29.11.16

ÀṢÀ

ASA IKINI NI ILE YORUBA: KIKI NI ILE YORUBA


Ikini tabi kiki ni ni ile Yoruba je ohun pataki ninu asa ile Yoruba. Awon Yoruba ko gba omo won laaye lati hu iwa omugo Kankan. Awon Baba wa bo, won ni “bi a ba bi omo ni ile ogbon, o gbodo moiran wo”. Omo ti o ba ji loowuro lodo agabalagba ti ko si mo ohun ti o lati se yoo gba abuku. Sugbon omo ti o ji ti o ti ki gbogbo ara ile, ti o ki baba, ti o ki iya, eleyi ti kogo ja gege bi omo Yoruba gidi. Asa ikini je asa ti awon Yoruba fi nko ara won ti ko si se gba lowo eni ti a ba fi asa naa to dagba.
.
Bi a ba se akiyesi iran Hausa daradara, nse ni won ma n wole ki baba tabi iya won. Bi a ba si wo bi iran Ibo ti n ki baba tabi iya won, nse ni won ma ate ori ba laasan bi o se okunrin tabi obinrin won. Sugbon bi a ba wo iran omo Yoruba lookunrin nibi ti o ti n ki bab, iya tabi agbalagba, pelu idobale gbooro ni. Nwon a na ese, nwon a si faya bale, nwon a si ni “e kaaro oo”. Baba tabi iya naa yoo dahun pe “Pele o, Aremu omo Akin, o kaaro, o o jire bi?” Omokunrin ko ni kuro lori idobale titi baba tabi iya re yoo fi dake. Asa yi ti mora to be ti a fi npe awon omo Yoruba ni “Omo e kaaro, e o jii re?”
.
Bi o tise Pataki fun omokunrin lati ki baba tabi iya re loowuro naa lo je dandan fun omobinrin lati ki baba tabi iya loowuro bi won ba ji. Idobale ni ti omokunrin sugbon ori ikunle laa mba omobinrin. Omobinrin a kunle, a si wipe baba tabi iya, e ku aaro o. Baba tabi iya yoo dahun pe, “Apeke mi, omo Ekun to fin toritori, se daradara lo ji o?” Omobinrin gbodo duro soori ikunle naa tit obi re yoo fi pari kiki re.
.

Owuro nikan ko la nki eniyan ni ile Yoruba. Bi a ti n ki ara wa ku aaro, e ji re, bee laa nki ara w ape, ‘E ku osan’, ni deede agogo mejila si meji osan; ‘E ku irole ni deede agogo merin si mefa’; ‘E ku ale ni deede agogo meje ale si monkanla’.Ohun kan ti o se Pataki ninu asa ikini Yoruba ni wipe, bi o se aaro, osan, irole ati ale ni, pelu idobale fun omokunrin ati ikunle fun omobinrin la n ki awon to ba ju ni lo. Yato fun ikunle, eyi ti o wopo laarin awon omobinrin, awon kan tun wa ninu awon Yoruba t ii fi ori bale bi nwon ba nki ni. Asa iforibale tabi kaa fori ba iganna tabi igi nigba ti oju ba nkan ni yi wopo pupo laarin awon Ekiti.
.

Awon oyo lo ni ikunle, Ekiti lo ni iforibale. Sugbon bayi, asa iforibale yi ti n kasenile, gbogbo awon omobinrin ile Yoruba ni o maa nkunle ki awon asaaju won. Awon Yoruba tun ki ara won nigba tin won ba fe lo sun ni ale. Akoko yi ni a ma ngbo pe ‘O daaro o, ki Olorun ji wa re o, kaa ma toju orun doju iku o, tabi laayo la o ji o’.
.

Awon ikini Pataki miran tun wa fun igba otooto, yala ninu odun tabi fun isele ayo ati ti ibanuje. Ni igba eerun a ma nso pe, ‘e ku eerun yi, eku ogbele yi e ku ooru yi’. Ni igba ojo a maa nki nip e ‘e ku ojo yi, ku oginnitin yi tabi e ku otutu yi’.Bi o ba je akoko ti onje won ni a maa nki eniyan pe, e ku iyan, e ku aheje tabi e ku owon onje yi. Bi o ba si je akoko ti onje po ni a maa nki nip e, ‘e ku opo onje, e kun mudun-mudun, e ku imuje, e ku iwasaya’. Awon Musulumi ti n gbawe la nki pe e ku ongbe, e ku ise laada.
.

Orisirisi ona lo wa ti a ngba ki awon eniya ni ile Yoruba. Sugbon ma menu ba die ninu re.

A. Aboyun ile laa nki pe:
E ku idura.
Isokale anfani.
Afon a gbo ko to wo o.
A o gbo ohun iya, a o gbo tomo o.
Tibi tire le o bi o.
Abiwere o.
Eku o ni gbo, eye o ni mo o.

B. Bi aboyun ba sese bimo re, a o ki pe:
Barika, e ku ewu omo.
Omo tuntun, o ku atorunbo.
Mo yo fun yin o.
Oluwa yoo da omo si, Oluwa yoo wo.
Eku owo lomi.
Yoo loowo rere lehin.
Yoo se omo kale.
Oluwa a somo ni bantale.
Eku owo losun o.

D. Eni ori ko yo ninu ewu la nki pe:
Barika, e ku orire.
E ku ewu.
E ku inu ire.
Bi o ba ku, ki Olorun yo ni.

E. Bi omo-owo tabi omode ba jalaisi, a o ki awon obi re pe:
E pele.
E ku amu-mora naa.
Omi lo danu.
Oluwa o nijagbe o fo
Oluwa yoo pese bantale.
Oluwa yoo pese ti elemi gigun.
Oluwa yoo se dada miran.
Olorun a so ibanuje dayo fun yin.

E. Bi odomode ba ku ninu ewu moto, iji, efuufu tabi ti ina, a o ki awon obi tabi ara re bayi pe:
E pele o, e ku ara fera ku.
E ku ajalu.
E ku iroju.
E ku ofo.
E ku afimora naa.
Olorun yoo fi mo bayi.
Olorun yoo ti ilekun ibanuje.
Olorun o ni je ka ri iru eyi mo.
Ojo a jina si ara won.
Emi a jina semi o.

F. Bi enikan ba wa ninu ejo tabi aisan, a o ma kii pe:
E ku wahala.
E ku rigboriye.
Ori a ko o yo.
Inu rere a ko o yo.
Edumare a da o lare.

G. Bi enikan ba padanu ohun ini re sinu ewu ina tabi effufu, a o ma kii pe:
E pele o.
E ku ofo.
E ku adanu.
Ki Oluwa fofo ra emi.
Olorun ko ni je ka riru re mo.
Olorun yoo fi mo be.

GB. Bi baba tabi iya to lojo lori ba ku, a o ma ki awon omo re pe:
E ku aseyinde
E ku inawo.
E ku idele.
Eyin baba tabi iya a dara.
Olorun a basiri o.
Baba tabi Iya a fohun rere paroko.
Baba tabi Iya a moore.

I. Eni to sese kole tan to nsi i la n kip e:
E ku inawo ile yi.
Emi a lo o.
Oluwa ko ni se e ni akota.
Tire tomo ni o lo ile yi.
Ile a tura o.
E o ko eyi to ju yi lo o.

