23.3.19

EWÌ - ÌDÁRÒ

Adébọ́lá Pius Adésànmí
(1972 - 2019)
- Ayọ̀ọlá ọmọ Fádèyí

Erin wó, gbogbo inú igbó pa kése
Àjànàkú lọlẹ̀ wì, ọba ọ̀dàn ṣòjòjò
Yemọja kú, ẹja kẹ́ja ò jẹ́ wẹ̀ nínú ibú
Olóòlà òǹkọ̀wé re àjà, òjé ìkọ̀wé gbẹ fírí
Wọ́n ni, kínni ìṣẹ́ tí àwọn tún gbà mọ́
Lẹ́yìn ikú olùbádámọ̀ràn àwọn
Ó ṣe, ikú o ṣèyí tán!
.
Ẹni bá mọ ikú
Kó bá mi béèrè lọ́wọ́ ikú oun mo ṣe fún - un
Ẹni bá mọ Àsàráílù
Kó bá mi béèrè lọwọ Àsàráílù oun mo fi ṣé
Tó fi mú Adébọ́lá Àkànjí mi lọ
A báni dámọ̀ràn bí ìyekàn ẹni
Baba Tise, olówó orí Olúmúyìwáá
.
Lọ́jọ́ kan àná lo gbé ikú jẹ; o gbé ikú mì
Lọ́nà Ògbómọ̀ṣọ́ sí Ọ̀yọ́
O ti àwọn ọ̀tá rẹ l'ójú
O fi omi ata bọ̀wọ́n lójú
Ikú ṣe wa padà mú ọ láìròtẹ́lẹ̀?
Ìrìnàjò láti Addis Ababa sí Nairobi
Ni àrìn-kẹ́yìn rẹ, àpérò Ilẹ̀ Áfíríkà lò ń lọ
Iṣẹ́ rẹ lò ń ṣe rìnrìn àjò lọ́jọ́ burúkú yìí
Ọjọ́ burúkú, ọjọ́ eṣu gbomimu
Ọjọ́ burúkú, ọjọ́ ògún fẹ̀jẹ̀wẹ̀
Ọjọ́ kẹwàá oṣù Ẹrẹ́nà ọdún 2019
L'ọkọ̀ bàlúù tí o wọ̀ já pàù nínú afẹ́fẹ́ lókè lọ́hùn-ún
Ẹ́tà dín l'ọ́jọ èèyàn ló ṣòfò ẹ̀mí l'ọ́jọ́ ẹlẹ́kọ ọ̀run ń polówó
Kò sí eegun, kò sí èérún, ọmọ èèyàn pòórá mọ́lẹ̀
Ẹkùn, ìróra, ìkẹ́dùn gba ayé kan, nǹkan ṣe!
.
Ṣé wọ́n ní ikú dóró?
Èmi ò mọ̀ pé ikú á máa dá oró lóòótọ́
Béèyàn kú àfi kí n kíi pé ó dìgbà ó ṣe
Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gba pe ikú ń dóró láì wẹ̀yìn wò
Ṣé ẹni ikú pa kọ́ ló d'óró fún
Àwọn èèyàn t'ókùú fi sílẹ̀ lọ nikú nà l'ẹ́gba ìpayínkeke
Ikú dá oro yìí náà
Ó wọ́mi déegun, ó wọ̀ ṣìnkun akínyẹmí ará mi lógán
Ikú gbé òrònròó òun yèrèpè wọ agbárí mi lọ
Gán-na-gàn-na l'ó kù tí n ò ṣe
A ṣé báyìí nikú burú tó
Ògidì ọmọ Adésànmí lọ
.
A-dú máa dán, ọrẹ ìmùlẹ̀ lórí Òpópónà 'Facebook'
A fi ọ̀yàyà ṣòrọ̀, kí ọ̀ràn má bàa dunni
A fẹ̀sọ̀ dá ìjọba l'ẹ́kun ìwà ìbàjẹ́
A perí olóṣèlú kilọ̀ fún jẹgúdújẹrá wọn
Á dá wọn lọ́wọ́ kọ́ gẹ́gẹ́ bí ọba sí ará ìlú
Adébọ́lá ọmọ Adésànmí a-gùn-taṣọ̀ọ̀-lọ̀
Ojú rekete, ọkùnrin fàkàfíkí
Ògbójú ọdẹ nínú igbó ìmọ̀
Ó fi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fọ́kọ́ mú fún onílé
Ó fi ọgbọ́n àgbà pògì mú fún àlejò
Ṣẹnu róbótó pilẹ̀ ọ̀rọ̀ ìwúrí
Bàbá afinú-ṣọgbọ́n rèwàlẹ̀ àsà
.
Gbogbo àwọn tí o fi ìmọ̀ rẹ jínkìn-ín l'Áfíríkà ń ṣe lé dè lẹ́yìn rẹ
Gbogbo àgbààgbà Ilẹ̀ Yorùbá ní kí n máa kì ọ
Gbogbo Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ilẹ̀ Kú-òórọ̀-oòjííre ni wọ́n ni kín n kí ọ
Gbogbo ọba ládéládé Ilẹ̀ Odùduwà ní wọn ránmi sí ọ
Ṣe tí onírèsé ò bá fíngbá mọ́,
Èyí tó fín sílẹ̀ ò le parẹ́
Wọ́n ní ń fi dá ọ lójú pé
Iṣẹ́, ìṣe àti ọ̀nà rẹ kò ní di àwátì
Gbogbo rẹ ni àwọn yóò fọ́nká sí ibikíbi nílé ayé
Tí ìrandíran ọmọ adáríhunrun yóò ma jẹ àǹfààní rẹ̀
To- lórí tẹlẹ́mù tọ̀kọ̀tùlùú ló pàwọ̀dà di dúdú fún ọ
.
Mọ̀mọ́ Bámidélé aya Ọlátẹ́jú, Bàbá Abímbọ́là Olújídé
Ẹ kú ọ̀rọ̀ ìmùlẹ̀ yín tó di olóògbé
Ìyáàfin Olúmúyìwáá Mama Tise, Ìyá Àgbà Mama Adébọ́lá
Ẹ kú àmúmọ́ra tí ọkọ àti ọmọ yín
Igi tó dá kìí pẹ́ nígbó
Akọ igi kìí ṣe òjé
Ẹ kú ọ̀rọ̀ ènìyàn
Elédùmarè nìkan ṣo ló lè tù yín nínú
Ẹ kú ilé dè
.
Tò, Elédùmarè, Ọba Ọ̀gá ògo
Mo tẹ́wọ́ mi méjèèjì sí ọ
Mo bẹ̀ ọ́ kí o foríji ẹni wà tó lọ
Kí o pa àṣìṣe rẹ̀ rẹ́
Kí o gbà á sí àárín àwọn èèyàn réré l'ọ́run
Kí o sì fi ikú wèrewère mọ lórí èyí
Kí ó má ṣé ní sísẹ̀ntẹ̀lẹ̀
Ẹ̀yin ẹ̀ ń báni dáró
Ikú Ọ̀jọ̀gbọ́n Adébọ́lá Pius Adésànmí kìí ṣe t'ọ̀fọ̀
Ká kú ní kékeré ṣ'àgbà ká dàgbà di ẹni yẹ̀yẹ́
.
Tí kìí bá ṣe t'ikú
Ọmọ Adésànmí ì bá fi gbòǹgbò jọ Baba Wọlé Ṣóyínká
Ìjọba Nàìjíríà, ẹ wá ohun kan gbòógì fi sọri ọmọ Adésànmí
Torí orúkọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ọmọ Alfred Adésànmí ti tàn ká
Níti dáadáa pẹlu ìṣe ọpọlọ tó múyán lórí tó gbé ṣe
Ẹ̀yin ọ̀jẹ̀lu Nàìjíríà, ẹ fi ìhùwàsí Adébọ́lá ṣe àkọ̀mọ̀nà
Adébọ́lá Pius Adésànmí gbé lé ayé ṣe rere
T'ẹ̀gàn lókù
.


#OroYoruba
©2019

No comments:

Post a Comment