4.11.20

Òwe

Òwe Yorùbá. "Àìsọ̀rọ̀ àìyánrọ̀ ló pa Eléǹpe ìṣáájú tó ní igba wúwo ju àwo lọ" Ọkàn lára ìtàn dòwe ilẹ̀ Yorùbá ni òwe yìí. Àlàyé òwe ọ̀hún rèé. Ìtàn bí Ọba Èléǹpe àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ Ọba àwọn tàpá tí ó sì jẹ́ baba Torosí tí í ṣe ìyá ṣàngó,ọmọ Ọ̀rànmíyàn kìí ṣe ń fẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀ la òun nìyí.Àsọjù ọ̀rọ̀ ló mú u sọ gbólóhùn yìí. Eléǹpe jẹ́ Tàpá nígbà kan. Lákòókò kan tí ó ń ṣe ọdún rẹ̀,ó pe àwọn ìjòyè rẹ̀ jọ,ó fún wọn ní ọtí,òun pàápàá mu ọtí yó,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí àwọn ìjòyè rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ni ó dá wọn lẹ́kun pé kí wọ́n dákẹ́.Ó ní òun pẹ̀lú Àgòrò igbákejì òun ti ń jiyàn sí ọ̀rọ̀ kan tipẹ́.Ó ní òun fẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà parí lónìí.Ó ti ń wọ́nà láti pa Àgòrò tipẹ́ tí kò rí ọ̀nà. Nítorí náà,ó wí pé ẹni tí ó bá pa irọ́ nínú àwọn méjèèjì,yálà Àgòrò tàbí òun,kí wọ́n lu Olúwarẹ̀ pa.Àwọn ìjòyè fọwọ́ sí i,wọ́n sì bí wọn léèrè ohun ti wọ́n ń jiyàn sí.Ọba ní òun wí pé igbá wúwo ju àwo lọ,Àgòrò sì wí pé bẹ́ẹ̀kọ́. Àwọn ìjòyè ìlú kó igbá gbígbẹ àti àwo wá,wọ́n ní kí Ọba gbé wọn wò kí òun pàápàá mọ èyí tí ó wúwo jù nínú wọn.Àsìkò yìí ni Ọba ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ pé òun kò là á délẹ̀ kedere pé igbá tútù ló wúwo ju àwo lọ.Kí ó tó yanu kótó láti pè, àwọn ìjòyè ti lù ú pa. Àwọn pàápàá mọ̀ pé ó fẹ́ pa Àgòrò igbákejì rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni,ló fi wí èyí.Báyìí ni Eléǹpe àkọ́kọ́ bọ́ sínú àwọ̀n tí ó dẹ sílẹ̀ fún ọmọnìkejì rẹ̀ nítorí Àsọ̀rọ̀ àìyánrọ̀ọ rẹ̀. Pàtàkì òwe yìí. À ń pa òwe yìí fún ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n tí kò la ọ̀rọ̀ náà kedere nígbà tí ó yẹ kó làá dáadáa.Òwe ìkóra-ẹni-ní-ìjánu gbáà ni òwe náà. -------------------------------------- Mo kí i yín o.A kú bí ojú ọjọ́ ṣe rí lọ́dọ̀ kówá. Ìwáyẹmí. Atúmọ̀ òwe bí ẹní ń tú aṣọ ìyàwó ẹ̀.

No comments:

Post a Comment