Bi a ti nki awon eniyan si ohun to sele naa la nki won si ohun ti won nse lowo. Ma menu ba die ninu orisirisi ona ti a ngba ki eni to n sise lowo.
A. Awon Agbe la ma n ki pe: Aroko boodun de tabi owo a ya o.

B. Awon Akope tabi Agunpe la ma nki pe: Igba a ro o tabi Emo o

D. Awon Atuko tabi Awako la ma nki pe: Oko a refo o.

E. Awon Alaro la ma nki pe: Aredu o, Areye o tabi Amugbe, ti won a si dahun pe Olokun a gbe o.

E. Awon Onidiri la ma nki pe: Oju gbooro, ti won a si dahun pe Ooya o, Iya moja a gbe o.

F. Awon Babalawo la manki pe: Aboru-boye o, ti won a si dahun pe Aboru-boye bo sise, Ifa a gbe o.

G. Awon Ode la ma nki pe: Arepa ogun, ti won a si dahun pe Arepa ntogu.

GB. Awon Alagbede la ma nki pe: Aroye o tabi Owu a ro o, ti won a si dahun pe Ogun a gbe o.

Iteriba ati iyesi ti awon Yoruba ni ni won fi ma n ki oba ati oloye, die ninu ba ti n ki wo niwonyi:

A ma n ki oba pe:
Kabiyesi, alase ekeji orisa.
Kia de pe lori.
Ki bat ape lese.
E o je ju ara iwaju o.
Awon Oloye la nki pe:
Ebo a fin o
Eru a da
Baba re a gbe e o.
E ku eto ilu.

Ori awon oba ati oloye ma n ya bi a ba nki won bayi, nitoripe a fi han pe a mo riri ipo won. Bi a ba farabale wo daadaa, a o ri wipe kikini lede Yoruba ko lopin be si ni idahun wok o si lonka. Asa yi ti wa di ajebi, ko si ohun ti o le gba a sonu lowo wa, bi o tile je wipe opo omo bibi ile Yoruba lo ti n te asa na mere sugbon “igbo kii di ka a ma mo Iroko, oja kii di ka a ma mo afin.” Bi o ti wu ki oju la to, a ko ni saimo omo Yoruba tooto lawujo nibi won gbe nki ni.

14.11.16

ÌWÚRE


IWURE OWURO
_____________________maawii te lemii
Eledumare ibaa ree loni oo akoda aye ibaa
Aseda orun ibaa
Ojumo iree lonii ooo
A o nii jade leku lowoo
Ayee mii o nii bajee
Ise mii o nii dii isee
Oriimii o nii buru
Orii mii o nii gbabodee
Orii mii o nii daru
Oriimii o nii see ofoo
Orii mii o nii bamija
Iku o nii kanmii
Jijadee mii lonii mi o nii ko agbako
Won o nii fii aso damiimo
Ogun o nii gba eje mii
Wahala o nii bamii
Aje o nii saa funmii
Alaanu o nii wonmii
Mi o nii fii osii loo igbaa
Isee onii bamii mulee
Mii o nii se ofoo omo
Mii o nii rii iku oko
Mii o nii see ofoo aya
Mii o nii kan idaamu
Oran o nii lumii
Mii o nii rogun ejoo
Mii o nii fii ewon loogba
Ayee o nii fimii pamo
Ile o nii lemii
Onaa o nii namii
Mii o nii rin arin fii ese siii
Ijanbaa o nii semii
Mii o nii dii enii akoleboo
Iku onii kanmii bayii
Idawole mii yii o yorii sii rere
Okan mii yii o baale
Ekun o nii kanmii
Won o nii bamii se ofoo
Lase edumare

LONI OJO AJE
ATEMI ATI EYIN A O RI TI AJE SE LONI

OOtunba Peter Oladele Fatomilola




ÌWÉ ÌTUNMỌ̀

Ẹ̀yà ARA


Ìgẹ̀: Muscular Chest

Ẹsẹ̀: Leg

Ojú: Eyes

Imú: Nose

Ẹnu: Mouth

Ìgùnpá: Arm

Apá/ Ọwọ: Hand

Ìgùnpá: Arm

Èékánná ọwọ́: Fingernail

Èékánná ẹsẹ̀: Toe nail

Ẹ̀dọ̀: Kidney

Ẹ̀dọ̀fóró: Liver

Ọ̀wọ̀rọ́kù: Intestine

Òróǹró: Bile

Káà Ọ̀nàfun: Oesophagus

11.11.16

ÌTÀN

LAAYE IGBA-N-NNI, LOJO-OJO'UN ANA!


BAYI NI BI ORIN JUJU SE BERE ATI AWON TODA SILE
( Apa Keji)

Moki gbogbo eyin ayanfe wa kaabo sori akotun eto wa eto yin LAAYE IGBA-N-NNI
LOJO-OJO'UN ANA, eku amojuba wa fun itesiwaju itan orin juju ta nbaabo lati
ijeejo a o ni deena penu lojo toni, bee si ni ko ni si atunwi asan o, eje ki a bere ni
paapapa o

ORIN IBILE NI IYA F'ORIN JUJU
Bee ni bi opolopo eeyan o se mo pe orin ibile wa loje iya fun orin juju gege bi o
se je fun awon orin yooku, lara orin ibile yi ni won ti yo orin bi apala, senwele waka,
ati beebelo, orin ti a n pe ni orin juju lojo toni, bi awon orin yooku se bere lo'un
naa se bere o, kin ni kan nipe idi emu, idi oguro nibi gbogbo tawon eeyan ti n se
faaji won leyin ise oojo won ni, lagbo faaji nile elemu ni won ti koko awon orin yi, gbogbo
nkan ti mo n so yi o ko i ti i ju odun 1920 lo ti orin naa gbile nilu Eko lo, kin ni kan ti
o daju saka nipe lati odo awon eeyan wa ti won ti rin irn ajo lo sawon ilu okere ni won mu
asa naa bo wa ti won si yi pada sede ti ibile wa.

EYI I NI AWON EEYAN TO SE PATAKI NINU ORIN JUJU


Ni ibere pepe ti ko ti i si orin juju iwonba awon eeyan meta si merin lo saba ma
n korin yii ni ibere pepe, bi won se ma n to ara won nipe eeyan kan yoo maa korin ti
yoo si gbe irinse pataki kan ti o mu orin naa yato si tawon yooku ti won n pe ni Banjo yi
lowo ti yoo si maa ta kinni ti won n pe ni Banjo yi bi jita atijo, ni odo awon oyinbo ni won ti
gbe wa tori eyii ko jo oun eelo orin kankan nile wa, enikeji yi ni yoo maa ta tamborin, tamborin
yi dabi ilu kan ti won n pe ni samba, sugbon won so saworo tabi ide wewe mo
leti ti yoo si ma dun jinwin jinwin bi won ba ti n luu, lodo eni to n lu tamborin yi gan-an ni oruko
ti won n pe orin juju yi ti wa saye, oni tamborin yi gan lo so orin juju loruko o, E je kin
farabale salaye re fun yin lekunrere o, bi oro naa se je nipe bi oni tamborin ba ti
n lu tamborin re yi oo, bi ere na bati wa n wo lara tan, ti inu re bere si ni dun ti o si
ti wo ni akinyemi ara bi o ba ti n lu tamborin yi bee naa ni yoo ma ju soke ti kinni naa yoo si tun
maa dun pelu ara oto, bee ni inu awon ero to n woran yoo ma dun ti awon naa
yoo si tun maa pariwo pe juu daadaa juu ki o tun juu, nibi ti won ti n pariwo juu daadaa
juu daadaa yi ni won ti yo oruko orin juju jade gege bi a ti n pe lojo toni o, ti awon
oluworan yoo ma sope mo fe lo woran awon olorin to n ju tamborin bi won ba ti n korin, bee ni won pe kuru
titi tofi di bi a se n pe lojo toni, eeyan keta ti o ma n tele won ni oni sekere bi
enikan ba n korin ti o mtun n ta Banjo, ti oni tamborin naa n lu tamborin to si fi n dasa
lorisirisi bee ni oni sekere naa yoo ma a ta sekere lati ma fi gbe orin won lese ti oun naa yooma gbe orin, eni kerin won gan ni ojulowo agberin leyi tim o tumo si pe koni ise meji ju ki o gbe orin lo.


Tooo, eje ki a danu duro loni lori itan orin juju ta n baabo fun ti toni ki ale loo
mu eto tuntun min-in wa fun yin, mo dupe lowo gbogbo eyin ayanfe wa ti e n fadura
gbewa ro pelu oro iyanju ti e n fi tuwa lokan, e seun oo, ajosepo wa o ni baje lase
Edumare o, Tooo, Agbe mi se tan, Agbe n rele, Aluko mi se tan, O n rode ikosun, Lekenleke
mi se tan, O n rode ikefun nini-n-nini, Olalekan Olaonipekun Akanji iko Ademeto, omo Baba ni Ijeru
Ogbomoso loni bi e ba jeun, ata o ni sa pa yin lori, bi e ba mu omi, koni gbodi lago Ara yin,
bi iku ba wa n sa egbe yin pa, ti Arun si n gbe awon egbe yin de, Oto ni iku ati Arun yoo ma
fi ti yin si o, bi a ba wa ri enikeni ti o n pe Ori yin lai da, Obaraka ki o ma ka gbogbo won da
si Orun. Oodua yoo gbe yin oo, yoo gbe iran mi oo, IRE OOO

- Oojiirebii Osf

ORIN

Ẹskẹkẹnkẹ Àyìndé(2)

Òdòlayé Àrẹ̀mú

...
Yásàlámọ̀ Yásàlámọ̀ alaekum
Ìgbòwó ló n mọ́lẹ̀, ọmọ Kòsọ́kọ́

Ẹ dákun, e má jẹ́ ki tẹ sẹ̀ ó gbọ̀n dànù
Ẹ dákun, e má jẹ́ ki tilẹ̀ ó pọ̀jù ti tẹnu lọ

Mi ò màmà ríhun tó pọ̀ tí ò ní tán
Ìrí tí morí, ṣé mo rí atare, Ẹskẹkẹnkẹ

À ní ọmọ Àmọ́dù, ọmọ Ẹjalónibú
Apá ọ̀tún tí mo wò, mo tún rí kábá

Báǹkí onímuṣin, ọ̀bùn muṣin
Onímuṣin, ọ̀bùn muṣin

Ọgbọngbọn bí ọjọ́ kanrí, agùntáṣọ́ọlò
Orí mọ́námọ́ná ṣiyàn ládé

Kò sí ìyà oró n Muṣin mọ́ páà
Ẹnu igbà tó joyè yìí náà ni, ọba Muṣin

Ìrí tí mo rí, ṣe mo rí atare?
Apá ọ̀tún tí mo wò, mo tún rí kábá
Ẹ̀yìn tí mo wò, mo rí àgádágodo
Ẹskẹkẹnkẹ, Ẹskẹkẹnkẹ

Ọ̀rọ yìí e débi à ń yọ orùka
Ṣébi min ò lóògùn, kédì ewé jíjá
Àyìndé bí mo bá dejò, ó sá di igi oko

Èyí tí wọ́n ṣe tó kọ̀ tí kòjẹ́ oo; yéèèèè
Àtèyí wọn máwọ̀ wèrè ṣe

Ní Muṣin
Olówó kan ò lè dún kowéè lé ọ lérí mọ́
Àyìndé ọwọ́ ti tẹ àgádágodo wọn

Elégbodo kan ò lè dún kowéè lé ọ lérí mọ́
Àyìndé ọwọ́ ti tẹ àgádágodo wọn

Akéwejẹ! Akéwejẹ!!
Akéwejẹ gbogbo Èkó

Kìnìún Ìdímù tíí ṣẹ́mọ à á ṣẹ́ mọ kọ́lá ó dígbọ́n
N ò rí ohun tí kòlè fi tọrọ
Íí ràlẹ̀ í fún èèyàn
Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ mí oo
Bí ebi bá ń pamí oo
B’órun bá ń kùn mí oo
Ó dilé Ẹskẹkẹnkẹ
Kìí pé àlejò pé ibo lóti wá

Ọmọ Ẹjalónibú
Bí Géḿbérí bá wọlé ẹ, á jẹun
Bí ó bá jẹun mumi tán, á ní kó máa lọ
Ẹskẹkẹnkẹ

Àjọsọ Kìnìún ọmọ Àdísátù
Bí Géḿbérí bá wọlé ẹ, á jẹun
Bí ó bá jẹun mumi tán, á ní kó máa lọ
Ọ̀ríjínà Yoòbá
Bí ó bá jẹun mumi tán, á ní kó máa lọ
Ẹskẹkẹnkẹ

Kìí pe wọ̀bìà, Bí ó pajá ẹ̀ kó wá jẹun
Ṣùrù lọlá tí ń bọ́ báálé tẹrú tọmọ
Baba toní o ó dà lo dàyìí
Àjọsọ Séríkí

Àgbà toní o ó dà lo dàyìí
Bo ṣe bí o ṣe ń ṣe ni, ni o máa ṣe
Àyìndé, Baba Akeem

Bí o bá ti rí ọmọ kékeré o máa fọmọ kékeré mọ́ra
Baba Enjiníà, baba lọ́yà, bàbá adájọ́
Àyìndé bí o rágbà o f’àgbà mọ́dọ ọọọọ
Ẹskẹkẹnkẹ
Baba dókítà
Àgbà ló ń báni ṣèlú, ọmọ kékeré ni ń báni tún ilé ẹni ṣe
Ẹskẹkẹnkẹ

Àyìndé má j’obì lọ́gànjọ́ mọ́ ọọọ
Ẹni bá rí ni tán ló ń ṣekú pani
Kòrí kòsùn ló pa Jimoh, ọmọ Àgbókí l’ádífá
Àpọ́nlé òògùn, là ń so ońdè mọ́wọ́
Ẹskẹkẹnkẹ Àyìndé

Tani ikú ò bá faragbá tí kò mú lọ?
Ìdájí ìdájí lo l’ógùn ń kú, ọmọ Àgbókí l’ádífá
Ọ̀ré rẹ ńkọ́, ṣé ó ń bẹ lá làáfíà ara?
Bùṣìrá, ọmọ Agúnbíadé
Ikú gberí kangí ọmọ Agúnbíadé


...

