24.3.19

ÌTUMỌ̀- Ọ̀RỌ̀ ÌṢÍNI-LÉTÍ

L'àbáwọlé fáfitì kan ní Orílẹ̀-èdè South Africa, àwọn ọ̀rọ̀ ìṣínilétí wọ̀nyìí ni wọ́n kọ sóde fún àròjinlẹ̀:

"Pípa Orílẹ̀-Èdè k'Órílẹ̀-Èdè run kò gba lílo àdó olóró tàbí àwọn ohun-èlò ìjà olóró alárìnjìnà. Ohun kan péré tó gbà ni dídẹwọ́ lórí ìkúnjú-òsùnwọ̀n ètò-ẹ̀kọ́ àti gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láyè láti máa gbéégún nínú ìdánwò."

Àwọn aláìsàn á máa kú lọ́wọ́ irú àwọn dókítà bẹ́ẹ̀.

Ilé yóò dà wó lọ́wọ́ àwọn onímọ̀-ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀.

Owó yóò di àwátì lọ́wọ́ àwọn onímọ̀- owó àti ọrọ-ajé bẹ́ẹ̀.

Ìjẹ́-ọmọ-ènìyàn yóò kú lọ́wọ́ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀.

Ìdájọ́-òdodo yóò dàwátì lọ́wọ́ àwọn agbẹjọ́ro àti adájọ́ bẹ́ẹ̀...

Ètò ìṣèlú yóò dojú rú lọ́wọ́ irú àwọn aṣòfin bẹ́ẹ̀.

*"Ìfórísánpọ́n ètò- ẹ̀kọ́ ni ìfórísánpọ́n orílẹ̀-èdè."*

Ìtumọ̀ sí èdè Yorùbá
Ayọ̀ọlá Fádèyí

No comments:

Post a Comment