A dá búlọ́ọ̀gù yii sílẹ̀ látara ìpè níja tí a rí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì bí kò ṣe si ẹyọ̀kan tí ó bójú tó èdè Yorùbá. Bẹ́ẹ̀ gbogbo ọmọ Kóòtû- ò-jíire ló mọ̀ pé ọrọ Yorùbá duǹ mọ̀rànyìn- mọranyin. Ní orí búlọ́ọ̀gù yìí, a o màa fi ìròyìn lẹ́kùn rẹ́rẹ́ tọ́ yín létí, òwe lọ́kan ò jọ̀kan ò ní gbẹ́yìn, àlọ́ àpamọ̀ àti àpagbè la ó máa fi dá ara wa lárará. Ẹ máa mìlíkì
3.6.22
EWI- OSELU 2023
BOLA TINUBU
TUWENTI TUWENTI TIRI
- Ayoola omo Fadeyi
.
Ko sewu legberun eko
Asiwaju Eko
Asiwaju Yoruba
Bola omo Tinubu, baba o
Mo si fila fori oselu nla
Ahmed omo Iya-loja
Tinubu baba Iya-loja
.
O n se won bii ko subu
Isubu iya-nla-iya won ni won kuku n wa
O n se won bii ko sise
Sise-sise o si ni si l'eede won
Bi eluulu ba p'ojo, ori ara re lo n roo le
Ina ti a ba daale fun gunnugun, eye miiran laa fi n sun
Ki sise sise maa ba awon to gbogun ti e
Nibikibi ti won ba lugo si
.
Won ti gbagbe ni
Omo olodo ide, feso wo nu
Won n se bi omode
Omode lafun loyin lana
L'o di oni lani ko bunwa ni sibi kan ninu eko owo re
Lo ko jale loni, eyi to wa l'owo oun ko to oun je lodun merin
Kila bere l'owo omo, esi wo lo funni?
Oro re, eyin eeyan
.
E lo fokan bale, ko sewu legberun eko
Eru o gbodo bodo
Eni fe we ninu re, l'eruu ba
Eni bami kukute Tinubu
Ara re lo n mi
E o ni Bola gbese
Yoo si bori gbogbo ogun ikoko ati gbangba
.
Oju yoo ti awon olote
Oju maa n ti ina ale ni
Oju yoo si ti won dojo ale won ni
Ha!
Se boju aye se ri re
Boore bape titi looto,
Asiwere a si gbagbe
Ohun lo mu asiwere won gbagbe
O se!
.
Adaripon pe ako Tinubu po lapoju
Eyi kuukuu agbado re
Pe, boo ni ti omo Tinubu se je' l'aye oun
Awon agbaya, agbaburuku elenu rirun kan
Si n pe, 'bawo ni Tinubu se je ninu oselu Naijiria'
Paga!
Ki keke pa, ko pa mo won lenu
Enu won si gbodo faya de agbari won
.
Oore sise gbodo niwon looto
Odale esi, a maa je ki ore suni se
Won fi oju olore won gungi tan
Won n yan fanda
Won o si ranti ola
Ola a si maa bere lowo eni
Eleda wa pelu re, agba oselu
Ko sewu legberun eko ni twenti twenti tiri
Lase Oba, Adaniwaye
.
©2023
AyF™
21.5.22
ORUKO ERANKO
YORUBA ANIMAL NAME
AGBONRIN = Deer
Agbanrere= Giraffe
Bogije = woodpecker
Erinmilokun = Hippopotamus
Erin = Elephant
Ere = python
Ekun = leopard
Efon = Buffalo
Gunugun = vulture
Ikoko = Hyena
Egbin = Gazelle
Ibaka = canary
Kolokolo = fox
Ketekete~Abila = Zebra
LILI =Hedgehog
Turuku = Warthog
Maalu = cow
Òòrę = porcupine
Ògòngò = Ostrich
Òwìwí = owi
Ràkunmi = camel
Sèbè= Black snake
Tolotolo = Turkey
Tanpepe = black ant
Tanwiji = mosquito larvae
Yanmuyanmu = mosquito
8.5.22
EWI- WON N BA BABA SERE NI
WON N BA BABA SERE NI
- Ayoola omo Fadeyi
.