9.11.16

ÒWE

Àwòdì tí ń re Ìbarà, atẹ́gùn ta à nídǐ pa, ó ní iṣẹ́ kúkú yá.

Translation: The hawk that was making for Ìbarà, the wind blew it from behind and the hawk said, ‘ that was quite a help.’

Lílò: Èdè nígbà tí ohun tí a kò nírè tí mú kí iṣẹ́ tí à ń ṣe lọ́wọ́ yá ju bí a ṣe ro; ohun tí a kò tànmọ̃ mú ọ̀ràn tètè yanjú.

Use: This is said when circumstances unexpectedly help a man with his plans.

Ẹ̀KỌ́ (GÍRÁMA)

Álífábẹ́ẹ́tì Èdè Yorùbá nínú ọ̀rọ̀

Yorùbá Alphabets in words

(1)
Aa Ajá (Dog)

Bb Bàlúù (Aeroplane)

Dd Dígí (Mirror)

Ee Edé (Crayfish)

Ẹẹ Ẹlẹ́dẹ̀ (Pig)

Ff Fọ́nrán (Voice Record)

Gg Gèlè (Head gear, for women)

GBgb Gbágùdáá (Cassava)

Hh Haúsá (Hausa)

Ii Ilé (House)

Jj Jagunjagun (Soldier)

Kk Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ (Fox)

Ll Labalábá(Butterfly)

Mm Màálù(Cow)

Nn Náwónáwó( A spendthrift)

Oo Olè(Thief)

Ọọ Ọ̀lẹ(Lazy man)

Pp Pẹ́pẹ́yẹ(Duck)

Rr Ràkúnmí(Donkey)

Ss Sàrùnmí (a name)

Ṣṣ Ṣakí (a town)

Tt Tafàtafà( Archer)

Uu Iku (Death)

Ww Woléwolé( Environmental Inspector)

Yy Yanmuyánmú (Mosquito)

8.11.16

TALÓ MỌ̀-Ọ́N

ÌBÉÈRÈ TÓ TA KÓKÓ

Sọ ìtunmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí a tọ́ka sí nínú gbólóhùn kàn-àn kan

1. Ó ṣebẹbẹ nígbà tí bàbá rẹ̀ kú- ṣebẹbẹ

2. Àlàbá ń ṣe fújà kiri ìlú- fújà

3. Fọ́rífọ́rí Àlàkẹ́ ti pọ̀ lápọ̀jù- fọ́rífọ́rí

4. Gbogbo ọmọ kékeré àdúgbò ni ifọ̀n ti mú l’ápa ọ̀tún tán- ifọ̀n

5. Àbàtà ta kété bí ẹni pé kò bá òdò tan- àbàtà

ORÍKÌ

IKORODU OGA

Omo Olowo Inu Aja

Omo Eluku Menden Menden

Omo Osinwin Rewa Loke Ota-Ona

Omo Aleremo Seji

Omo Ake Nigbo, Keru Ba Ara Ona

Omo Magbo Igbore

Omo Imale Afeleja

Omo Likopa Nmeru Ogudu

Omo Liwe Likoro

Omo Ikorodu Oriwu

Omo Asale Jeje Bi Eniti Ori Obirin Ri

Omo Awaiye Ma Ba Tise Wa

Omo Ikorodu Oga, Ilu Ti Osi Alaaru

EWÉ ÀTI EGBÒ

7.


Coastal goldenleaf, coast goldleaf – asaragba, asa gidi, aarasa, ira, fonu fonu

Blighia konig sapindaceae, akee apple – isin odo, isin jise, isin oka, isin odan

Triangle tops, Phialodiscus unijugatus, P. plurijugaturs, P. zambesiacus – isin ako, ako isin, odofin ile, akoisin

Star apple – osan agbalumo, osan olomo wewe, onidosan, agbalumo olomo

Satin leaf, Damson plum – osan edun, osan palambi, osanko

Upas tree, antiaris – oriro, oro, oro efun, abori kefun, awase, oriro omo oluugbo

Alligator weed – sawewe

Sessile joyweed, sessile floweres globe amaranth – ewaowo, awo crede, moni roderode, sajeje

leaves of Senecio biafrae – worowo

fermented seeds of Parkia biglobosa, African locust beans in English, Igba/Iyere

leaves of Talinum triangulare (water leaf) or Basella alba, Indian spinach , Amunututu

West African black pepper/Ashanti pepper (Piper guineense, Uziza in Igbo and Ata iyere

Phyllanthus amarus – ehin olobe or eyin olobe

Celosia argentea – soko

Launaea taraxacifolia – African lettuce, wild lettuce – efo yanrin.

Xanthosoa poeppigii – ewe koko

Citrus aurantiifolia – osanwene

ÀLỌ́ ÀPAGBÈ

Àlọ́ Àpagbè. Ìjàpá T'ìrókò- ÌJÀPA Àti ÀTÍÒRO(1)


https://soundcloud.com/ay-la-fadeyi/alo-apagbe-ijapa-tiroko-ijapa-ati-atioro1-oroyorubacom

