3.3.19

ÀRÒKỌ

OLÓWÓ-ÌBÍNÚ ÀTI ÌYÀWÓ-O RẸ̀ ÌDÀÀMÚ-AYÉ

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi Olùkọ́ Èdè Yorùbá,

Mo kí-i yín pẹ̀lẹ́ ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi àtàtá . Ẹ kú-u bí ojú ọjọ́ ti rí. Ṣé àwọn ènìyàn-àn mi wà ní àlàáfíà? Ìyàwó àti àwọn ọmọ nkọ́? Ṣe ẹ-ẹ̀ jà si ò-o.

Mo rántí wí pé mo ṣe ìlérí kan fún-un yín láìpẹ́ ọjọ́. Àbúrò-ò mi Yínká Adébóyè kò tilẹ̀ jẹ́ kí nfi ẹ̀dọ̀ lórí òróṅro nítorí ìlérí náà. Yínká tilẹ̀ sọ fún mi wí pé ọjọ́ tí mo bá ti mú ìlérí-ì mi ṣẹ òun yóò ra ògidì ẹmu fún mi. Òun yóò se ọbẹ̀ tí ó jọjú kí njẹ-ẹ́ pẹ̀lú ẹran ìgalà àti iyán tí ó gbámúṣé; odidi ọ̀yà kan lòun yóò sì gbé fún mi relé lẹ́hìn tí mo bà gbádùn ara-à mi tán. Ènìyàn iyì ni àbúrò-ò mi Yínká; nítorí náà, bí mo fẹ́ bí mo kọ̀ mo ní láti sọ ìtàn tí mo ṣèlérí-i rẹ̀ fún-un yín.

Ìtàn kan ni ó jẹ sí mi lọ́kàn lónìí yìí. Bàbá-à mi ni ό sì fi ìtàn náà tó mi létí kí n tó ní ìyàwó. Mo sì mọ̀ wí pé tí mo bá sọ ìtàn náà fún-un yín kò burú, bí a bá sì jọ gbádùn-un rẹ̀ kò léèwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó le-è mú mi bí mo bá fi lu ìlù ògìdìgbó, tí ọlọ́gbọ́n bá bá mi jό-o tí ọ̀mọ̀ran sì bá mi mọ̀n-ọ́n.

Bàbá-à mi ti kìlọ̀ fún mi wí pé ó yẹ ki nsọ́ra kí n tó ní ìyàwó, kí n sì kún fún àdúrà kí n tό lóbìnrin. Ó wí fún mi pé nṅkan ńlá ni ìgbéyàwó, ayẹyẹ ńlá sì ni ọjọ́ ìgbéyàwó pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní-í gbé ìyàwó níjọ́ tí olόde ńgbòde; wọ́n á gbé ìyàwó nínú ibú ìbìnújẹ́, wọ́n á fi Sàtánì ṣe ìmùlẹ̀, Bìlísì yóò bá wọn kẹ́sọ̀-ọ́ ròde, Wàhálà yóò sì jẹ́ ojúlówó èníyàn níjọ́ àjọyọ̀-ọ wọn.

Bí bàbá-à mi sì ṣe sọ ìtàn yìí fún mi ni ń ò ṣe sọ́ fún-un yín lónìí yìí ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi. Ẹ jẹ́ ki nsọ ìtàn náà fún-un yín; kí njù-ú sí i yín bí àkàṣu èdè àti ọ̀rọ̀. Kí a sì jọ gbádùn ara wa bí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ tó rí ṅkan ayọ̀ yọ̀ sí. N όò jόkòό sí ipò-o bàbá-à mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi náà yόò sì jόkòό sí ipò mi bí mo bá ṣe ńsọ ìtàn náà fún fún-un yín. Kí èmi àti ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi sì gbàdùn ìtàn náà bí Ìbàdàn ṣe ńgbádùn ọkà àti ọ́ọ́yọ́ tòun ti gbẹ̀gìrì. Kí ìtàn náà wọ inú–un wa lọ, kí ó wọ inú ẹ̀jẹ̀-ẹ wa lọ kό ṣe wá ní àṅfàní; kí a sì jọ kọ́ ẹ̀kọ́ ti yóò ṣe ọmọ aráyé lόore.

Ẹ bá mi kálọ ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi.

Ọkùnrin olόwό kan-án wà ní ayé àtijọ́ tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Olόwό-Ìbínú. Bàbá tí ó sì bí-i ni Ìfòyà tí-í ṣe ọkọ Ìfẹ́dàrú ọmọ ilé Àìbalẹ̀-Ọkàn níbi tí Inúnibíni ti-í ṣe Mọ́gàjí-i wọn. Olόwό Ìbínú ló ní owó jùlọ jàkéjádò ìlú-u wọn ní àtijọ́. Tọmọdé tàgbà ló sì mọ̀ wí pé ní àgbàlá Olόwό-Ìbínú ni igi owó ti ńso.

