní ọjọ́ ìkomọjáde, àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ yóò péjọ síwájú ilé níbi tí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò máa ń dà sílẹ̀ láti orí òrùlé. Wọn yóò gbẹ́ ihò kéékèèkéé méjì síwájú ilé náà. Ìyá ìkókó náà yóò wọṣọ tó dára nítorí ọjọ́ ayọ̀ ni ọjọ́ náà fún un. Nígbà tí ìyá ìyá ìkókó báti jókòó níwájú ilé tán, àgbà obìnrin kan yóò wọlé lọ gbé ọmọ náà jáde láti inú ìyàrá. Ìyá rẹ̀ yóò gbà á. Wọn yóò máa da omi tútù sórí òrùlé bí ìyá ìkókó ṣe ń gbé omọ rẹ̀ bọ̀. Ẹ̀kán omi tútù yóò kán sára ìkókó. Ọmọ náà yóò ké nítorí omi náà ṣàjejì lára rẹ̀. Inú àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ tó péjọ yóò dùn fún igbe ayọ̀ tí ọmọ náà ké. Igbe náà sì tún fi hàn pé ara ọmọ náà dápé. Nígbà mìíràn, ẹ̀ẹ̀méje ni wọn yóò fi ara ọmọ náà gbe ẹ̀kán omi náà bí wọn ti ń gbé e wọlé, tí wọ́n ń gbé e jáde, bí ó bá jẹ́ obìnrin. Bí ó bá jẹ́ ọkùnrin, ẹ̀ẹ̀mẹsàn án ni. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ ìbejì, ẹ̀ẹ̀mẹ́jọ ni.
.

Bí a bá yẹ àṣà yìí wò, ó fi ara jọ ìṣamì àwọn ẹlẹ́sìn Krístì. Ó sì tún jẹ́ pé àwọn baba- ńlá wa ní ìmọ̀ ẹ̀sìn Krístì kí wọ́n tó wá tẹ̀dó sí Ilẹ̀- Ifẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣáá, ìdí tí a fi ń ṣe àṣà yìí ni láti jẹ́ kí ara ìkókó náà mọ omi tútù nítorí ìgbà tí ìyá rẹ̀ yóò máa gbé e kiri. Láti ọjọ́ ìkómọjáde náà ni ìyá rẹ̀ yóò ti máa gbé e káàkiri bí ó bá ti fẹ́.


- Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá Titun

No comments:

Post a Comment