7.11.16

ÌWÚRE

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀

A kò ni bọ́jọ́ ọlọ́jọ́ lọ

A kú ìbẹrẹ̀ ọ̀sẹ̀ yii

A ò ní ṣe àṣetì nídǐ iṣẹ́ wa

À tà jèrè ọjà

Kí a má ríbi elénìní

Kí òní sànwá sí rere

ÌWÉ ÌTUNMỌ̀

IṢẸ́ ỌWỌ́

1. Agbẹ́gilére: Sculptor

2. Agbaṣọrán: Tailor

3. Onídìrí: Hairdresser

4. Onígbàjámọ̀: Barber

5. Asobàtà: Cobler

6. Alágbẹ̀dẹ: Blacksmith

7. Àgbẹ̀: Farmer

8. Ajórinpọ̀: Welder

9. Akànṣó: Carpenter

10. Eléré- orí-ìtàgé: Actor/ Actress

ÀKANLÒ ÈDÈ

ÀKANLÒ ÈDÈ APÁ KẸRIN

1. Àgùntàn bu(ni) jẹ. ṣe aìlè bá obìnrin lò pọ̀

2. Ẹja ǹ bákàn. Ire tàbí ibi

3. Já(ni) sí agbami. Padà lẹ́yìn ẹni láàrín ín méjì

4. Igi lẹ́yìn ọgbà. Aláfẹ̀yìntì

5. Rí ọwọ́ họrí. Ní owó

6. Ṣé ní bòńkẹ́lẹ́. ṣé ní ìpámọ́/ kọ̀rọ̀

7. Pín gààrí. Pínyà tàbí dẹ́kun àjọṣepọ̀

8. Wá fìn-ín-ìn ìdí kókò. Ṣe òfintótó/ ṣe ìwádǐ láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀

9. Nu (ni) lọ́rọ̀. Sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí ni

10. Mú ọ̀gẹ̀dẹ̀ nínú ọsọ́. Ya òmugọ̀

6.11.16

ÀRÒKỌ

Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ẸBÍ WA

APÁ KẸRIN


.
Nǹkan púpọ̀ ni mó fẹ́ bèèrè lọ́jọ́ náà lọ́hǔn, ṣùgbọ́n n kò rí ẹni bi. Gbogbo èèyàn ló bara jẹ́ tí wọ́n ṣe bí ẹni pé wọn kò tilẹ̀ rí àwa ọmọdé- ilé. Títí kan àwọn tí wọ́n máa ń yọ̀ kí wa, lásán ni wọ́n kí wa. Obìnrin kan tilẹ̀ sọkún tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí kò tilẹ̀ mọ̀ pé èmi ni mo jókǒ ní kọ̀rọ̀ kan ní ẹ̀yìnkùlé.
.
Wọ́n ti gbé ìbùsùn bàbá mi sí pálọ̀. Mo rí gbogbo àwọn nǹkan tí wọ́n ti rà láti fi sin òkú náà kí wọ́n tó sin ín. Ńṣe ni mo fi gbogbo rẹ̀ ṣe ìran wò. Wọ́n ní kí gbogbo ènìyàn yẹra o, wọ́n ń gbé òkú bọ̀. Mo gbọ́, mo sì fẹ́ wò ó, ṣùgbọ́n ìyá wa àgbà kan lé mi sẹ́hìn. Ó ní, ‘Àwọn ọmọ ayé ìdayìí mà láyà o. Wọ́n ní wọ́n ń gbé òkú bọ̀, ìwọ Ìyábọ̀ ń yọjú. O fẹ́ wo òkú ni?’ Bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ kí n rí òkú náà wò bí wọ́n ṣe ń gbé e bọ̀. Yàrá bàbá mi ni wọ́n gbé e lọ. Mo sì mọ̀ pé wíwẹ̀ ni wọ́n lọ wẹ̀ ẹ́ nítorí mo ri àwọn ènìyàn wa tí wọ́n ń gbé kàn-ìn-kàn-ìn, igbá omi, aṣọ ìnura, wọ ilé. Ó pẹ́ kí wọ́n tó jáde, wọ́n ní wọ́n ti wẹ òkú tán, wọ́n sì ti wọ ‘ṣọ fún un tán. Wọ́n ní wọ́n ma gbé e lọ sí pálọ̀. Wọ́n wá tẹ́ ẹ sí orí ìbùsùn bàbá mi tí wọ́n ti tẹ́ aṣọ funfun lé.
.
Ó tó agogo méjìlá ọ̀sán báyìí. Tí kò bá sí ọ̀fọ̀ tí ó ṣẹ̀ wá ni, irú àsìkò báyìí , ilé- ìwé ni èmi, ẹ̀gbọ́n àtí àbúrò mi ìbá wà ṣùgbọ́n wọn kò jẹ́ kí á lọ sí ilé- ìwé. Nǹkan púpọ̀ ni ó jẹ́ nǹkan ìyàlẹnu fún mi l’ọ́jọ́ ìsìnkú yìí. Wọ́n ní kí emi àti ẹ̀gbọ́n mi wọ aṣọ funfun kan tí a máa ń wọ̀ lọ sí ilé- ìsìn. Ìyá mi sì fún wa ní gèlè dúdú láti wé. N ò wé gèlè dúdú rí ṣùgbọ́n a ṣe bí wọn ṣe wí. A jókǒ sí ẹ̀hìnkùlé, a n gbọ́ ìkini òkú àti ìdánilóhùn oríṣiríṣi. Ẹlòmíràn á sọkún kíkorò, á sì kí àwọn ènìyàn wa báyìí pé:
Ẹ pẹ̀lẹ́ o.
Ẹ kú àjálù.
Ẹ kú ọ̀fọ̀.
Ọlọ́run yóò ṣe é mọ bẹ́ẹ̀.
Ọlọ́run kò ní í jẹ́ k’a r’írú rẹ̀ mọ́.
.

Ẹlòmíràn á tún dé, a ní ṣe irú rẹ̀ ní tiyín mọ́.
Ọlọ́run yóò fi mọ bẹ́ẹ̀.
Ọlọ́run á tìkùn ìbànújẹ́.
.
Síbẹ̀ ẹlòmíràn tún lè kí wa pé:
Ẹ pẹ̀lẹ́ o.
Ẹ kú ẹjọ́ tí Ọlọ́run dá yín.
Ọlọ́run kò ní í fi irú bẹ́ẹ̀ sí sàkání yín mọ́.
Ọlọ́run kò ní í jẹ́ kí ẹ kú àkúrun mọ́ o.
.

Ìdáhùn àwọn òbí wa sí kíkí ọ̀kan-ò- jọ̀kan wọ̀nyí ni:
Ẹ ṣeun, ṣeun.
Ẹ ṣeun, a dúpẹ́ o.
Ọlọ́run kò ní í ṣe é ní àáró o.
Ọlọ́run kò ní í jẹ́ kí ẹ fi irú rẹ̀ gbà á o.
Bí a ti rí náà nìyẹn o.

.
- ÌYÁBỌ̀

ÒWE

Àparò,ěṣe tí aṣọ rẹ fi pọ́n báyìí? Ó ní ‘Ìgbàwo ni aṣọ kò ní pọ́n? Ọ̀sán jíjẹ; òru sísùn; óńjẹ kò ṣé fi sílẹ̀ l’ọ́sàn ań, oorun kò ṣé fi sílẹ̀ l’óru láti fọ aṣọ’.
.

Translation: ‘Bushfowl, why are your clothes (feathers) so dirty?’ She said: ‘When will my clothes cease to be dirty? The day is for eating and the night for sleeping. Food cannnot be put aside during the day nor can sleep be put aside during the night to wash clothes.’
.

Ĺlò: Ìbáwí fún ìwà àṣejù tàbí ìmọràn pé ó dára kí a ṣe ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe níwọ̀n- tunwọ̀nsí lásìkò láìṣe àṣejù.
.

Use: This reproaches a person for lack of moderation and suggests that there is a time for everything.

5.11.16

ÀṢÀ

ÌSỌMỌLÓRUKỌ

APÁ KEJÌ: ÈTÒ ÌSỌMỌLÓRÚKỌ

Kí ó tó di ọjọ́ ìsọmọlórúkọ, oríṣiríṣi orúkọ ni a máa ń pe ọmọ titun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Àwọn mìíràn a máa pè é ní àlejò nítorí pé wọ́n kà á sí àlejò tó wá bá ni; ṣùgbọ́n wọn kò kà á sí àlejò tí yóò tún padà, bí kò ṣe èyí tí yóò máa bá ni gbé lọ títí. Àwọn mìíràn a máa pè é ní ìkókó, túnfúlù tàbí aròbó. Àwọn ẹ̀yàYorùba mìíràn ní orúkọ tí wọ́n ń pe ọmọ titun tí kò tíì ní orúkọ ní ẹ̀ka- èdè ti wọn.
.