Oníṣòwò tí ó dáńgájá ni Olόwό-Ìbínú, ohun tí ó sì ń fi inú–un rẹ̀ rò ní ọ̀sán àti òru kò ju owό lọ. Owό ni èrò ọkàn Olόwό-Ìbínú ní ìgbà gbogbo, owó sì ni ό fẹ́ràn júlọ ní òde ayé. Olόwό-Ìbínú fẹ́ràn owó ju ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ. Olόwό-Ìbínú kì-í ṣe ohunkόhun láì ronú owó. Ní ìgbà tí ó sì tó fún-un láti ní obìnrin torí owó ló ṣe fẹ́ ìyàwó-o rẹ̀. Orúkọ ìyàwó-o rẹ̀ ni Ìdààmú-Ayé. Ìdààmú-Ayé sí ni àrẹ̀mọbìnrin Olόyè Ògbójú, Mọ́gàjí Ilé-Ìkà ní Ìlú Ìbàjẹ̀-Ènìyàn. Olόwό-Ìbínú fẹ́ obìnrin yìí nítorí ό rò wí pé tí àwọn àna òun bá kú, owó-o wọn yόò di ti òun ni.

Ẹni líle ni Olόyè Ògbójú, Ọkùnrin náà sì gbóná ju àpáàrà lọ. Olόyè Ògbójú kò náání ẹnikẹ́ni lόde ayé, ό sì burú tό bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò sí ẹni tí ό ńsọ̀rọ̀ Ọkùnrin náà dára nílé lόko. Olόyè Ògbójú ti wό ilé aláìsàn rí nítorí onitọ̀un jẹ-ẹ́ ní kọ́bọ̀. Ò ti gba ibùsùn lọ́wọ́ aboyún rí nítorí ẹ̀kọ sísì; ό sì ti lu ọmọ òkú ọ̀run ní kùmọ̀ lόrí rí nítorí-i kúlíkúlí-i ṣílè kan. Ìtàn pàápàá sì sọ wí pé ní ìgbà tí Olόyè Ògbójú má-a fẹ́ ìyàwó-o rẹ̀, Ilé Alájẹjù lọ́dọ̀ Balόgun Ojúkòkòrò ọkọ Gbèsè lόti lọ m’obìnrin. Akọ́bi ilé náà tí ńjẹ́ Àdánwò ló sì fẹ́. Ó fi tìpá tìkúùkù gbé ọmọ náà láì san owó ori-i rẹ̀ ni. Ó ní awọn òbì-i rẹ̀ gba oko lọ́wọ́ òun ní pọ́ùn kan, wọn kò sì tí-ì sanwό oko tán. Ní ìgbà tí yόò sì ṣírò èlé orí oko, èlé owó tό ní kí wọ́n san ju àpò mẹ́fa lọ.

Ṣé ajá tí yόò sọnú kì-í gbọ́ fèèrè ọdẹ. Gbogbo ènìyàn ni ό gba Olόwό-Ìbínú ní imọ̀ràn kí ό máṣe fẹ́ Ìdààmú-Ayé ṣùgbọ́n ό kọ̀ jalẹ̀. Olόwό-Ìbínú ní Ìdààmú-Ayé nìkan lό wu òun lóbìnrin. Tí àwọn bá si fẹ́ ara wọn kò léèwọ̀; owó wọn yόò má-a ṣubú lόrí owó, ọlá lόrí ọlá, ìgbéga wọn yόò sì má-a wà lόrí ìgbéga. O si da oun loju wí pé ni igba ti Olόyè Ògbójú bá pa ipò dà, gbogbo owó-o rẹ̀ yόò di ti Ìdààmú-Ayé. Níwọ̀n tí òun sì jẹ́ ọkọ Ìdààmú-Ayé, owó náà yόò di ti òun.