Won n ba baba sere ni
Ako aja won lo n gbo
Kini won le se, ti baba o le se
Won n ba baba sere ni
.
N o mo, bi ola yoo seri
Sugbon, e je ki baba o de be
Emi o se oselu esin
Bee n o se oselu eleyameye
Sugbon, ika to ba to loye ka fi romu
.
Omo le se bii baba looto
Sebi baba rere ni i fe ki omo re laluyo
Bee ni ti baba yii ri
Sugbon, eyi ti baba nife si nisinsinyin
Ko ba da, ki e gba baba laye
Ki o le se iwon ti o le se
Naijiria, mo gbagbo yoo gbadun re
.
Ire o!
AyF™
©2022
4.11.20
Òwe
Òwe Yorùbá.
"Àìsọ̀rọ̀ àìyánrọ̀ ló pa Eléǹpe ìṣáájú tó ní igba wúwo ju àwo lọ"
Ọkàn lára ìtàn dòwe ilẹ̀ Yorùbá ni òwe yìí.
Àlàyé òwe ọ̀hún rèé.
Ìtàn bí Ọba Èléǹpe àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ Ọba àwọn tàpá tí ó sì jẹ́ baba Torosí tí í ṣe ìyá ṣàngó,ọmọ Ọ̀rànmíyàn kìí ṣe ń fẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀ la òun nìyí.Àsọjù ọ̀rọ̀ ló mú u sọ gbólóhùn yìí.
Eléǹpe jẹ́ Tàpá nígbà kan. Lákòókò kan tí ó ń ṣe ọdún rẹ̀,ó pe àwọn ìjòyè rẹ̀ jọ,ó fún wọn ní ọtí,òun pàápàá mu ọtí yó,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí àwọn ìjòyè rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ni ó dá wọn lẹ́kun pé kí wọ́n dákẹ́.Ó ní òun pẹ̀lú Àgòrò igbákejì òun ti ń jiyàn sí ọ̀rọ̀ kan tipẹ́.Ó ní òun fẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà parí lónìí.Ó ti ń wọ́nà láti pa Àgòrò tipẹ́ tí kò rí ọ̀nà. Nítorí náà,ó wí pé ẹni tí ó bá pa irọ́ nínú àwọn méjèèjì,yálà Àgòrò tàbí òun,kí wọ́n lu Olúwarẹ̀ pa.Àwọn ìjòyè fọwọ́ sí i,wọ́n sì bí wọn léèrè ohun ti wọ́n ń jiyàn sí.Ọba ní òun wí pé igbá wúwo ju àwo lọ,Àgòrò sì wí pé bẹ́ẹ̀kọ́.
Àwọn ìjòyè ìlú kó igbá gbígbẹ àti àwo wá,wọ́n ní kí Ọba gbé wọn wò kí òun pàápàá mọ èyí tí ó wúwo jù nínú wọn.Àsìkò yìí ni Ọba ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ pé òun kò là á délẹ̀ kedere pé igbá tútù ló wúwo ju àwo lọ.Kí ó tó yanu kótó láti pè, àwọn ìjòyè ti lù ú pa. Àwọn pàápàá mọ̀ pé ó fẹ́ pa Àgòrò igbákejì rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni,ló fi wí èyí.Báyìí ni Eléǹpe àkọ́kọ́ bọ́ sínú àwọ̀n tí ó dẹ sílẹ̀ fún ọmọnìkejì rẹ̀ nítorí Àsọ̀rọ̀ àìyánrọ̀ọ rẹ̀.
Pàtàkì òwe yìí.
À ń pa òwe yìí fún ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n tí kò la ọ̀rọ̀ náà kedere nígbà tí ó yẹ kó làá dáadáa.Òwe ìkóra-ẹni-ní-ìjánu gbáà ni òwe náà.
--------------------------------------
Mo kí i yín o.A kú bí ojú ọjọ́ ṣe rí lọ́dọ̀ kówá.
Ìwáyẹmí.
Atúmọ̀ òwe bí ẹní ń tú aṣọ ìyàwó ẹ̀.
12.4.20
ÀWÚRE
Òkú igi kìí rójú p'ewé
Òkú ọ̀pẹ kìí r'ójú ta'gbò mọ́lẹ̀
Ẹnìkan kìí rójú tà'wú aláǹtakùn tó já
Àìrójú àìráyè kìí jẹ́ kí alákẹdun fá' rí
Ká'wọn t'ó gbógun sí mi má rójú ṣojú
Kí wọn má rójú ṣe mí níbi
.