Ní ìbẹrẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ọjọ́ mẹ́fà ni à ń sọ ọmọ lórúkọ ìbáà jẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin. Ṣùgbọ́n àwọn ìran tàbí ìdílé pàtàkì pàtàkì pàápàá ní ààrin ẹ̀yà Yorùbá Ọ̀yọ́ ní ètò ìsọmọlórúkọ tó yàtọ̀ sí ọjọ́ mẹ́fà. Ní ìdílé Olú- òjé, Onígbẹ̀ẹ́tì, Olókùn- Ẹṣin, Arẹ̀sà, Oníkòyí àti Olúgbọ́n, ọjọ́ keje ni à ń sọ ọmọbìnrin lórúkọ. Ọjọ́ kẹsàn án ni ti ọkùnrin. Bí a bá bí ìbejì ní ìdílé wọ̀nyìí, tí àwọn méjéèjì sì jẹ́ obìnrin, ọjọ́ keje la ó sọ wọ́n lórúkọ. Ṣùgbọ́n tí àwọn méjéèjì bá jẹ́ ọkùnrin, ọjọ́ mẹ́sàn án ni a ó sọ wọ́n lórúkọ. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjéèjì bá jẹ́ ọkùnrin tí èkejì sì jẹ́ obìnrin, ọjọ́ kẹjọ ni a ó sọ wọ́n lórúkọ ní ìdílé náà.
.

Ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ní ìdílé Ọlọ́fà tún yàtọ̀. Ní ìdílé Ọlọ́fà, ọjọ́ méje ni à ń sọ ọmọkùnrin lọ́rúkọ. Ọjọ́ karùn ún ni ti obìnrin. Ọjọ́ kẹfà ni ti àwọn ìbejì tí ọ̀kan jẹ́ ọkùnrin tí èkejì jẹ́ obìnrin. Ṣùgbọ́n tí àwọn ìbejì náà bá jẹ́ ọkùnrin, ọjọ́ keje la ó sọ wọ́n lórúkọ. Bí wọ́n bá jẹ́ obìnrin, ọjọ́ karùn ún ni. Ní ìdílé Aláàfin, ọjọ́ kẹfà ni à ń sọ ọmọ lórúkọ.
.

Láyé òde òní, ìyípadà ti dé bá ọjọ́ ìsọmọlórúkọ. Kí gbogbo rẹ̀ lè dọ́gba, ọjọ́ kẹjọ ni à ń sọ ọmọ lórúkọ ní ibi púpọ̀ ilẹ̀ Yorùbá. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ló ní orò- ilé tí obìnrin tó bí ọmọ gbọ́dọ̀ ṣe láti ọjọ́ tí ó bá ti bímọ títí di ọjọ́ ìsọmọlórúkọ. Orò kan wọ́pọ̀ ní ibi púpọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá. Èyí ni ‘kíkó- ọmọ- jáde’ ní ọjọ́ ìsọmọlórúkọ.
.

Inú ìyàrá ni ìyá ìkókó gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú ìkókó náà láti ọjọ́ tí ó bá ti bímọ títí di ọjọ́ ìkomọjáde.Ibẹ̀ ni wọn yóò maá dàná fún un yá. Ìgbà tó bá fẹ́ yàgbẹ́, ìgbà tó bá fẹ́ tọ̀ tàbí ìgbà tí ó bá fẹ́ mọ́ra ni yóò maá jáde sí gbangba. Ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ni a ó tó gbé ọmọ náà jáde láti inu ìyàrá bí ó bá jẹ́ ọ̀kan. Bí ó bá jẹ́ ìbejì, ọjọ́ náà la ó tó kó wọn sí gbangba òde. Ìdí nìyǐ tí a fi ń pe ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ní ọjọ́ ìkómọjáde.
.

Ní ọjọ́ ìkomọjáde, àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ yóò péjọ síwájú ilé níbi tí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò máa ń dà sílẹ̀ láti orí òrùlé. Wọn yóò gbẹ́ ihò kéékèèkéé méjì síwájú ilé náà. Ìyá ìkókó náà yóò wọṣọ tó dára nítorí ọjọ́ ayọ̀ ni ọjọ́ náà fún un. Nígbà tí ìyá ìyá ìkókó báti jókòó níwájú ilé tán, àgbà obìnrin kan yóò wọlé lọ gbé ọmọ náà jáde láti inú ìyàrá. Ìyá rẹ̀ yóò gbà á. Wọn yóò máa da omi tútù sórí òrùlé bí ìyá ìkókó ṣe ń gbé omọ rẹ̀ bọ̀. Ẹ̀kán omi tútù yóò kán sára ìkókó. Ọmọ náà yóò ké nítorí omi náà ṣàjejì lára rẹ̀. Inú àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ tó péjọ yóò dùn fún igbe ayọ̀ tí ọmọ náà ké. Igbe náà sì tún fi hàn pé ara ọmọ náà dápé. Nígbà mìíràn, ẹ̀ẹ̀méje ni wọn yóò fi ara ọmọ náà gbe ẹ̀kán omi náà bí wọn ti ń gbé e wọlé, tí wọ́n ń gbé e jáde, bí ó bá jẹ́ obìnrin. Bí ó bá jẹ́ ọkùnrin, ẹ̀ẹ̀mẹsàn án ni. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ ìbejì, ẹ̀ẹ̀mẹ́jọ ni.
.

Bí a bá yẹ àṣà yìí wò, ó fi ara jọ ìṣamì àwọn ẹlẹ́sìn Krístì. Ó sì tún jẹ́ pé àwọn baba- ńlá wa ní ìmọ̀ ẹ̀sìn Krístì kí wọ́n tó wá tẹ̀dó sí Ilẹ̀- Ifẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣáá, ìdí tí a fi ń ṣe àṣà yìí ni láti jẹ́ kí ara ìkókó náà mọ omi tútù nítorí ìgbà tí ìyá rẹ̀ yóò máa gbé e kiri. Láti ọjọ́ ìkómọjáde náà ni ìyá rẹ̀ yóò ti máa gbé e káàkiri bí ó bá ti fẹ́.


- Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá Titun

ORÚKỌ

ORÚKỌ TÍ Ó JẸ MỌ ÀSÌKÒ

1. Ọ̀tẹ́gbẹ̀yẹ: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ ìlú. Ọ̀tẹ̀ náà sì ti gba ẹ̀yẹ ìdílé

2. Ogúnpọlá: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn tàbí lásìkò ogun. Ogun ti pa ọlá ìdílé

3. Abíóyè: Ọmọ tí a bí lásìkò tí bàbá rẹ̀ wà lórí oyè

4. Abíọ́lá: Ọmọ tí a bí sínú ọlá tàbí lásìkò tí àwọn òbí rẹ̀ ní ọlá púpọ̀

5. Abíọ́nà: Ọmọ tí a bí lásìkò tí ìyá rẹ̀ wà lójú ọ̀nà sí ibì kan yálà ọ̀nà oko, ọ̀nà odò, ọ̀nà ọjà, ìrìn- àjò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

6. Abíọ́sẹ̀/ Abọ́sẹ̀dé/Ajọ́ṣẹ̀/ Jọ́ọ̀ṣẹ̀ (Ọjọ́- ọ̀sẹ̀): Ọmọ tí a bí lọ́jọ́ ọ̀sẹ̀ Òrìṣà-ńlá; tàbí lọ́jọ́ ọ̀sẹ̀ òyìnbó lóde òní.

