
A dá búlọ́ọ̀gù yii sílẹ̀ látara ìpè níja tí a rí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì bí kò ṣe si ẹyọ̀kan tí ó bójú tó èdè Yorùbá. Bẹ́ẹ̀ gbogbo ọmọ Kóòtû- ò-jíire ló mọ̀ pé ọrọ Yorùbá duǹ mọ̀rànyìn- mọranyin. Ní orí búlọ́ọ̀gù yìí, a o màa fi ìròyìn lẹ́kùn rẹ́rẹ́ tọ́ yín létí, òwe lọ́kan ò jọ̀kan ò ní gbẹ́yìn, àlọ́ àpamọ̀ àti àpagbè la ó máa fi dá ara wa lárará. Ẹ máa mìlíkì
19.1.17
Ọfọ̀ Ẹ̀yọ́nú
Bépo bá ń lérí sọná
Ijó ni iná fi i jó
Bí àdí bá ń lérí sí òòrùn
Ayọ̀ ni òòrùn fi ń yọ
A kì í gba igbó lọ́wọ́ onígbó
A kì í gba ọ̀dàn lọ́wọ́ ọlọ́dàn
Ẹja ńlá ní í fòkun ṣelé
Ọ̀nì gìdìgbà níí fọ̀ṣà sàrípọ̀nlọ
Ẹ yọ́nú sí mi
Kí wọ́n má lè ṣí mi nípò
Kí wọn yọ́nú sí mí o
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment