14.8.19

BARIKA DE SALLAH- ỌDÚN ILEYA

BARIKA DE SALLAH- ỌDÚN ILEYA 1440AH
- Ayọ̀ọlá ọmọ Fádèyí
.
Ọdún iléyá dé, tolórí tẹlẹ́mù ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀
Ara ọmọdé ò lélẹ̀, tàgbà ò fi jọ omi àmù
Ará ilé ń kí ara oko pé 'A kú ọdún, kú ìyèdún'
Àwọn ẹrúsìn Allah ń kí ara wọn pé 'Barka de Sallah'
Ọjọ́ ọdún iléyá ọjọ́ ẹyẹ
Kò sí ibi ọdún iléyá ò ti gbayì
Ó gbayì ní Amẹ́ríkà dé Italí-Róòmù
Ó gbayì ni Faransé dé Ṣáínà
.
Ọjọ́ tí àwọn Mùsùlùmí òdodo tí òkè Arafah bọ̀
Tí wọ́n ń ké lóhùn rárá tó kún fún ìyìn Ọba Adániwáyé
Ṣèbí Ànábì Ibrahim ni àwọn imale fi ṣe àwòkọ́ṣe
Ẹni tí ó kọ́kọ́ kọ Ilé Ọlọ́run sí Mẹ́kà
Tí ó sì yíká lẹ́ẹ̀méje
Èyí lódi tàwáàfù di òní olónìí
Fún ọjọ́ mẹ́wàá gbáko ni àdúrà tí ń pe àdúrà ránṣẹ́
Ní kàábà, Ilé Olúwa
Káàkiri gbogbo Ilẹ̀ Àgbáńlá Ayé
.
Mẹ́ta lọjọ́ l'ọ́dún iléyá
Ọjọ́ kinnín-ín, kejì kẹta
Iyì ọjọ́ kinnín-ín ju ìkejì
Tọjọ́ kejì ju ti ìkẹta
Bẹ́ẹ̀ lẹran tí a pa lọ́jọ́ kankan níyì ju ara wọn
.
Mẹ́ta lẹran to ni ládá lọ́jọ́ iléyá
Ràkúnmí, àgbò àti màálù
Pàtàki wọn lójú Ẹlẹ́dàá yàtọ̀ sí ara wọn
Nílẹ̀ Nàìjíríà, àgbò ṣàgbà màlúù
Nílẹ̀ Lárúbáwá, ràkúnmí ṣàgbà àgbò
Èyí tí ó bá tọ́ làápa
Kò ṣeèwò tí onígbàgbọ́ bá pa ẹran mẹ́ta lẹ́ẹ̀kàn - an ṣoṣo
Mẹwa, ogún kìí ṣeèwò, bí agbára bá ṣe ká ní
Mélòó lẹ́yìn pa lọ́ọ̀dẹ̀ yín, ẹ jẹ́ á gbọ́?
.
Ọ̀nà mẹ́ta làá pín ẹran ọdún iléyá kánkán sí
Ìkínní jẹ́ ti mọ̀lẹ́bí ẹni
Ìkejì jẹ́ ti abánigbé àti ará àdúgbò
Ìkẹta jẹ́ ti àwọn aláìní tí wọn kò rówó ṣọdún
Bẹ́ẹ̀ èèwọ̀ ni, ẹran iléyá ò gbọdọ̀ pẹ́ nílẹ̀
Kò gbọdọ̀ ju ọjọ́ mẹ́ta lọ nínú ìṣasùn ọbẹ̀
.
Ẹ̀kọ́ tí ọdún Iléyá kọ́ ọmọ adarí hunrun pọ̀ jáǹtìrẹrẹ
Ṣe ẹ rán tí pé àṣẹ tí Elédùà pa Ànábì Ibrahim ló fẹ́ mú ṣẹ
Tí ẹran àgbò fi sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀ rọ́pò Ismaila ọmọ rẹ̀
Bẹ́ẹ̀ l'Ànábì Ibrahim pa ẹran àgbò rọ́pò ọmọ
Títẹ̀lé àṣẹ Ọlọ́run láì wẹ̀yìn wò, láì ṣe ìyè méjì
Ló sọ Ibrahim di bàbá ìgbàgbọ́
.
Elédùmarè Ọba tó bá lórí ohun gbogbo
Ò ní ohun kan ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí a ta sílẹ̀
Bí kò ṣe ìpayà àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí a fi dúnbú ẹran
Ló pàtàkì sí Ọba tó tóbi jù lọ
Ẹ jẹ́ á ṣiyè pé agbára àwọn ẹranko wọ̀nyìí jú tí àwa ọmọ ènìyàn lọ
Ṣùgbọ́n, Elédùmarè rọ̀ wọ́n fún wa
Kí a lè máa fi wọn láta
Èyí ó tò ká yín Ọlọ́run bí?
.
Káfi àgbò kàn, ò tọ súnna
Ẹni bá ń ṣe èyí tàpá sí àṣẹ Allah
Ká fi ọtí òun bíà jẹ́ ẹran iléyá
Iṣẹ́ àṣètáánì ni, ẹ jẹ́ ta késé sí irú ìṣe báyìí
Kí a lè bá jèrè tó pọ̀ lọ́dún òní
Ṣìná, àgbèrè, tẹ́tẹ́ ò tún ṣe é sọ
.
Ejẹ́ á tẹ́wọ́ àdúrà
Ẹ̀yin tẹ́ ẹ ní àwọn Alhaji àti Alhaja ni Mẹ́ka
Láyọ̀láyọ̀ la ó pàdé wọn
Wọ́n ó ní fi òkú wọn ránṣẹ́ sílè
Ọdún ayọ̀ lèyí yóò jẹ́ fún gbogbo wa káàfàtaà
Haji tó pé ó ní ṣe èèwọ̀ ẹnìkànkàn-an wa
Níjọ́ níjọ la ó máa lọ
A ò ní pẹ́dín lọ́dún tóhún bọ̀. Àṣẹ
.
#AyF™
©2019

No comments:

Post a Comment