8. Bọ́sẹ̀dé: Orúkọ obìnrin ni èyí

9. Abíọ́dún/ Abọ́dúnrín/ Abọ́dúndé: Ọmọ tí a bí lásìkò ọdún pàtàkì kan- Ó le ṣe ọdún ẹ̀sìn tàbí ọdún ìlú

10. Ọdúnjọ/ Ọdún- Ifá/ Ọdúnayọ̀: Ọmọkùnrin tí a bí lásìkò ọdún Ifá tàbí ọdún mìíràn

11. Babájídé/ Babátúndé/ Babárìndé/ Babáwándé: Ọmọkùnrin tí a bí ní kété tí bàbá rẹ̀ kú. Orúkọ yìí fi ìgbàgbọ́ Yorùbá nínú àjínde múlẹ̀

12. Yéwándé/ Yéjídé/ Yétúndé/ Ìyábọ̀dé/ Yésìdé: Ọmọbìnrin tí a bí ní kété tí ìyá bàbá rẹ̀ kú

13. Babárínsá/ Babárímisá/ Òkúgbésàbí: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, bí ọmọ bẹ́ẹ̀ bá jẹ́ ọkùnrin

14. Jọ́họ̀jọ́/ Yérímisá: Ọmọbìnrin tí a bí tí ìyá rẹ̀ sì kú lọ́jọ́ náà tàbí kí á tó sọ ọ́ lórúkọ

15. Adéọjọ: Ọmọkùnrin tí a bí tí ìyá rẹ̀ sì kú lọ́jọ́ náà tàbí kí a tó sọ ọ́ lórúkọ

16. Àbíìbá: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, pàápàá bí ó bá pẹ́ díẹ̀ tí baba rẹ̀ ti kú kí a tó bi i

17. Ábíára: Ọmọ tí oyún rẹ̀ kò tí i hàn dáadá tí baba rẹ fi kú. Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ ju oṣù mẹ́sàn- án lọ tí baba rẹ̀ ki á tó bí i

18. Babáyẹjú: Ọmọbìnrin tí a bí lẹ́yìn ikú baba rẹ

4.11.16

ORIN

ESKEKẸNKẸ ÀYÌNDÉ(1)

- Odòlayé Àrẹ̀mú


AwúsùbìLáàyì
Mínàṣàìtọ́nì Rọ̀jíími
Bísímìláàyi Aramọ́ọ́ni Rọhíìmì
.

Àti wálé ayé ọjọ́
Ìbà lọ́wọ́ rẹ
Odòlayé ni ń wí ìbà yìí o
.

Àti wọ̀ oòrùn
Ìbà lọ́wọ́ rẹ
.

Àáfà tó yàn, tó yan jú
Tínú ẹ̀ mọ́, tó ya wòólì
Ìbà lọ́wọ́ ẹ̀yin o
.

Ẹ̀yin tẹ́ ẹ layé
Ìbà lọ́wọ́ ẹ̀yin o
.

Ẹ̀yin ọmọ kéèkèèké tẹ́ ẹ ṣẹ̀ lẹ́yìn wa
Ìbà lọ́wọ́ ẹ̀yin o
.

Kini ‘ǹfààní ẹni tóní ọwọ́ ayé ò le tẹ òun
Tí ń janu, tí ń ṣagbaja, tí ń tún minu
Àkámarà èé jẹ́bẹ̀
.

Ìgbà tí ayé bá ṣe èèyán tán
Wọn á sì dárò bọnu
Tí ayé bá ṣe èèyán tán, wọn a l’ódò rè é gbétí lé
.

Ṣé kí n máa lọ, ṣé kòsí nǹkan?

Ègbè: Wọ́n ní kòsí ǹkankan
.

Mo ríbà ‘i’ ríbá, mo ríbà dagbaro
Ẹbọra lágbó ẹgẹ, Ọ̀bá di méji; a gbẹwọ̀n gbẹ̀gẹ̀dẹ̀
.

Pẹ̀lẹ́ bí ẹ gbóhùn àríri, abínú fọhùn bí ènìyàn
Mo ríbà ‘i’ ríbá, mo ríbà ìyá mi oo
Ajíbọ́lá ẹdan
Ìyá mi ẹdọ̀ ọrọ oo
Ọ̀rọ̀ tí ń gbénú ilédì tí ń kùn yùnmùyùnmù
.

Ní alẹ́ yìí, ìbà lọ́wọ́ Ajíbọ́lá
Ará ìlú ète, ará ilú eédú
.

Ọlọ́ṣùn ún tẹ́rẹ́, abirù tínrín
Bóbá dú lójú, a dú lénu
Aájò lápá ìsàlẹ̀ woyìwoyì
Afínjú Àdàbà tí ń jẹ́ láàrín ín òrófo
Afinjú ẹyẹ tí ń jẹ ní gbangban ilé ọba
.

Àákú ayé ò bá o
Aa
Àákú ayé ò bá o, ilẹ̀ ló tún tẹ̀yin ṣe
Ọmọ aláya ọba, èyí tí ń ṣàǹfàni nínú ilédì, ọmọ àgbàgbà ìmùlẹ̀
Afínjú ońmùlẹ̀ tí ń so kùtúkùtú mọ́wọ́
.

Ẹ má wò ó óóó
Ẹ̀yin ọ̀dàlè ènìyàn
Ṣòkè ṣodò
Ẹlẹ́nu mẹ́rin-dín-lógún
Agbọ́ yìí sọ̀ yìí; Asọ̀lú kọ̀lú
Kẹ́ni mánǐ; Wèrè; Dìgbòlugi
.

Ẹ má debi a ò pèyín o
Ẹ ò gbọdọ̀ wo o, ojú ò gbọdọ̀ ri
.

Ẹ ò wá wo ọmọ inú ọgbà bí wọ́n ti ń ṣe
Àwọn ọmọ Àbẹ̀ní, ọmọ Oótù Ifẹ̀
.

Ní alẹ́ yìí, ìbà lọ́wọ́ Dángbọ́ngbọ́n baba kóko
Erù ọgbọ̀n gandàn, baba Ìlosùn
.

Aṣọ mẹ́rin-dín-lógún laṣọ Ṣọ̀npọ̀nná
Ọ̀kan lahún Ìlárá- Eskẹkẹnkẹ
Hájì kámaṣọ
Yínmíyínmí píṅkin
Ọgọgọlúmọlúmọ
Apẹran máwàkú, olókìkí òru
.

Ìbà lọ́wọ́ yín, atìdí mùjẹ̀ èèyàn
Ìyá mi, ọ̀rẹ́rẹ́ oo, ooooo, ooooo
Ati ojú j’orí oo
Ati ẹdọ̀ jọkàn
Ati òróǹró jẹ̀fun Ọ̀gàlàǹta
Ajẹran òró òó
Ajẹ ẹ̀dọ̀ èèyàn mabì
Ẹ̀yin lẹ kọ́mi lódù, tẹ sìnmí wálé ayé
Tẹ́ẹ sọ pé ilé ayé tí mo wá, orin ni kí n máa kọ, kí n máa fi jẹun
.

