A dá búlọ́ọ̀gù yii sílẹ̀ látara ìpè níja tí a rí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì bí kò ṣe si ẹyọ̀kan tí ó bójú tó èdè Yorùbá. Bẹ́ẹ̀ gbogbo ọmọ Kóòtû- ò-jíire ló mọ̀ pé ọrọ Yorùbá duǹ mọ̀rànyìn- mọranyin.
Ní orí búlọ́ọ̀gù yìí, a o màa fi ìròyìn lẹ́kùn rẹ́rẹ́ tọ́ yín létí, òwe lọ́kan ò jọ̀kan ò ní gbẹ́yìn, àlọ́ àpamọ̀ àti àpagbè la ó máa fi dá ara wa lárará.
Ẹ máa mìlíkì
12.4.20
ÀWÚRE
Òkú igi kìí rójú p'ewé
Òkú ọ̀pẹ kìí r'ójú ta'gbò mọ́lẹ̀
Ẹnìkan kìí rójú tà'wú aláǹtakùn tó já
Àìrójú àìráyè kìí jẹ́ kí alákẹdun fá' rí
Ká'wọn t'ó gbógun sí mi má rójú ṣojú
Kí wọn má rójú ṣe mí níbi
.
Ọ̀rọ̀Yorùbá
2020
No comments:
Post a Comment