Ọ̀rọ̀Yorùbá
2020
Òkú ọ̀pẹ kìí r'ójú ta'gbò mọ́lẹ̀
Ẹnìkan kìí rójú tà'wú aláǹtakùn tó já
Àìrójú àìráyè kìí jẹ́ kí alákẹdun fá' rí
Ká'wọn t'ó gbógun sí mi má rójú ṣojú
Kí wọn má rójú ṣe mí níbi
.
Ọ̀rọ̀Yorùbá
2020
14.8.19
BARIKA DE SALLAH- ỌDÚN ILEYA
BARIKA DE SALLAH- ỌDÚN ILEYA 1440AH
- Ayọ̀ọlá ọmọ Fádèyí
.
Ọdún iléyá dé, tolórí tẹlẹ́mù ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀
Ara ọmọdé ò lélẹ̀, tàgbà ò fi jọ omi àmù
Ará ilé ń kí ara oko pé 'A kú ọdún, kú ìyèdún'
Àwọn ẹrúsìn Allah ń kí ara wọn pé 'Barka de Sallah'
Ọjọ́ ọdún iléyá ọjọ́ ẹyẹ
Kò sí ibi ọdún iléyá ò ti gbayì
Ó gbayì ní Amẹ́ríkà dé Italí-Róòmù
Ó gbayì ni Faransé dé Ṣáínà
.
Ọjọ́ tí àwọn Mùsùlùmí òdodo tí òkè Arafah bọ̀
Tí wọ́n ń ké lóhùn rárá tó kún fún ìyìn Ọba Adániwáyé
Ṣèbí Ànábì Ibrahim ni àwọn imale fi ṣe àwòkọ́ṣe
Ẹni tí ó kọ́kọ́ kọ Ilé Ọlọ́run sí Mẹ́kà
Tí ó sì yíká lẹ́ẹ̀méje
Èyí lódi tàwáàfù di òní olónìí
Fún ọjọ́ mẹ́wàá gbáko ni àdúrà tí ń pe àdúrà ránṣẹ́
Ní kàábà, Ilé Olúwa
Káàkiri gbogbo Ilẹ̀ Àgbáńlá Ayé
.
Mẹ́ta lọjọ́ l'ọ́dún iléyá
Ọjọ́ kinnín-ín, kejì kẹta
Iyì ọjọ́ kinnín-ín ju ìkejì
Tọjọ́ kejì ju ti ìkẹta
Bẹ́ẹ̀ lẹran tí a pa lọ́jọ́ kankan níyì ju ara wọn
.
Mẹ́ta lẹran to ni ládá lọ́jọ́ iléyá
Ràkúnmí, àgbò àti màálù
Pàtàki wọn lójú Ẹlẹ́dàá yàtọ̀ sí ara wọn
Nílẹ̀ Nàìjíríà, àgbò ṣàgbà màlúù
Nílẹ̀ Lárúbáwá, ràkúnmí ṣàgbà àgbò
Èyí tí ó bá tọ́ làápa
Kò ṣeèwò tí onígbàgbọ́ bá pa ẹran mẹ́ta lẹ́ẹ̀kàn - an ṣoṣo
Mẹwa, ogún kìí ṣeèwò, bí agbára bá ṣe ká ní
Mélòó lẹ́yìn pa lọ́ọ̀dẹ̀ yín, ẹ jẹ́ á gbọ́?
.
Ọ̀nà mẹ́ta làá pín ẹran ọdún iléyá kánkán sí
Ìkínní jẹ́ ti mọ̀lẹ́bí ẹni
Ìkejì jẹ́ ti abánigbé àti ará àdúgbò
Ìkẹta jẹ́ ti àwọn aláìní tí wọn kò rówó ṣọdún
Bẹ́ẹ̀ èèwọ̀ ni, ẹran iléyá ò gbọdọ̀ pẹ́ nílẹ̀
Kò gbọdọ̀ ju ọjọ́ mẹ́ta lọ nínú ìṣasùn ọbẹ̀
.