Èkó náà la wàyìí
Olú Nàíjíríà gan la wàyìí
Muṣin la wàyìí
Ọ̀dọ Ẹskẹkẹnkẹ la wàyìí
Ọ̀dọ ọmọ Ààmádù la wàyìí
Ọ̀dọ̀ Àyìndé la wàyìí
Ọ̀dọ Kìnìún Ojúwóyè la wàyìí
Ọ̀dọ Ìyàndá ọmọ Àdísátù la wàyìí
Ọ̀dọ Akódúdú la wàyìí
Ẹ dákun, ẹ má jẹ̀ kí tọwọ́ ó bọ́
-----


Ó ń tẹ̀ síwájú

3.11.16

ÀWÒRÁN

ÌTA ỌGBÀ FÁFITÌ ÈKÓ TI ÌJỌBA ÀPAPỌ̀


TALO MỌ ỌN?

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ TA KÓKÓ

1. Kíni 'Òkú ewúrẹ́ tí í fọhùn bí ènìyàn'

2. Kíni Yorùbá ṣe ń kí èèyàn báyìí: 'Ẹ kú arógun'

3. Ibo ni 'Ìgẹ̀' wà ní ààgọ̀ ara?

4. Tani olórí 'Ẹgbẹ́ Onímọ̀ Èdè Yorùbá?'

5. Tani Yorùbá máa ń kí báyìí 'Ẹ rìn wá'?

2.11.16

AKANLO EDE

*AKANLO EDE TI ALE ONI*

Kini itunmo awon Akanlo Ede wonyii:

1. Fi ikun lukun

2. Tu ito soke foju gba a

3. Ya agbado enu

4. Wo agba loju

5. Se ayonu so.

oroyoruba.blogspot.com.ng

OFIN EGBE OROYORUBA LORI WHATSAPP

*AWON ETO EGBE*

1. Aiku: Eko, 08082683195 (9: 30 ale) ati Oro Esin(Kristi) (8: 00 ale

2. Aje: Iwure- 08030627995 (7: 30 owuro)

3. Isegun: Ewi- 08066231094 (9:00 ale)

4. Ojoru: Akanlo Ede ati Alo Apamo- 08184823237 (9: 00ale)

5. Ojobo: Ipolowo Oja oun Iru Wa, Ogiri Wa

6. Eti: Oro Esin Isilaamu- (11: 00 owuro)

7. Abameta: Eko, 07034682225 (9:00 ale)

----------------------------------------

*Afikun ti o po si n bo, sugbon ki a bere pelu awon wonyii na.

A o ti i ri eni ti yoo maa se iwaasu fun wa ninu esin meejeeji

Iwo ti o ba mo pe o le se e eyikeyi ninu awon eto ti ati la kale, ma se jafira lati fi to eyikeyi ninu awon alabojuto

Ti o ba ni ohun kan ti o fe fi to egbe leti loi bi idagba soke se le wo inu egbe, gbegede gbegede laaye si sile.

Ki awon ti nomba ipe won jade fi ara won le ki won si fun a ni oro itewogba won.


Bawo ni e se ri i si? So ti e.

Ire!

1.11.16

EWÉ ÀTI EGBÒ

6.

Argemone mexicana – Mexican poppy, Mexican prickly poppy, Flowering thistle, cardo or cardosanto – Egun arugbo, Ekan-ekun

Artocarpus altilis – Berefurutu

Boerhaavia diffusa – punarnava – Etiponla, Olowojeja

Borreria verticillata – Irawo ile

Carpolobia lutea – Osunsun

Citrullus colocynthis – colocynth, bitter apple, bitter cucumber, desert gourd, egusi, or vine of Sodom – Egusi-baara

Citrus aurantium – Bitter orange, Seville orange, sour orange, bigarade orange, or marmalade orange – Osan

Aspilia africana – Yunyun

Nicotiana tabacum – Ewe taba

Transvaal alchornea – jandu, ijandudu, gbaluwo, ijan pupa, sewo sese pepe, ijan, ijan funfun, pepe

Christmas bush – isin, ipa, epa, esin, asiyin, esin abata

Yellow siris, yellow bean – yoruba: ayinreta, ayinre popo, ayunre, akudinrin, alota

Lebbeck tree, siris tree, white siris tree, bastard lebbeck, tall albizia, white siris – Yoruba: ayinreta

Flat Crown – ayinre, ayinre isingede, ayinre ogo

Black currant tree – yoruba: aduigbo, asofeyeje, olowuko, yanya holo

Tassel berry – yoruba: aponlojusese, aroro

White mahogany – ifa okete

Kola nut – yoruba: obi-abata, ogungun

Zulu coshwood, vanquisher – atewu-edun, orodo, ofun, fomu, obi-edun

Job’s tears, gromwell-read, pearl barley – obi, obi ifin, obi pupa, obi abata

African mahogany, counterwood – apa, ako apa, apa igbo

Pond apple – afe

Soursop, prickly custard apple : eko oyibo, eko omode

Wild custard apple, custard apple – abo, arere, afon

Silk tree albizia, mimosa, mimosa tree, silk tree, silk sirirs, Persian acacia, pik siris tree – ayinre, ayinreye

Pattern wood, alstonia – atikekereheyin, dagunro kekere

Scrub ironbark, grey birch – ira odan, ira, iralodan

ORÍKÌ

ÌKAMÒDÙ

˂PRE>
.
Ìkamòdù dúdúmọ̀ọ́dú, ẹlẹ́wìrì ihò.
Ó kọjá nínú igbó, òórùn gba ‘gbó kankan;
Ó kọjá l’ókè ọ̀dàn, òórùn gba ‘jù.
A-jí-kó-òórùn- hárí a b̂ara dúdú kunkun.

.
Ìkamọ̀dù kì í lọ s’ógun àìm’ẹ́rú- bọ̀- wálé.
Èyí t’ó lọ s’ógun tí kò m’ẹ́rú wálé
Di à- níkàn- dá- jẹ̀ láàrin ìgbẹ́,
Tiz] kò tún sun inú ihò mọ́;
Ó di k’ó máa sun abẹ́ ewé, abẹ́ igi kiri.

.
Ṣé Ìkamọ̀dù l’ó jagun l’ọ́jọ́ kan, ọ́jọ́ kan,
L’ọ́jọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣoró n’íhò ọ̀run.
Ìkamọ̀dù l’ó lọ s’ógun ibá ikán jà,
Bí wọn ti ń pa ikán n’ikán ń pa wọ́n.

.
Ọ̀rọ̀ kò wọ̀ mọ́ Ìkamọ̀dù dá òórùn sílẹ̀ l’álẹ́ ihò,
Níbi tí gbogbo ikán ti ń lé ‘mú òórùn bébé.
Fún òórùn t’ó gba ‘nú ihò, t’ó sì gba ‘gbo kankan,
Àwọn Ìkamọ̀dù gb’ọ́fá fùrọ̀.

.
Wọ́n n ta ikán ní mèlemèle.
Ìkamọ̀dù jagun náà, wọ́n sì m’ẹ́rú wálé.


Ni wọ́n fi n ki gbogbo àwọn Ìkamọ̀dù pé:


Ọmọ a- fi- òórùn- jagun- m’ẹ́rú- kere;
Wàrànwéré l’ogun Ìkamọ̀dù.
˂/pRE>