Olόwό-Ìbínú àti Ìdààmú-Ayé ṣe ìgbéyàwό, ọjọ́ ìgbéyàwό-o wọn lárinrin púpọ̀, ayé gbọ́, ọ̀run sì mọ̀ pẹ̀lú wí pé àwọn gbajúmọ̀ méjì-í fẹ́ ara wọn. Ṣùgbọ́n àtẹ̀yìnwò ìgbéyàwó wọn kò ṣẹnure. Nítorí Ibú Ìbànújẹ́ ni wọ́n ti ṣe ìgbéyàwό, Ọ̀run Àpáàdì sì ni ìwé ẹ̀rì-i wọn-ọ́n ti jáde. Sàtánì ló jόkόό bí alága ìgbéyàwό, Bìlísì-í sì jόkòό sí ibi ẹ̀yẹ. Gbogbo eku-ú jẹjẹ jẹ wọ́n yó; àwọn ẹyẹ jẹ èso títì wọ́n fi orí sọgi. Elégbèdè mọtí yό ό lu igi mẹ̀fa ya, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀lírí ńgbádùn ayé-e rẹ̀ lẹ́bà-á àsun fún odidi oṣù mẹ́jọ láì fara pa.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹni jàṅkàn jàṅkàn ló wá sí àṣeyẹ yìí; àwọn ẹ̀mí ọ̀run olόkìkí sì wá pẹ̀lú. Àwọn gbajúmọ̀ tό wá ńkíra kú àtijọ́. Àwọn mẹ̀kúnù jόkòό sí àyé wọn pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ láì b’Ólúwa wíjọ́. Àwọn ọ̀tọ̀kùlú sì ńṣe fàájì bí agbára-a wọ́n ti mọ. Ikú wá, òun àti ìyàwó-o rẹ̀ Àrùn. Àìní wá ṣùgbọ́n ìyàwó-o rẹ̀ Àkísà kò le-è wá nítorí Òṣì ọ̀rẹ́-ẹ rẹ̀ ńṣe ọjọ́ ìbí. Òun àti èkejì-i rẹ̀ Àbùkù lọ jόkòό sí ìta níbi tí wọn ti le-è tètè rí ońjẹ jẹ. Èṣù-ú pàápàá wà, Ẹlẹ́gbára náà sì wá pẹ̀lú. Ìrẹ̀lẹ̀-ẹ́ wá ati ọ̀rẹ́-ẹ rẹ̀ Ṣebíotimọ ṣùgbọ́n ariwo Ìgbéraga àti ìbátan rẹ̀ Àṣejù ti pọ̀ jù nítorí náà wọn kò pẹ́ púpọ̀ kí wọ́n tό-ό lọ; wọ́n lọ bá ọ̀re-ẹ́ wọn Ayọ̀ àti Inú-dídùn níbi ti wọ́n ti ńta ayò ní ìgboro.

Ìnákúnàá ni alásè, bẹ́ẹ̀ ni àbúrò-o rẹ̀ Àwìn lό wà ní ìdí ọtí. Ọ̀gbẹ́ni Ẹ̀tàn ni ό ńdárin, Èké ló ńlu ìyá ìlú, Irọ́ sì ni ό ńlu omele. Ìranú ati Àìnírònú ńfi ọwọ́ kọ́ ara lọ́rùn nìbi tí Òfò ti ńṣe sisí, tí Àìbìkítà sí ńṣe ojúlόwό Ọkùnrin. Àwọn ará ilé Ọ̀tẹ̀ mú ìjόkòό ńlá, Olόyè Àbòsí sì jόkòό ní agbo ènìyàn pàtàkì pẹ̀lú ọ̀rẹ́-ẹ rẹ̀ Àgàbàgebè. Olùyà pọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́, Ẹni-Ìyà sì pọ̀ láàárín ìbátan. Àìrόjú lό mú ìyàwó wọlé, Imẹ́lẹ́ ló fà-á lé ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ níbi tí Òfófó àti Owú ti jẹ́ Olόyè láàárín àwọn obìnrin, tí Ìnira sì jẹ́ ẹni iyì láàárín àwọn Ọkùnrin.

Àwọn ẹni ńlá tí ó wá sí ìgbéyàwό yìí gbadun ara wọn pupọ̀. Oríṣiríṣi ẹ̀bùn ni wọ́n sì fi ta tọkọtaya yìí lọ́rẹ. Ẹní mú owó wá mú owó wá, èyìí tí ó fún wọn láṣọ-ọ́ fún wọn láṣọ. Tánńganran kúnlé gbári, ohun ọ̀sọ́ kò sì lóhùnkà. Ibi tí wọ́n sì kó ẹ̀bùn sí tóbi ju Gbọ̀ngàn-ìṣeré-òmìnira ti ìlú Ìbàdàn lọ. Ṣùgbọ́n ní gbogbo àwọn ẹ̀bùn tí àwọn tọkọtaya yìí gbà lọ́wọ́ àwọn tí ó yẹ́ wọn sí, kò sí èyí tí ó dára tó ibùsùn idẹ tí Bìlísì fi ta wọ́n lọ́rẹ. Ibùsùn yìí kò ní àfiwé; gbogbo ọ̀pá ibùsùn yìí la fi gόòlù ṣe ọnà sí lára. Omi díámọ́ṅdì la fi kọ orúkọ tọkọtaya sí ìgbèrí ibùsùn náà. Tìmùtìmù ìrọ̀rí-i rẹ̀-ẹ́ jẹ́ ti ẹ̀gbọ̀n òwú olόwó iyebíye; bẹ́ẹ̀ ni itẹ́lẹ̀-ẹ rẹ̀ dàbí àrán ọba pàtàkì. Ibùsùn náà dára ό wu ni jọjọ.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi tòótọ́, ẹ jẹ́ kí á sinmi ìtan dídùn yìí fún òní. Tí ó bá di ọ̀la, n ó-ò parí ìtàn náà fún-un yín

Ó dàáro ná. Kí Olúwa jí wa’re

Ire òó

Diípọ Fágúnwà

No comments:

Post a Comment