14.3.17

ÌṢERÉ

ÌTÀKÙRỌ̀SỌ LÁÀRÍN- ÍN ÈMI ÀTI ÌYÁ ONÍWÓRÓBO

Ayọ̀ọlá: Ẹ káalẹ́ o
Ìyá Alájé: Ooo
.
Ayọ̀ọlá: Kínni ẹ ni ní títà tí mo lè fi mu gàrí
Ìyá Alájé: Ẹ̀wà ló wà
.
Ayọ̀ọlá: Lẹ́yìn ẹ̀wà, kínni ẹ tún ní
Ìyá Alájé: Kòsí
.
Ayọ̀ọlá: Ó da, ṣé ẹní bàbá dúdú
Ìyá Alájé: Kòsí
.
Ayọ̀ọlá: Tí ó bá jẹ́ bẹ̀, ẹ ta ẹ̀wà múrí kan àbọ̀ wá
Ìyá Alájé: Ṣé ìyẹn kìí ṣe ‘sixty nairà’ bí
.
Ayọ̀ọlá: Rárá o, ‘thirty nairà’ ni mo sọ; múrí kan jẹ́ ‘twenty nairà, àbọ̀ rẹ̀ jẹ ‘ten nairà’, tí a bá ṣí i pọ̀ yóò fún wa ní , ‘thirty nairà’ , múrí mẹ́ta á sì jẹ ‘sixty naira’. Ṣé ó yé?
Ìyá Alájé: Bẹ́ẹ̀ni, ó yé, ẹ ṣeun gan- an fún àlàyé yín
.
Ayọ̀ọlá: Ọlọ́hun ló ni í
Ìyá Alájé: Ṣùgbọ́ ṣá o, kòsí ẹ̀wà múrí kan àbọ̀. Ati ‘fifty nairà’ ni ẹ̀wà ti bẹ̀rẹ̀, ṣíbí kan sì ni
.
Ayọ̀ọlá: Á jẹ́ pé owó yín ti dé nì yẹn
Ìyá Alájé: Àmín ooo
.
Ayọ̀ọlá: Ǹ jẹ́ ẹ ní ṣúgà
Ìyá Alájé: O wá, èló lẹ fẹ́
.
Ayọ̀ọlá: Ẹ mú oní múrí kan wá. Ǹ jẹ́ ẹ ní ẹ̀pà náà
Ìyá Alájé: Bẹ́ẹ̀ni, ó wà
.
Ayọ̀ọlá: Tí ó bá jẹ́ bẹ̀, ẹ mú ẹ̀pà àti ṣúgà, múrí kàn-àn kàn wá
(Bí mo ṣe gba ṣúgà àti ẹ̀pà lọ́wọ́ Ìyá Aláje rè é, tí mo sì fùn- un ni ogójì náìrà/ múrí méjì)



No comments:

Post a Comment