Ẹ̀kọ́ tí ọdún Iléyá kọ́ ọmọ adarí hunrun pọ̀ jáǹtìrẹrẹ
Ṣe ẹ rán tí pé àṣẹ tí Elédùà pa Ànábì Ibrahim ló fẹ́ mú ṣẹ
Tí ẹran àgbò fi sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀ rọ́pò Ismaila ọmọ rẹ̀
Bẹ́ẹ̀ l'Ànábì Ibrahim pa ẹran àgbò rọ́pò ọmọ
Títẹ̀lé àṣẹ Ọlọ́run láì wẹ̀yìn wò, láì ṣe ìyè méjì
Ló sọ Ibrahim di bàbá ìgbàgbọ́
.
Elédùmarè Ọba tó bá lórí ohun gbogbo
Ò ní ohun kan ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí a ta sílẹ̀
Bí kò ṣe ìpayà àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí a fi dúnbú ẹran
Ló pàtàkì sí Ọba tó tóbi jù lọ
Ẹ jẹ́ á ṣiyè pé agbára àwọn ẹranko wọ̀nyìí jú tí àwa ọmọ ènìyàn lọ
Ṣùgbọ́n, Elédùmarè rọ̀ wọ́n fún wa
Kí a lè máa fi wọn láta
Èyí ó tò ká yín Ọlọ́run bí?
.
Káfi àgbò kàn, ò tọ súnna
Ẹni bá ń ṣe èyí tàpá sí àṣẹ Allah
Ká fi ọtí òun bíà jẹ́ ẹran iléyá
Iṣẹ́ àṣètáánì ni, ẹ jẹ́ ta késé sí irú ìṣe báyìí
Kí a lè bá jèrè tó pọ̀ lọ́dún òní
Ṣìná, àgbèrè, tẹ́tẹ́ ò tún ṣe é sọ
.
Ejẹ́ á tẹ́wọ́ àdúrà
Ẹ̀yin tẹ́ ẹ ní àwọn Alhaji àti Alhaja ni Mẹ́ka
Láyọ̀láyọ̀ la ó pàdé wọn
Wọ́n ó ní fi òkú wọn ránṣẹ́ sílè
Ọdún ayọ̀ lèyí yóò jẹ́ fún gbogbo wa káàfàtaà
Haji tó pé ó ní ṣe èèwọ̀ ẹnìkànkàn-an wa
Níjọ́ níjọ la ó máa lọ
A ò ní pẹ́dín lọ́dún tóhún bọ̀. Àṣẹ
.
#AyF™
©2019

24.3.19
ÌTUMỌ̀- Ọ̀RỌ̀ ÌṢÍNI-LÉTÍ
L'àbáwọlé fáfitì kan ní Orílẹ̀-èdè South Africa, àwọn ọ̀rọ̀ ìṣínilétí wọ̀nyìí ni wọ́n kọ sóde fún àròjinlẹ̀:
"Pípa Orílẹ̀-Èdè k'Órílẹ̀-Èdè run kò gba lílo àdó olóró tàbí àwọn ohun-èlò ìjà olóró alárìnjìnà. Ohun kan péré tó gbà ni dídẹwọ́ lórí ìkúnjú-òsùnwọ̀n ètò-ẹ̀kọ́ àti gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láyè láti máa gbéégún nínú ìdánwò."
Àwọn aláìsàn á máa kú lọ́wọ́ irú àwọn dókítà bẹ́ẹ̀.
Ilé yóò dà wó lọ́wọ́ àwọn onímọ̀-ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀.
Owó yóò di àwátì lọ́wọ́ àwọn onímọ̀- owó àti ọrọ-ajé bẹ́ẹ̀.
Ìjẹ́-ọmọ-ènìyàn yóò kú lọ́wọ́ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀.
Ìdájọ́-òdodo yóò dàwátì lọ́wọ́ àwọn agbẹjọ́ro àti adájọ́ bẹ́ẹ̀...
Ètò ìṣèlú yóò dojú rú lọ́wọ́ irú àwọn aṣòfin bẹ́ẹ̀.
*"Ìfórísánpọ́n ètò- ẹ̀kọ́ ni ìfórísánpọ́n orílẹ̀-èdè."*
Ìtumọ̀ sí èdè Yorùbá
Ayọ̀ọlá Fádèyí

Subscribe to:
Posts (Atom)